You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kíló fa rògbòdìyàn tó gbẹ̀mí àwọn eèyàn lẹ́yìn àbẹ̀wò Makinde ní Igangan?
Ọrọ di boolọ koo yaa mi lẹyin ipolongo ibo ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde lọ ṣe ni ilu Igangan l'ọjọ Iṣẹgun.
Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe laarin awọn eeyan ilu ati awọn oṣiṣẹ ajọ to n ṣe akoso igbokegbodo ọkọ n'ipinlẹ Ọyọ 'Park Management System (PMS)' to n bẹ labẹ akoso Alhaji Lamidi Mukaila ti ọpọ eeyan mọ si 'Auxiliary' ni wahala ti bẹ silẹ lẹyin ti Makinde kuro ni ilu naa.
Lara awọn eeyan ilu naa ti ọrọ yii kan ni iroyin sọ wi pe wọn jẹ aṣoju ẹgbẹ to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, iyẹn 'Yoruba Nation'.
Bo tilẹ jẹ wi pe ko si ẹni to ri alaye ṣe nipato lori ohun to ṣe okunfa wahala naa,
ohun ti iroyin fi idi rẹ mulẹ ni wi pe aṣoju 'Yoruba Nation' kan ni wọn kọkọ ṣe iku pa ki o to di pe awọn alatilẹyin rẹ naa gbẹsan lara awọn oṣiṣẹ PMS.
Lara awọn eeyan to padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ naa ni wọn pe orukọ rẹ ni Mathew Ọjẹlabi.
Aburo baba rẹ ti o ba awọn oniroyin sọrọ, Samuel Ọjẹlabi ṣe alaye wi pe wọn sare wa pe awọn nile ni lẹyin iṣẹlẹ naa, nigba ti wọn si riidaju pe wọn ti yinbọn pa ọmọ wọn ni wọn ke gbajare lọ si agọ ọlọpaa.
Arakunrin kan ti o pe orukọ ara rẹ ni Samson Agbara fi ẹsun kan wi pe lẹyin ti rogbodiyan naa ṣẹlẹ ni oun deede ri awọn janduku kan ti wọn n dana sun awọn alupupu ti awọn gbe silẹ.
Alupupu marun un si ni wọn dana sun nibi iṣẹlẹ naa.
O ni bi o ti lẹ jẹ wi pe oun ko ba wọn yọju si ibi ipolongo ibo ti Makinde wa ṣe ni ilu naa, niṣe ni awọn janduku naa da oju ibọn kọ oun lẹyin ti wọn dana sun alupupu ti oun gbe silẹ.
Agbara fi kun ọrọ rẹ wi pe nigba ti ibọn ti wọn yin ko wọle si oun lara ni wọn bẹrẹ sini lu oun ni ilu bara.
O ni oun ti o le dẹkun aleekun wahala ni ki Makinde ra alupupu tuntun pada fun oun.
BBC Yoruba kan si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lori iṣẹlẹ naa. Alaye ti alukoro ọlọpaa, Adewale Oṣifẹsọ ṣe fun akoroyin wa ni pe iṣẹlẹ naa ko waye lasiko tabi nibi ti wọn ti n ṣe ipolongo ibo.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, bẹẹ sini eti awa oniroyin ko ni di si abajade rẹ.
Bo tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ko sọ onka iye ẹmi ti o ba iṣẹlẹ naa lọ, aworan ti a ri ṣe afihan oku eeyan meji ati awọn eeyan mii ti o fi ara pa.