You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ikú dóró! Èèyàn tó jẹ́ Ọlọ́run nípè níbi ìbúgbàmú Mọsalasi Pakistan ti di 100
Àwọn Ọlọpaa ni iroyin ni awọn to ṣiṣẹ́ laabi ọhun fẹ dojú kọ amọ nnkan yiwọ.
Nibayii, iye awọn to kú nibi ti awọn eeyan kan ti n kirun ni Mọsalasi agbegbe Peshawar ni Pakistan ti gòkè sii di ọgọrun.
Mọsalasi naa wa ni agbegbe to jẹ pe ààbò to daju wa iwadii si ti n lọ bayii lati mọ bi ẹni to gbe Ado oloro naa ṣe rí ọna wọ adugbo naa.
Èyí jẹ ikọlu ipaniyan to buru ju to ti waye ni Pakistan lati ọpọlọpọ ọdun sẹ́yìn.
Yàtọ̀ fun awọn to ku, ọ̀pọ̀ eeyan lo tun farapa nibẹ.
Ọmọ ikọ Taliban kan ni wọn kọ́kọ́ fẹ̀sùn kan pe o wa nidi ikọlu naa amọ ikọ naa bu ẹnu atẹ lù ú.
Fún ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn, ikọ Taliban ti n bù ẹnu atẹ lu àwọn ẹsun ikọlu si Mọsalasi, ilé ẹ̀kọ́, ati ọjà ti wọn fi n kan wọn nitori wọn ni awọn ti wọ sokoto ija kan naa pẹ̀lú awọn oṣiṣẹ alaabo ni kii sii ṣe àwọn eniyan Pakistan.
Ẹwẹ, ọ̀pọ̀ eeyan ni ko gba ọrọ to ti ẹnu ikọ Taliban jade yii.
Ènìyàn 59 ni iroyin kọ́kọ́ gbé pé wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò tí wọ́n ń kírun lọ́wọ́ nínú mọ́ṣáláṣí
Kò dín ní ènìyàn mọ́kàndínlọ́gọ́ta tó pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí àdó olóró kan dún gbàmù ní mọ́ṣáláṣí kan ní ìlú Peshawar ní orílẹ̀ èdè Pakistan.
Ìròyìn ní àwọn ọlọ́pàá ní ẹni tó ju àdó olóró náà fẹ́ pa.
Olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè náà, Shehbaz Sharif ní àwọn agbéṣùmọ̀mí náà mọ̀-ọ́n-mọ̀ fẹ́ dá ìbẹ̀rù bojo sọ́kàn àwọn ènìyàn nípa dídojúkọ àwọn tó ń dá ààbò ìlú.
Kò sí ikọ̀ kankan tó tíì jáde láti sọ wí pé àwọn ni àwọn wà nídìí ìkọlù náà àmọ́ wọ́n ti ń so ìkọlù ọ̀hún mọ́ ikọ̀ Taliban Pakistan.
Láti inú oṣù Kọkànlá ọdún tó kọjá ni ikọ̀ yìí ti dáwọ́ ogun dúró ṣùgbọ́n síbẹ̀ ìkọlù ṣì ń tẹ̀síwájú níbẹ̀.
Apá ibì kan níbi mọ́ṣáláṣí náà ló wó lulẹ̀ tí àwọn aláṣẹ sì ní àwọn ènìyàn wà lábẹ́ ilẹ̀.
Àwọn ìròyìn kan ní ẹni tó yin àdó olóró náà jókòó síwájú náà yin àdó olóró náà bá ara rẹ̀ àmọ́ àwọn aláṣẹ kò ì tíì fìdí èyí múlẹ̀.
Agbẹnusọ ilé ìwòsàn sọ fún BBC pé ènìyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ti di mọ́kàndínlọ́gọ́ta tí ènìyàn 157 sì farapa.
Muhammad Ijaz Khan tó jẹ́ ọlọ́pàá ìlú Peshawar sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ó tó ọ̀dúnrún sí irínwó ọlọ́pàá tó wà níbi agbègbè tí ìkọlù náà ti wáyé.
Mọ́ṣáláṣí náà ló wà lára àwọn ààyè tó ní ààbò jùlọ ní ìlú ọ̀hún tó fi mọ́ oríkò Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti àjọ tó ń gbógunti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí.
Nínú àtẹ̀jáde kan Sharif ní àwọn tó wà nídìí ìkọlù náà kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Islam.
Ó fi kun pé gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà ló ń gbógunti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí.
Lásìkò tí ìrun ọ̀sán ń lọ lọ́wọ́ ní nǹkan bíi aago kan àbọ̀ ọ̀sán ni ìkọlù náà wáyé ní ìlú tó pààlà pẹ̀lú Afghanistan.
Fídíò kan tó gba orí ayélujára èyí tí BBC ti ṣèwádìí rẹ̀ ṣàfihàn pé apá kan mọ́ṣáláṣí náà ló jì wọnú tí àwọn ènìyàn sì ń sáré láti sá kúrò.
Igbákejì Kọmíṣọ́nà ìlú Peshawar, Shafiullah Khan ní ìgbìyànjú ṣì ń tẹ̀síwájú láti yọ àwọn tó há sínú ìkọlù náà àti pé àwọn tún ti rí àwọn òkú kan yọ.
Agbẹnusọ ilé ìwòsàn Lady Reading, Mohammad Asim ní gbogbo àwọn tó ní ìpalára tí wọ́n gbé wá sí ilé ìwòsàn náà ló wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run.
Ilé ìwòsàn Lady Reading ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà burú jáì àti pé tí wọ́n sì sọ fún BBC pé wọ́n ṣì ń gbé àwọn ènìyàn tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà wá sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Bákan náà ni wọ́n ń pè fún kí àwọn ènìyàn wá fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn tó farapa.
Nínú oṣù Kẹta ọdún tó kọjá ni ìkọlù kọ́kọ́ wáyé ní Peshawar níbi tí wọ́n ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní mọ́ṣáláṣí Shia.