Èsì ìdánwò Naijiria rèé nínú orílẹ̀ède tó ní ìwà àjẹbánu jùlọ ní àgbáyé

Ajọ Transparency international, TI ti fi esei iwadii iwa ajebanu lagbaye ti wọn ṣe fun ọdun 2022 sita.

Ajọ Transparency International ti ẹka Naijiria lo gbe esi naa jade pe ipo 150 ninu 180 ni Naijiria wa lagbaye ninu awọn orilẹede to ni iwa ajẹbanu ju lagbaye.

Ajọ naa ni eyi tun mọ si pe iwa ajẹbanu si peleke si ni Naijiria amọ o ti walẹ ju ti ọdun 2021 ti wọn ṣe ipo 154 lọ.

Ajọ Transparency International naa ni bio tilẹ jẹpe awọn ọmọ Naijiria rọ wi pe ijọba yii yoo gbogun ti iwa ajẹbanu doju ami amọ nise ni ọrọ bẹyin yọ.

Wọn fikun un pe bio tilẹ jẹpẹ Iwa ajẹbanu walẹ si ju ti ọdun 2021 wa, iwa ajẹbanu ṣi jẹ ohun to kọni lominu ni Naijiria.

Awọn nkan to mu ki iwa ajẹbanu rọlẹ ni ọdun 2022 ju 2021 lọ ni;

  • Ajọ eleto idibo ni Naijiria, Inec to ṣe atunṣe eto ilera ni Naijiria to mu ki awọn eniyan tunbọ ni igbagbọ ninu eto idibo ni Naijiria ju ti tẹlẹ lọ.
  • Agbeyẹwo iwe ofin ọdun 1991 ni Naijiria ti wọn ṣatunṣe rẹ nipa bi awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe n ri owo wọn naa mu ki iwa ajẹbanu rọlẹ si.
  • Ṣiṣẹ ilana ofin lati risi bi wọn ṣe n na owo ti wọn ba rigba lọwọ awọn to n hu iwa ajẹbanu, iyẹn Proceeds of Crime (and Management) Act 2022 naa tun mu ki adinku ba iwa ajẹbanu ni Naijiria.
  • Bakan naa ni ofin tuntun Money Laundering (Prevention and Prohibition) Act 2022 naa rọ eto idajọ lagbara lati gbogun ti iwa ajẹbanu.

Awọn ohun to mu ki iwa ajẹbanu ṣi le tente ni Naijiria si ni?

  • Bi ijọba ṣe fi awọn oloṣelu kanti ọwọ tẹ to n hu iwa ibajẹ silẹ ṣakoba fun igbogun ti iwa ibajẹ, to si tun mu irẹwẹsi ba awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹnanu.
  • Ohun miran bii rẹ ni iwa ajẹbanu to si peleke laarin awọn ilumọọka ni Naijiria, paapaa bi ijọba ṣe ri 30 bilion naira gba pada lọwọ akọwe eto owo (Accountant general) ti ijọba apapọ tẹlẹ ri.
  • Bakan naa ni aibikita ijọba apapọ lati ṣweadii awọn ti orukọ rẹ jade ninu iwadii iwa ajẹbanu bii ti FinCen files, Panama Papers, Paradise Papers ati Pandora Papers.
  • Bi awọn kan ṣe n ji epo gbe lọ ni Naijiria naa wa lara iwa ajẹbanu to gbode kan ni Naijria.Eyi ti mu ki eto aabo dẹnukọlẹ to si n ṣakoba fun ọrọ ajẹ Naijiria.
  • Ajọ Transparency international naa ni ọrọ iranwọ ijọba ‘’subsidy’’ naa tun wa lara ọna ti iwa ajẹbanu fi peleke si Naijiria.
  • Titi di asiko yii ọwọngogo epo bẹntirol ko i tii kuro nilẹ, ti awọn kan ṣi gbe ayederu epo wọle si Naijria ni ọdun 2022 ọhun, ti ijọba ko si ṣewadii wọn.
  • Eyi ati awọn iṣe mii jẹ ki iwa ajẹbanu peleke ni Naijiria, ti wọn si rọ ijọba lati gbe igbeṣẹ lati koju awọn iwa ajẹbanu yii, ki orilẹede Naijiria le ni orukọ rere ni agbaye.