You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìyà tó tọ́ ni yóò jẹ àwọn Ọba tó ń ta ilẹ̀ ìjọba fáwọn tó ń gbin igbó l'Ogun - Gómìnà Abiodun
Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun, ti fẹsun kan awọn ọba kan nipinlẹ naa pe wọn ta ilẹ ijọba.
Gomina Abiodun wi pe awọn ọba naa ni wọn n talẹ igbo-ọba fawọn ọdaran kan to n filẹ naa gbin igbo.
Gomina wa wi pe igbagbọ oun ni pe ọrọ naa kii ṣe ootọ nigba ti wọn sọ fun oun, amọ ohun iyalẹnu ati ibanujẹ lo jẹ fun oun nigba tiwadii fi idi rẹ mulẹ.
Abiodun, to sọ ọrọ yii nibi ipade awọn lọbalọba nilu Abeokuta, wa kilọ pe ijọba ohun ko nii fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ẹnikẹni ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori.
Gomina naa wi pe “ọrọ pe awọn ọba kan n pin ilẹ ninu igbo-ọba ati awọn oko ijọba atawọn aaye miran lo ti de ọdọ wa ni Abeokuta nibi, taa gbọ pe wọn n pin-in wọn si n taa.
“O ṣoro fun mi lati gbagbọ pe awọn ọba alaye yoo maa lẹdi apo pọ mọ awọn kan lati hu iwa aitọ yii, to si jẹ pe pupọ ninu awọn ti wọn n taa fun ni kii ṣe ọmọ bibi ipinlẹ Ogun.
“Awọn kabiyesi wa n gbimọ pọ pẹlu awọn ajoji lati maa waa ba igbo-ọba jẹ nipinlẹ yii, ti wọn si n gbin igbo nibẹ.
“inu u mi bajẹ lọpọlọpọ nigba ti mo gbọ ọrọ yii taa si sẹ iwadii lati fi idi ọrọ naa mulẹ.
“Gẹgẹ bii ijọba to ṣetan lati ṣe ohun to tọ, a ko nii kuna lati fi iya to tọ jẹ gbogbo awọn ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori, ibaa jẹ ọba tabi ẹni yowu ko jẹ.
“Nitori pe ilẹ yii kii ṣe temi, bẹẹ ni kii ṣe tiwọn. Ohun ajogunba gbogbo wa ni, to yẹ ki a fi ṣe ọrọ ni. Kii sẹ ki a waa maa hu iwa to lee ba ori itẹ jẹ pẹlu rẹ.”
Ṣaaju ni kọmiṣọna fun ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ, Ganiyu Hamzat, ti dupẹ lọwọ awọn ọba alaye naa fun ajọṣepọ to dan mọran laarin wọn ati ijọba leyi to mu ki alaafia o maa jọba nipinlẹ naa, to si rọ wọn lati tunbọ maa ṣe atilẹyin fun ijọba ki idagbasoke lee jẹ kariile nipinlẹ naa.
Alaga igbimọ lọbalọba nipinlẹ naa to jẹ Akarigbo ti ilẹ Remo, Ọba Babatunde Ajayi, gboriyin fun Gomina Abiodun fun itọju awọn ọba, o si tun yonbo ipa to n ko lati mu ki idagbasoke o de origun mẹrẹẹrin ipinlẹ naa.