‘’Àìrówó ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ mi san ló sún mi débi ‘Korope’ wíwà’’

Abiamọ ku ọrọ ọmọ, Arabinrin Okoro Blessing di awakọ ero Korope lẹyin ti oun ati ọkọ rẹ ko rowo ile ẹkọ awọn ọmọ wọn san.

Arabinrin Blessing, to jẹ ọmọ ipinlẹ Enugu ni mi ni ijọba ibilẹ Awgu ṣalaye pe ‘’ilu Ibadan ni wọn bi mi si, amọ ilu Eko ni mo dagba si ko to di pe iṣẹ gbe ọkọ mi wa si ilu Ilorin ti mo fi bẹrẹ si ni wa ọkọ Korope.

O ti to ọdun kan bayii ti mo bẹrẹ si ni wa Korope.

Mo ti ta ounjẹ, irẹsi, ẹwa ni apo ri amọ awin ko jẹ ki n tẹsiwaju nipa iṣẹ yẹn.’’

Arabinrin Blessing ni ‘mo ni ki ọkọ mi wa Korope ti mo maa fi le maa ṣiṣẹ kaakiri wi pe ma a wa.

Ọkọ mi ro boya ere ni.

Mo wa awọn to maa n fun eeyan ni Korope lati wa ti mo maa wa fun wọn lowo lojumọ.

Amọ, ko sẹni to dami lohun tori pe obinrin ni mi.

O dẹ dun mi gan an tori mi o rowo ile ẹkọ ọmọ gan an san mọ.

Lẹyin o rẹyin, wọn bami ri ọkọ Korope gba lati maa fi ṣiṣẹ.’’

Blessing ni ko rọrun nigba ti oun kọkọ bẹrẹ, amọ awọn dẹrẹba yoku lo n tọ oun sọna.

‘’Ni bayii, mo dupẹ Ọlọrun, mo ti di akọṣẹmọṣẹ ninu Korope wiwa.

Kosi ibi ti mi o le lọ pẹlu Korope bayii.

Ipenija ti mo n doju kọ ninu Korope wiwa ni pe awọn ọkunrin kan maa n fi ilọkulọ lọ mi.

Amọ, emi mọ nkan ti n mo n ṣe.

Awọn mii maa n bu mi pe ori mi o pe wi pe ṣe Korope lo yẹ ki n maa wa.

Bakan naa lawọn mii maa n yin mi lawo pe mo n gbiyanju pẹlu Korope wiwa.

Mi ki n lo oogun fi wa Korope.

Ti mo ba ji nigba mii, gbogbo ara lo maa n ro mi.

Amọ, ti mo ba tun wo awọn ọmọ mi, ara mi tun maa ji siṣẹ, Blessing ṣalaye.