Àlàyé rèé bí àṣírí ṣe tú nípa ọkùnrin kan tó lúgọ sábẹ́ táyà bàálù ní pápákọ̀ òfurufú Ilorin pẹ̀lú èròńgbà láti jápa lọ Amẹrika

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọwọ ti tẹ ọkunrin kan, Segun Martins, ti wọn fura si pe oun gbiyanju ati japa lọna aitọ ni papakọ ofurufu Tunde Idiagbon to wa niluu Ilorin.

Ọkunrin naa ni a gbọ pe o fẹ lugọ si abẹ taya baalu Overland Airways kan to gbagbọ pe o n rinrinjo lọ silẹ Amẹrika.

Ajọ to n ri si irinajo ọkọ ofurufu ni Naijiria, Nigerian Civil Aviation Authority to fidi iroyin naa mulẹ sọ pe afurasi naa wa ọna lati de ibi abẹ taya baalu ọhun lasiko to fẹ gbera.

Agbẹnusọ NCAA, Michael Achimugu ni awọn ẹṣọ papakọ ofurufu naa tete gba mu ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii.

Achimugu sọ loju opo x pe "Ni nnkan bii iṣẹju meji kọja aago mẹta ọsan, ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Segun Martins ri aye wọ ibi ẹsẹ baalu Overland to fẹ gbera ko le ri aye sa pamọ sibi taya rẹ.

"Ọgbẹni Segun sọ fun wa pe oun gbagbọ pe ilẹ Amẹrika ni baalu naa n lọ ti oun si fẹ ba ọkọ naa lọ silẹ naa."

Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn eeyan yoo gbiyanju lati japa nipa sisa pamọ sibi taya baalu ni Naijiria.

Lọpọ igba lawọn eeyan naa maa n sa pamọ sinu ile ẹru awọn baalu ọhun lọna ati fi Naijiria silẹ.

Pupọ ninu awọn iṣẹlẹ yii lo maa n waye ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa niluu Eko.

Ṣe eeyan le sa pamọ sinu taya baalu lati japa?

Gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ sọ, o ṣoro pupọ lati lọ ilẹ mii nipa sisapamọ sinu ile ẹru tabi taya baalu, aimọkan lo si n ṣe ọpọ awọn to n gbiyanju rẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, pupọ ninu awọn to n ṣe bẹẹ ni wọn maa n padanu ẹmi wọn latari otutu to pọ ju tabi aisi afẹfẹ 'oxygen' ti eeyan maa n mi simu ninu irinajo naa.

Nigba mii ẹwẹ, awọn mii ninu wọn lo maa n jabọ ti baalu ba gbera tan to fi jẹ pe oku wọn ni awọn ẹṣọ papakọ ofurufu maa n ri lẹyinorẹyin.

Iṣẹlẹ yii n fi han pe awọn ẹṣọ alaabo papako ofurufu ko ṣiṣẹ wọn to bii iṣẹ ni ọkunrin yii fi ri aye wọ ibi ti ko yẹ ko de.

Wayi o, ti o ba n gbero lati japa nipa sisa pamọ sinu ile ẹru baalu tabi taya ọkọ ofurufu, ma dan wo, iku tabi abamọ ni yoo gbẹyin rẹ.