Ìjọba Amẹ́ríkà ṣe òfin tuntun méjì fáwọn arìnrìnàjò láti Nàíjíríà, wo bó ṣe kàn ọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ọọfisi ijọba Amẹrika ni Naijiria ti kede pe awọn yoo bẹgi dina ẹnikẹni to ba fẹ gba fisa ilẹ naa lati lọ bi ọmọ ki ọmọ le di ọmọ oniluu l'Amẹrika.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan loju opo X ijọba ilẹ ọhun lọjọ Aje.

Atẹjade naa sọ pe "a ko ni fun ọ ni fisa ti a ba gbagbọ pe eredi abẹwo rẹ si Amẹrika ni lati lọ bimọ sọhun ki ọmọ rẹ le jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika."

Ó di èèwọ̀ fún ọmọ Naijiria láti lọ bímọ s'Amérika láti di ọmọ onílùú – Ìjọba Amẹrika

Wọn fidi rẹ mulẹ pe awọn ko ni gba ẹnikẹni laaye lati maa lọ silẹ awọn "latari ọmọ bibi nikan ṣoṣo."

Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti ile ẹjọ kan sọ ninu oṣu Kẹfa pe Trump le tẹsiwaju ninu igbesẹ to fẹ gbe lati dena awọn to n lọ Amẹrika lati lọ bi ọmọ sibẹ.

Amọ ṣa, awọn ilẹ ẹjọ kan ti pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ọhun.

Ti ẹ ko ba ba gbagbe, lara awọn igbesẹ ti Trump kọkọ gbe gẹgẹ bii Aarẹ kẹtadinlaadọta ilẹ Amẹrika ni lati fopin si bi awọn eeyan ṣe n gba we igbelu latari ibi ti wọn bi wọn si.

Igbesẹ naa jẹ ọkan gboogi lara awọn igbesẹ to ṣeleri lati gbe fun ọjọ pipẹ amọ iroyin ni yoo le diẹ lati le ṣe gbogbo ohun to yẹ ki igbesẹ ọhun le wa si imuṣẹ.

Amọ ṣa, kii ṣe Naijiria nikan nikan ni Amẹrika ti kede irufẹ igbesẹ bayii, o tun kede iru rẹ ni awọn orilẹede miii lagbaye bii Uganda, Jamaica, The Caribbeans, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lati nnkan bii ọgọfa ọdun sẹyin ni ilẹ Amẹrika ti bẹrẹ ki enikẹni ti wọn ba bi silẹ maa di ọmọ oniluu amọ Trump ni o to gẹ bayii.

Ijọba Amẹrika tun kede atunṣe ilana wiwọ ilẹ rẹ lai kọkọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun fisa

Ọọfisi ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ ilẹ okeere, US Department of State ti kede awọn ti ko ni nilo lati lọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo ki wọn to gba fisa gẹgẹ bii alejo silẹ rẹ, bẹrẹ lati ọjọ keji, oṣu Kẹsan an, ọdun 2025 yii.

Awọn koko atẹjade naa ree

Gbogbo ẹni to ba fẹ gba fisa abẹwo s'Amẹrika ti ọjọ ori wọn din ni ọdun mẹrinla atawọn ti ọjọ ori wọn ti le ni ọdun mọkandinlọgọrin gbọdọ yọju si ọọfisi ijọba Amẹrika fun ifọrọwanilẹnuwo

Awọn ti ko nilo lati wa ṣe ifọrọwanilẹnuwo ni awọn to fẹ gba fisa to wa ni ipin A-1, A-2, C-3, G-1, G-2, G-3, G-4, NATO-1 titi de NATO-6, tabi TECRO E-1

Awọn to wa ni ipin C-3 ti wọn jẹ oluranlọwọ tabi alabaṣiṣẹ osiṣẹ ilẹ Amerika tabi ijọba gbọdọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun fisa

Awọn to ba fẹ lọ ilẹ Amẹrika lorukọ ijọba Naijiria ko nilo ifọrọwanilẹnuwo fun fisa

Awọn mii ti ko nilo lati ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun fisa ni awọn to ba fẹ fikun ọjọ ori fisa B-1, B-2, B1/B2, tabi awọn to ni iwe " Border Crossing Card/Foil" wọn laarin ọdun kan ki ọjọ to lọ lori fisa naa

Ki eeyan to le pegede lati ma ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun fisa yii, o gbọdọ jẹ ẹni ti ọjọ ori rẹ ti le ni ọdun mejidinlogun soke nigba to gba fisa akọkọ, o si gbọdọ kọwe fun fisa naa ni orilẹede bibi rẹ to n gbe, o si gbọdọ jẹ ẹni ti ijọba Amẹrika ko tii kọ lati fun ni fisa ri

Mọ̀ nípa ìlànà tuntun tí ìjọba UK ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde àti bó ṣe kan ọmọ Nàìjíríà tó lé ní 10,000

Ìjọba orílẹ̀ èdè United Kingdom, UK ti kéde àwọn ìlànà tuntun lórí báwọn iléeṣẹ́ ṣe lé máa gba àwọn èèyàn láti ilẹ̀ òkèèrè àti fífún àwọn òṣìṣẹ́ ní físà.

Ìjọba UK, lójúnà àti mú àdínkù bá bí àwọn èèyàn ṣe ń wọ orílẹ̀ èdè náà, ní àwọn ti yọ iṣẹ́ ọgọ́rùn-ún kúrò lára àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti máa fún àwọn èèyàn ní ìwé àtìlẹyìn láti ṣiṣẹ́.

Bákan náà ni wọ́n tún kéde pé àwọn ti mú àlékún bá owó oṣú táwọn òṣìṣẹ́ míì tó wà lábẹ́ abala yìí yóò máa gbà pẹ̀lú ìdá ọgbọ̀n (30%).

Wọ́n ní àwọn ti yọ àwọn iṣẹ́ kan kúrò lára àwọn èyí tí wọ́n le gba àtìlẹyìn lé lórí àyàfi tí wọ́n bá jáde lára àwọn iṣẹ́ tí wọn kò ní èèyàn tó nínú àtẹ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ gbé jáde.

Lára àwọn iṣẹ́ tí wọ́n yọ jẹ́ jíjẹ alákoso láwọn ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn, ètò ìtọ́jú àwọn arúgbó, ètò ìlera iléeṣẹ́ ìpoògùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Kí ni àwọn nǹkan tó wà nínú ìlànà tuntun náà?

Ní oṣù Karùn-ún ni ìjọba UK ti kọ́kọ́ kéde pé àwọn ń ṣe àwọn àyípadà sáwọn ètò gbígba físà wọn.

Ìjọba UK ti ní àyípadà máa wáyé sí bí àwọn èèyàn ṣe ń gba físà wọ orílẹ̀ èdè náà pàápàá láti àwọn orílẹ̀ èdè tó jẹ́ pé àwọn èèyàn wọn kìí fẹ́ kúrò mọ́, tí wọ́n bá ti wọ orílẹ̀ èdè náà.

Lábẹ́ èròńgbà Home Office tuntun yìí, àwọn èèyàn láti Pakistan, Nigeria àti Sri Lanka ni ó ṣéeṣe kó ṣòro láti rí físà wọ UK tún le díẹ̀ si.

Àwọn Mínísítà gbàgbọ́ pé àwọn tó ń wọ UK bó ṣe tọ́ lábẹ́ òfin láti àwọn orílẹ̀ èdè náà fún iṣẹ́ tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n kìí fẹ́ kúrò mọ́, tí wọ́n sì máa ń bèèrè fún ààbò láti máa gbé UK lọ títí.

Wọ́n ti wá kéde àwọn ìlànà náà tí wọ́n sì sọ pé ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Keje, ọdún 2025 ni wọ́n sọ pé ètò tuntun yìí yóò gbérasọ, èyí tó ti ń fa inú fu àyà fu láàárín àwọn èèyàn pàápàá àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè náà.

Ìlànà tuntun yìí ní àlékún yóò bá owó táwọn òṣìṣẹ́ tó ní ìwé ẹ̀rí lọ́wọ́ di £41,700 tàbí jù bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bí iṣẹ́ wọn bá ṣe lọ sókè sí nígbà tí àwọn tó wà ní ètò ìlera àti ìtọ́jú arúgbó ṣì wà ní £25,600.

Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn tó ń gba èèyàn síṣẹ́ gbọdọ̀ ṣàfihàn rẹ̀ pé owó tí wọ́n ń sọ fáwọn òṣìṣẹ́ wọn lọ́dún jẹ́ £25,600 lẹ́yìn tí wọ́n bá yọ gbogbo àwọn owó tó yẹ, tó fi mọ́ owó ilé àti owó ọkọ̀.

Pẹ̀lú ìlànà tuntun yìí, àwọn iṣẹ́ tí iléeṣẹ́ máa ń ṣe àtìlẹyìn fún láti gba àwọn èèyàn síṣẹ́ láti orílẹ̀ èdè mìíràn lẹ́ka ìmọ̀ ẹ̀rọ àtàwọn míì ni wọn kò ní sí ààyè fún láti gba físà fún wọn mọ́ àyàfi tí iléeṣẹ́ bẹ́ẹ̀ bá ṣetán láti fi owó kún owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́.

Ìjọba UK tún mú àlékún bá iye ìwé tí èèyàn le kà sí ipele kẹfà, ìyẹn ẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, kí wọ́n tó le kà á kún ẹni tí iṣẹ́ gidi wà lọ́wọ́ rẹ̀.

Àwọn iṣẹ́ tó wà lábẹ́ ipele kẹfà yìí ni ó ṣeéṣe kí wọ́n yọ kúrò lábẹ́ ìlànà tuntun yìí.

Ìkéde tuntun yìí ló ti ń mú ìbẹ̀rù bá àwọn àlejò tó wà ní UK pàápàá àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ yọ kúrò náà.

'Ọ̀pọ̀ àwọn Nàìjíríà tó wà ní UK ló ṣeéṣe kí wọ́n padà sí Nàìjíríà'

Nígbà tó ń ṣàlàyé ìlànà tuntun náà, onímọ̀ nípa ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè tó fi UK ṣe ibùjókòó, Kayode Alabi sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn The Punch pé àwọn ọmọ Nàìjíríà àtàwọn ọmọ oríilẹ̀ èdè míì tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n yọ kúrò náà ni ó ṣeéṣe kí wọ́n má rì í ọ̀nà gbé e gbà nígbà tí físà sáà tí wọ́n ń lo lọ́wọ́ bá parí.

Ó ṣàlàyé pé àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn kò ní lè gba físà míì lẹ́yìn tí àtìlẹyìn ti iléeṣẹ́ tí wọ́n ń bá ṣíṣẹ fún wọn bá tán.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ì tíì sí ọmọ Nàìjíríà kankan tí wọ́n gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ látàrí ìlànà tuntun yìí, ó wòye pé lẹ́yìn tí físà wọn bá wá sí ìparí ni wọ́n máa mọ odó tí wọ́n máa da ọ̀rúnlá sí.

"Àwọn tí wọ́n bá ti yọ iṣẹ́ wọn lábẹ́ ìlànà tuntun yìí kò ní lè rí iṣẹ́ míì, wọn kò sì ní lè gba físà míì, tí èèyàn kò bá sì ní físà, ó ti di ẹni tó ń gbé nílẹ̀ òkèèrè lọ́nà àìtọ́.

"Ìpèníjà táwọn èèyàn tí iṣẹ́ wọn ṣì wà lábẹ́ ìlànà tuntun yìí ni pé ṣe iléeṣẹ́ tí wọ́n ń bá ṣiṣẹ́ ṣetán láti mú àlékún bá owó oṣù tí wọ́n máa fún àwọn òṣìṣẹ́ èyí tó ti lékún láti £24,000, £25,000 àti £26,000 di £41,700.

Alabi sọ pé ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ni wọ́n ti ń kó àyà sókè látàrí òfin tuntun yìí.

Bákan náà ni àwọn ọmọ Nàìjíríà tí físà wọn kò ní pẹ́ parí ti ń kọminú lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ wọn ló ń wòye pé ó ṣeéṣe kí àwọn padà sílé tí àwọn kò bá mọ odó tí wọ́n máa da ọ̀rúnlá sí.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ló ṣeéṣe kí ìlànà tuntun yìí ṣe àkóbá fún tí ọ̀pọ̀ wọn sì lè padà sí Nàìjíríà tàbí kí wọ́n gba orílẹ̀ èdè mìíràn lọ.