Kí ló dé tí ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí NYSC gba àgùnbánirọ̀ obìnrin láàyè láti wọ síkẹ́ẹ̀tì?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọjọ ti pẹ ti a ti mọ awọn agunbanirọ nilẹ Naijiria pẹlu imura bii ologun, tawọn obinrin naa yoo si wọ sokoto kaki bii awọn ọkunrin ologun.

Amọ awọn obinrin kan to n sinru ilu maa n pariwo loore koore pe ẹsin awọn ko fara mọ wiwọ sokoto, ti wọn si n beere pe ki ajọ NYSC maa fi aaye gba awọn lati wọ sikẹẹti.

Lẹyin ọpọ awuyewuye ti ko ni ojutu fun ọpọ ọdun, awọn obinrin agunbanirọ meji to laya bii kininu, gbe ajọ NYSC lọ sile ẹjọ lati ja fun ohun ti wọn pe ni ẹtọ awọn naa.

Awọn obinrin mejeeji naa, ti wọn jẹ ẹlẹsin Kirisitẹni ni ẹsin awọn ko fi aaye gba sokoto wiwọ.

Bakan naa, wọn fi kun pe ajọ NYSC ko gba awọn laaye lati pari isinru awọn tori pe awọn kọ lati wọ sokoto.

Wọn fikun pe, ajọ naa ko tun fun awọn niwe ẹri pipari eto isinru ilu, to si tẹ ẹtọ awọn mọlẹ pupọ.

"NYSC n gbogun ti wa tori aifẹ wọ sokoto sinru ilu, igbesẹ wiwọ sokoto si tako asẹ Ọlọrun ninu Bibeli"

Awọn agunbanirọ obinrin mejeeji naa, Omidan Ogunjobi Blessing ati Omidan Ayuba Vivian, ti pe ẹjọ tako ajọ yii.

Wọn salaye pe awọn n koju iṣoro lati ọdọ NYSC nitori aifẹ wọ ṣokoto sinru ilu.

Ninu ẹjọ ti awọn agunbanirọ mejeeji pe lọtọọtọ, ti nọmba ẹ jẹ FHC/ABJ/CS/989/2020 ati FHC/ABJ/CS/988/2020, ni wọn ti ni ẹsin igbagbọ ti awọn n sin, lodi si ki obinrin wọ ṣokoto.

Ẹsẹ Bibeli, Deuteronomy 22:5, ni wọn fi gbe awijare wọn lẹsẹ.

Wọn ni ẹsẹ Bibeli naa sọ pe obinrin ko gbọdọ wọ asọ to ba n ṣe ti ọkunrin.

Wọn fi kun un pe, NYSC ti ko laṣọ meji ju ṣokoto lọ yii, huwa to le mu awọn ṣẹ si aṣẹ Ọlọrun, ajọ naa si tun doju ija kọ awọn lori ẹ.

NYSC, fi awọn obinrin agunbanirọ to ba fẹ wọ yẹri dipo ṣokoto silẹ, lati wọ yẹri wọn - Ileẹjọ gbe idajọ kalẹ

Ile ẹjọ giga to wa niluu Abuja, lasiko to n gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ti awọn agunbanirọ mejeeji naa pe, ko yẹ ki ajọ NYSC kan-an nipa fawọn agunbanirọ obinrin lati maa wọ sokoto.

Ileejọ naa sọ pe bo ṣe jẹ pe ṣokoto ni tọkunrin-tobinrin to ba n sinru ilu labẹ eto National Youth Service Corps (NYSC) maa n wọ, jẹ titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ.

O ni eyi tako ẹtọ ọmọniyan lati ṣe ẹsin to ba wu u pẹlu.

Adajọ Hauwa Yilwa to sọ eyi di mimọ, paṣẹ ninu idajọ rẹ, pe ki NYSC fi awọn obinrin agunbanirọ to ba fẹ wọ yẹri dipo ṣokoto silẹ, lati wọ yẹri wọn.

Adajọ Yilwa sọ pe bi ajọ naa ṣe sọ ṣokoto nikan di aṣọ ti wọn fi aaye gba, tako anfaani ti orilẹede yii fun eeyan lati wọ aṣọ to wu u .

Yàtọ̀ sí wíwọ síkẹ́ẹ̀tì, àwọn àgùnbánirọ̀ yìí tún bèèrè mílíọ́nù mẹ́wàá owò gbà-má-bínú

Ninu ohun ti awọn agunbanirọ naa beere fun ninu iwe ipẹjọ wọn ni pe ki ajọ NYSC fi aaye gba agunbanirọ obinrin yowu lati wọ sikẹẹti, ti i ṣe aṣọ ọbinrin.

Awọn ọmọbinrin to pe NYSC ati ọga agba pata ajọ naa lẹjọ, tun ni ki ile ẹjọ jẹ ki ajọ naa mọ pe wọn ti tapa si abala 38(1) ofin ọdun 1999, to fi aaye gba awọn lati wọ aṣọ to ba wu awọn.

Bakan naa ni wọn ni NYSC tako abala keji ofin to da ajọ naa silẹ ti ọdun 1993.(Schedule 2, Article 1(I)(a) of the NYSC Bye-Laws 1993.)

Paripari rẹ ni owo gba-ma-binu ti Blessing ati Vivian beere fun, wọn ni miliọnu mẹwaa naira lawọn fẹ ki NYSC san fawọn.

"NYSC, san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000) owo gba ma binu fun agunbanirọ obinrin meji to pe ẹjọ"

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Hauwa Yilwa, sọ pe bi NYSC ṣe gba ṣokoto nikan laye, lodi labẹ ofin.

O paṣẹ pe ki wọn jẹ ki obinrin ti ko ba fẹẹ wọ ṣokoto, wọ sikẹẹti.

Adajọ sọ pe titẹ ẹtọ wọn loju labẹ ofin ọmọniyan, ati ẹsin igbagbọ loju, ni iwa ti ajọ NYSC n hu.

Ni ti owo nla ti awọn agunbanirọ naa beere, Adajọ Yilwa yi owo gba ma binu naa si ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (500,000).

O paṣẹ pe ki NYSC sanwo naa fun ẹnikọọkan wọn bii gba-ma-binu, latari idojukọ ti wọn ri latọdọ ajọ to n ri si isinru ilu naa.

"Mo paṣẹ pe ki NYSC pe awọn akẹkọọ ti ọrọ yii kan, ki wọn si fun wọn ni iwe ẹri wọn bo ṣe yẹ.''

Adajọ Yilwa lo paṣẹ bẹẹ.

Idajọ naa sọ pe bi wọn ko ṣe gba awọn agunbanirọ naa laye lati pari isinru ilu nitori aṣọ lasan, tumọ si pe wọn ya wọn sọtọ nitori ẹsin ti wọn yan laayo ni.

Amọ titi di akoko yii, ajọ NYSC ko tii fesi lori idajọ naa.

Ki ni ajọ NYSC wa fun?

Ọdun 1973 ni wọn da ajọ National Youth Service Corps silẹ, ofin Decree No. 24 ti wọn ṣe lọjọ kejilelogun oṣu Karun-un ọdun 1973 ni wọn si fi gbe e kalẹ.

Wọn gbe eto naa kalẹ lẹyin ogun abẹle ọdun1967, ki wọn le mu iṣọkan wa kaakiri Naijiria lẹyin ogun.

Awọn akẹkọọ to ba kawe tan nileewe giga ni wọn yoo gbe lati ipinlẹ wọn lọ si apa ibo miran, lati mọ bi wọn ṣe n ṣe lọhun-un ati fun iṣọkan Naijiria.

Ọdun kan ni isinru ilu naa fi maa n waye, aṣọ kaaki oniṣokoto ati ẹwu ti wọn si ti n wọ latigba naa ni wọn ṣi n wọ titi doni.

Ijọba si maa n sanwo diẹdiẹ fun wọn lati fi so apo wọn ró.

Ọpọ igba ni ọrọ aṣọ wiwọ yii maa n mu awuyewuye dani.

Awọn akẹkọọ-binrin kan ninu awọn onigbagbọ ati awọn ẹlẹsin Islam to n sinru ilu ti ṣokoto wiwọ naa ko ba lara mu si maa n tako o.