You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọlọ́pàá fi pampẹ́ mú Pásítọ̀ àtàwọn méjì míì lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fẹ́ kó ọmọdé ṣòwò ẹrú
Ileeṣẹ ọlọpaa lolu ilu ilẹ Naijiria Abuja ti kede pe awọn ti mu arakunrin Pasitọ kan,ibatan rẹ ati dirẹba to wakọ lori ẹsun pe wọn fẹ ko awọn ọmọde mejila sinu lọ ṣowo ẹru nipinlẹ Ogun.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa fi sita o ni lọsan ọjọ Ẹti lawọn mu arakunrin dirẹba to ko awọn ọmọ naa sinu ọkọ yii ni nkan bi ago ago kan oru ku iṣẹju marun un.
Ọjọ ori awọn ọmọde yi wa laarin ọdun marun un si ọdun mẹrindinlogun.
Alukoro ọlọpaa Josephine Adeh sọ pe ọwọ awọn tẹ Muhammad Isah ti ilu Kafanchan awakọ bọọsi ti nọmba idanimọ rẹ jẹ APP 489 XE nibi to ti ko awọn ọmọ mejila, ọkunrin mẹrin ati obinrin mẹjọ.
O tẹsiwaju pe iwadii ibẹrẹ tawọn yi ṣe ti fihan pe Pasitọ kan Simon Kado aati ibatan rẹ Jesse Simon Kado to wa ni ahamọ ọlọpaa yi lo ṣagbatẹru eto kiko awọn ọmọ yi lati Akwanga nipinlẹ Nasarawa lọ si ipinlẹ Ogun.
Josephine Adeh fi kun pe bayii ti iwadii ṣi n tẹsiwaju pẹlu akẹgbẹ wa nipinlẹ Nasarawa lori ọna ati da awọn ọmọ yi pada sọdọ mọlẹbi wọn ''Kọmiṣana ọlọpaa FCT fẹ fi da awọn araalu loju pe awọn ko fi aabo wọn ṣere rara''
Lẹnu lọọlọ yi ni olu ilu ilẹ Naijiria ti n koju ipenija ijinigbe ati iwa janduku lemọlemọ.
Ni oṣu Kini ọdun 2024 yi ni awọn ọlọpaa Abuja ṣeku pa awọn ajinigbe mẹta kan ninu igbo to wa lagbegbe Bwari nilu Abuja.
Agbegbe Bwari yi ni naa ni awọn ajinigbe ti gbe awọn ọmọ marun un kan ati baba wọn ti wọn si pada ṣeku pa ọkan ninu wọn lẹyin ti wọn si pada tun gba owo idoola aimọye miliọnu Naira.
Iṣẹlẹ fifi ọmọde ṣowo ẹru jẹ eleyi to tako ofin orileede Naijiria ṣugbọn ti ọpọ ṣi n kopa ninu rẹ .
Awọn ti aje ọrọ yi ja mọ lori a maa saba sọ pe ọmọ ọdọ lawọn fẹ fi awọn ọm yi ṣe ati pe awọn obi wọn mọ nipa rẹ.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju lati mọ ibi ti wọn n ko awọn ọmọde mejila yi lọ nipinlẹ Ogun.