UK gbé òfin tuntun kalẹ̀ fún àwọn tó bá fẹ́ 'jápa' sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wo bó ṣe kàn ọ́

Ijọba ilẹ Gẹẹsi lo ti gbe iye owo oṣu ti awọn to fẹẹ japa wa si orilẹede naa lati ṣiṣẹ gbọdọ maa gba soke ju ti tẹlẹ lọ ki wọn too le gba ‘Visa’.

Igbesẹ yii lo wa lara ilana ijọba ilẹ naa lati mu adinku ba oye eeyan to n wa si orlẹede naa lati ṣiṣẹ, ti wọn si n ko gbogbo mọlẹbi wọn dani.

Ẹni to ba fẹẹ gba iwe lati wọle si orilẹede naa ni owo ti o n gba lọdun kan ni lati jẹ ẹgbẹrun mejidinlogoji o le ẹẹdegbeje dollar, leyi to pọ ju igbalelẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn dollar to jẹ tẹlẹ.

Bakan naa ni ẹni to ba ti n siṣẹ nilẹ Gẹẹsi tẹlẹ ni lati maa gba iye owo tuntun yii lọdun ki wọn too le pe mọlẹbi wọn kankan wa.

Afikun yii wa lara ilana marun un tuntun ti akọwe ọrọ abẹle lorilẹede naa, James Cleverly, kede lọjọ Aje.

Cleverly wi pe bi awọn eeyan ṣe n ya wọ ilẹ naa pọ pupọ, bẹẹ lo tun sọ pe awọn eeyan ti n ṣi eto iwe aṣẹ igbelu fun awọn oniṣẹ ilera lati okeere lo.

Awọn aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ Conservative ni wọn waako pẹlu Olootu Ijọba Rishi Sunak ati iṣejọba rẹ lati wo bi awọn eeyan ṣe n wọ ilẹ naa lẹyin ti awọn alaṣẹ wi pe eeyan ẹgbẹrun lọna ojilelẹẹdẹgbẹrin ati marun un (745,000) lo wọ ilẹ naa lọdun to kọja.

Cleverly wi pe awọn ohun ti ijọba fẹẹ ṣe lẹyin owo ti wọn gbe soke yii ni:

  • Ilana marun lati mu adinku ba iye eeyan to n wọle sorilẹede naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun lọdọọdun
  • Ifofinde awọn oṣiṣẹ eto ilera lati maa ko awọn mọlẹbi wọn dani
  • Fifi opin si igbalaaye awọn ileeṣẹ lati maa san owo to din ida marun fawọn oṣiṣẹ
  • Lati gba ‘Visa’ fun idile kan, wọn ni lati maa gba owo ti ko din ni ẹgbẹrun mejidinlogoji o le ẹẹdegbeje dollar
  • Ṣiṣe agbeyẹwo ‘Visa’ akẹkọọ to faaye gba wón lati lo ọdun meji lẹyi ẹkọ wọn

“Igbesẹ tuntun yii lewu fun ẹka eto ilera”

Akọwe apapọ ajọ oṣiṣẹ Unison, Christina McAnea, lo ti wi pe igbesẹ ijọba yii yoo ṣe akoba fun eto NHS ati itọju awọn alaisan.

McAnea wi pe “awọn to waa ṣiṣẹ lati ilẹ okeere ti wọn ko awọn mọlẹbi wọn dani ko nii le gba iwe tuntun, abi ki wọn sọ fun wọn pe ki wọn da awọn ọmọ wọn pada silu wọn.

“Aisi awọn oṣiṣẹ lo mu ki awọn eeyan yii o waa ṣiṣẹ nibi. Awọn ileewosan ati ile itọju ni wọn ko lee ṣiṣẹ lai si awọn eeya wọnyi.”

“Awọn to fẹẹ ṣiṣẹ yoo wa lai ko mọlẹbi wọn dani”

Cleverly to ni eto irinna gbọdọ jẹ ohun to tọ, to tẹle ofin, ti yoo si ṣee gbọkanle, wi pe awọn oṣiṣẹ eto ilera kan ko nii fẹẹ wa mọ nitori aile ko mọlẹbi wọn dani, amọ oun nigbagbọ pe eyi ko lee jẹ idiwọ fun awọn to ṣetan lati ṣiṣẹ ni tootọ.

Ẹwẹ, aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ Labour to n moju to akọwe fọrọ abẹle, Yvette Cooper, wi pe eto irinna tuntun yii “jẹ ọkan lara aogbọraẹniye to ti gbinlẹ laarin ijọba yii”.

O wi pe bo tilẹ jẹ pe o yẹ ki iye awọn to n wọle sorilẹede naa o walẹ, o yẹ ki ilana kikọ ati gbigba awọn ọmọ ilẹ naa siṣẹ o wa.