You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram tó lé ní 100 rí sómi
Awọn adari ikọ Boko Haram to le ni ọgọrun ti ri si omi lasiko ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn lọwọ ikọ ọmọogun Naijiria to ṣigun bo wọn.
Ipinlẹ Borno ni ikọ Ọmọogun ofurufu ati tori ilẹ ti kọju ija si awọn agbesunmọmi naa.
Ninu ọrọ wọn, ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni gbogbo ibi ti wọn n sa pamọ si ni igbo Sambisa ni wọn ṣekọlu si patapata.
Bakan naa ni awọn ikọ Boko Haram miran sa asala fun ẹmi wọn nitori ojo arọrọda to waye ni ipagọ wọn nibẹ.
Awọn ẹṣọ alaabo ni oku awọn eniyan ti wọn yọ kuro ninu omi, ju ọgọrun lọ, ti wọn si ti sin wọn.
‘’Ẹgbẹgbẹrun eniyan lo ti ku ninu ikọlu Boko Haram’’
Gẹgẹ bi iroyin ṣe fi lede, ojo arọrọda to fa omiyalẹ ni agbegbe Yedzaram lo ṣe akoba fun awọn agbegbe ti awọn ẹṣọ alaabo wa, ti eyi si mu ki wọn sa kuro nibẹ lati doola ẹmi ara wọn.
Lati igba ti ogun ikọ Boko Harm yii ti bẹrẹ ni nkan bii ọdun mẹwaa ṣẹyin, ẹgbẹgbẹrun eniyan lo ti ku, ti awọn eniyan to le ni miliọnu meji si ti di alairile gbe.
Amọ laipẹ yii ni Ajọ eleto aabo ni Naijiria pẹlu awọn adari wọn gbe igbeṣẹ lati koju ija kọ wọn ni ara ọtọ, ti eyi si mu aṣeyọri dani.
Bakan naa ni a ri awọn ikọ Boko Haram naa to jọwọ ara wọn, ti wọn si wa ni panpẹ ijọba.
Awọn ikọ agbesunmọmi bii ISWAP ati ANSARU lo n ṣọṣẹ ni ẹkun ariwa orilẹede Naijiria fun ọpọlọpọ ọdun bayii.