You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bí Gómìnà Sanwo-Olu ṣé dúró sókè òkun lẹ́yìn tí ilé dàwó ṣáfihàn pé kó nífẹ́ Ìlú – Jandor
Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP, Azeez Olajide Adeniran, ti ọpọ eeyan mọ si Jandor, ti bu ẹnu atẹ lu ihuwasi Gomina Eko, Babajide Sanwo-Olu lori iṣẹlẹ ile alaja meje to wo ni agbegbe oniru, Lekki ni Eko.
Adeniran ninu atẹsita kan to gbe si oju opo ayelujara Twitter rẹ ni, to ba jẹ pe ijọba ipinlẹ Eko tẹle ileri to ṣe lọdun 2021, lẹyin ti ile kan dawo, irufẹ iṣẹlẹ naa ko tun ni waye.
O ni o ṣe ni laanu pe awọn ko le beere ibeere lọwọ gomina ipinlẹ Eko nitori o kọ lati wa silẹ Naijiria, lẹyin ti o gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
‘Awọn to n sejọba ni Eko, ko mọ isẹ wọn nisẹ’
“A ko le beere ibeere lọwọ gomina ti a dibo yan, ẹni ti o ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa ati iwadi ijẹkujẹ to fa ki ile dawo.
Amọ Sanwo-Olu kọ lati wa si orilẹede Naijiria , to si duro si orilẹede Amẹrika lati ma pin ami ẹyẹ.
Iwa iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC ti a ni nipinlẹ Eko ti safihan pe awọn to n ṣejọba ko mọ isẹ wọn nisẹ.
O fikun pe wọn ko bikita nipa awọn eeyan ipinlẹ Eko."
“Bi ẹgbẹ oṣelu yii ṣe n ṣe ijọba lo gbe wa de ibi ti a wa loni nipinlẹ Eko, nibi ti a ko ti bikita nipa ẹmi awọn araalu.
Eyi lo si n se akoba fun ọjọ ọla ipinlẹ Eko nitori àrè ti wọn fẹ ri loni.
Adeniran wa bawọn mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ati awọn to farapa kẹdun, to si ni ki Ọlọrun mu wọn duro lasiko yii.
Ọrọ ti Oludije gomina fun PDP l‘Eko sọ nipa awọn to ku nibi ile to dawo ko bojumu - APC
Wayi o, agbẹnusọ fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, Seye Oladeji ti fesi si ọrọ naa, to si sapejuwe iwa oludije sipo gomina fẹgbẹ PDP gẹgẹ bi iwa ọmọde.
“Ijọba ipinlẹ Eko kii dẹkun lati ṣe iwadi lori irufẹ iṣẹlẹ bayii ati lati gbe igbesẹ to yẹ lati fi dena rẹ nitori ọjọ ọla.
A mọ pe awọn kọrọlọsi ẹda kan wa ninu isejọba, ti wọn fẹ da iṣejọba APC ru nipinlẹ Eko, sugbọn Ijọba Sanwo-Olu ko ni fun awọn anfani.
“Ọrọ to ti ẹnu oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP jade lori iku awọn eeyan yen nitori ọrọ oṣelu, ni ko bojumu rara.
Irọrun awọn olugbe ipinlẹ Eko lo jẹ ijọba logun, a si daabo bo ẹmi ati dukia awọn olugbe naa, ti ko si ni dawọ duro.
"Kí ni èrè ẹkùn gúúsù nínú PDP bí alága àti olùdíje ààrẹ bá wá láti ẹkùn àríwá?"
Ọkan lara eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bode George ti ni alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Ayu Iyorcha gbọdọ kọwe fi ipo rẹ silẹ, to ba fẹ ilọsiwaju ẹgbẹ.
Bakan naa lo ni ti Ayu ba fẹ aseyọri PDP ninu eto idibo ọdun 2023, se lo yẹ ko kọwe fipo silẹ.
Bode George salaye fun BBC pe eto ati ilana ti awọn oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu PDP gbe kalẹ, ko fi aye gba pe ki oludije ati alaga ẹgbẹ wa lati ẹkun ijọba kannaa.
“Awọn to da ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ wa lati ẹkun gbogbo lorilẹede Naijiria, a ni Oloye Bola Ige, Alex Ekwueme, Jim Nwobodo ati awọn miiran.
‘Wọn pin PDP si mẹfa ki ẹkun kọọkan le ni anfaani si ipo alagbara’
Wọn pin iṣejọba ẹgbẹ naa si mẹfa lati ri pe alaafia jọba ninu ẹgbẹ oselu naa.
“A gbe ẹgbẹ yii kalẹ lọna ti ẹkun ijọba kọọkan yoo fi ni ẹtọ ninu ipo mẹfa to lagbara ni Naijiria, lati ori oludije aarẹ si alaga ẹgbẹ."
O ni ọkan gboogi to fa rogbodiyan lọwọlọwọ bayi ni bi atunto ṣe ba ilana iṣejọba ẹgbẹ oṣelu PDP.
O ni nipaapa julọ ifigagbaga to waye laarin Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ati Oludije sipo aarẹ, Atiku Abubakar.
‘Ayu ati Atiku to wa lati ẹkun ariwa lo fa awuyewuye ninu PDP’
Bode George tẹsiwaju pe “Ilana ẹgbẹ PDP ni pe ẹkun ijọba kọọkan lo ni ẹtọ si ipo ninu ẹgbẹ naa.
Sugbọn ni bayii, a ni Oludije sipo aarẹ, Atiku Abubakar ati Ayu Iyorcha, ti wọn dijọ wa lati apa ariwa Naijiria .
“Eyi gan lo fa awuyewuye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ti a si gbọdọ bu omi pa a.
“Ẹkun ariwa nikan ko da bori eto idibo, wọn lilo iranwọ awọn eeyan lati apa miiran .
“Ni bayii, ki ni a fẹ sọ fun awọn eeyan wa ni apa guusu, papa julọ guusu iwọ oorun lati ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ipo wo la fẹ sọ pe o kan awọn eeyan wa lẹkun guusu ninu eto iselu PDP?
Ipo wo la fẹ sọ pe o kan awọn eeyan wa lẹkun guusu ninu eto iselu PDP.
Ibeere yii ni Bode George n bi awọn asaaju ẹgbẹ oselu PDP?
“Wọn ki a ni suuru, ka jẹ ki ibo pari, bawo ni mo se fẹ ṣọ fun awọn eeyan pe wọn ni ka ni suuru?”
Oloye Bode George ni ẹgbẹ oṣelu naa ni lati ṣe ohun to tọ, ti oun si ni igbagbọ pe yoo se bẹẹ.
George ni PDP ni awọn olori pipe laarin wọn lati yanju aawọ naa.
Àwọn ọmọdé, tí kò lóye ló ní kí n kọ̀wé fípò alága PDP sílẹ̀, ariwo lásán ni - Ayu
Alaga ẹgbẹ PDP ni Naijiria, Iyorchia Ayu ti ni ohun ìbanujẹ lo jẹ pe awọn kan fẹ ki oun kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii alaga.
Ayu ni pupọ lara awọn to ni erongba naa ni wọn jẹ ọmọ kekere tí wọn ko ni agbọye lori erongba ẹgbẹ PDP.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News, Ayu, ẹni to ti fi igba kan jẹ sẹnetọ ri, ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP dibo yan oun lori ilana ti ẹgbẹ naa gbe kalẹ.
O ni ti ẹgbẹ oselu PDP yoo ba tìẹ ṣe ìdibo abele lati yan awọn adari wọn, awọn oludije sipo aarẹ ko ni anfani lati dupo naa.
Ọpọlọpọ awuyewuye lo tí n waye lẹyin idibo abẹnu ẹgbẹ oselu PDP larin ẹgbẹ ati oludije sipo aarẹ to lulẹ, eyiu Nyesom Wike.
Wike ni wọn fẹsun kan pe ko ṣe atilẹyin fun oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar fun eto ìdibo ọdun 2023.
Wike wa fesi pe ti PDP ba fẹ ki oun satilẹyin fún Atiku Abubakar, alaga ẹgbẹ, Iyorchia Ayu, ẹni to wa lati ẹkun ariwa pẹlu Atiku, gbọdọ kọwe fipo silẹ.
Nigba to n fesi lori ọrọ naa, Ayu ni oun ko níbi lọ nítorí wọn yan oun gẹgẹ bii alaga pẹlu ilana ati ofin ẹgbẹ oselu PDP ni.
O ni fun idi eyi, oun ko ni kọwe fipo silẹ nitori pe awọn kan n beere pe ki oun se bẹẹ.
" Wọn dibo yan mi gẹgẹ bi alage ẹgbẹ oselu PDP fun ọdun mẹjọ, ti n ko ti lo ọdun kan.
"Ọrọ Atiku ati ìdibo abẹnu ko ni nkan ṣe pẹlu ibo alaga ẹgbẹ oselu PDP.
" N ko sẹ, bí ilọsiwaju ẹgbẹ oselu PDP yoo ṣe waye ni o jẹ mi logun. Ariwo ọja lásán ni.
"Mo mọ pe nko jí owo ẹgbẹ, n ko ṣẹ ẹsẹ kankan, fun idi eyi ń ko ni nkankan lati sọ."
Bakan naa ni Ayu tẹsiwaju pe awuyewuye to wa laarin oludije sipo aarẹ labẹ PDP, Atiku Abubakar ati Gomina Ipinle Rivers ko le ṣe idiwọ fun aseyọri ẹgbẹ.
Ayu ni wọn ti da ẹgbẹ oselu PDP silẹ kí awọn ọmọde to darapọ mọ wọn nítorí wọn ko mọ nípa gbogbo alakọja ẹgbẹ oselu naa.
"Nigba ti a bẹrẹ irinajo ẹgbẹ oselu PDP, a ko ri awọn ọmọde yii.
Ọmọde ni wọn nítorí wọn ko mọ nípa bí a se da PDP silẹ ati idi ti a fi dasilẹ, fun idi eyi, a ko ni fun wọn ni anfani lati da ẹgbẹ ru."