Ìlú ò fararọ lẹ́ka ìpèsè oúnjẹ tí ìjọba kéde, wo bí ọ̀rọ̀ ṣe lè kan ìwọ náà

Aarẹ Bola Tinubu kede lọjọ kẹtala, oṣu Keje pe nkan ko fararọ faraalu lẹka ounjẹ tori naa awọn yoo gbe igbesẹ lati koju rẹ gẹgẹ bi ijọba.

Agbẹnusọ rẹ̀, Dele Alake, lo kede eyi fun awọn akọroyin nile ijoba nílùú Abuja.

Lẹnu lọọlọ yi, ọpọ lo n kerora lori bi owo ounjẹ ati awọn nkan eelo miran ti ṣe gbowo lori.

Bi a ba tun wo ti yiyọ ẹkunwo lori epo bẹntiroo lasiko yi, a o ri pe tipatipa lawọn eeyan fi n ri bukata gbọ.

Igbesẹ ijọba lori ọrọ yi wa ninu atẹjade ti wọn fi sita, bẹẹ naa si ni wọn ṣalaye awọn nkan ti wọn yoo ṣe lati koju ipenija yi.

Ki ni ipa ti eto ti wọn fẹ sẹ le ni lara araalu?

A kan si onimọ nipa eto ọrọ aje kan lati yannana ọrọ yi fun wa.

Kini ikede ilu o fararọ lẹka ipese ounjẹ tunmọ si?

Bismark Rewane, to jẹ onimọ nipa ọrọ aje sọ fun BBC pe kikede ilu o fararọ yi tunmọ si pe ijọba ti ri wi pe owo ounjẹ tilọ sọke, ti o si nilo igbesẹ kiakia lati fi koju ipenija yi.

''Ikede yi jẹ nkan ti o niṣe pẹlu ipese ounjẹ to si di dandan ki ijọba wa ojutu si.

Ọna ati ri ounjẹ yi ti di iṣoro bẹẹ si ni owo ti wọn n ta eleyi to ba de ọja naa si ti di gọbọi''

Onimọ yi sọ pe paṣiparọ iye owo Naira si ti ilẹ okere to wa nita bayii yoo lapa lori igbesẹ ijọba lati mu ki ounjẹ pọ yanturu.

''O ni mimu adinku ba iye taa fi n parọ Naira si owo ilẹ okere jẹ igbesẹ pataki lati le fi ṣe eleyi''

Ni ṣoki, o ni ijọba ni lati mu adinku ba iye ti wọn na ninu akoto owo lati le pese iranlọwọ to peye lẹka ounjẹ.

Bakan naa ni onimọ mii Victor Aluiyi sọ pe ti Naijiria ba fẹ koju ipenija ipese ounjẹ yi, o ni lati koju aisi aabọ to peye.

O ni gbogbo ilakaka ijọba ko le so eso rere bi wọn ko ba koju aisi aabo to n ko ọkan araalu soke ni paapa lagbegbe ariwa Naijiria.

Awọn onimọ mii fara kin ọrọ ti Aluyi sọ ti wọn si ni o di dandan ki ijọba ri pe ileri eto aabo to peye ti wọn ṣe di amuṣẹ ki awọn agbẹ baa le pada soko lalaafia.

Aluyi wa sọ pe ki araalu maa reti iyipada ninu bi ọrọ ipese ounjẹ ti ṣe ri bo ti lẹ jẹ pe o ni yoo ṣe diẹ ki wọn to ri iyipada yi amọ yoo wa bo pẹ bo ya.

Ipo wo ni eto ọrọ aje Naijiria wa bayii?

Idẹnukọlẹ ọrọ aje Naijiria sọ ọpọ sinu agbami iṣẹ ohun oṣi tawọn mii si n sa lọ silẹ okere lati wa ọna ijẹ imu.

Gẹgẹ bi banki agbaye ti ṣe sọ, lasiko taa n sọrọ mimu adinku ba iṣẹ ni Naijiria yi, awọn to wa nipo pe iṣẹ n ta wọn ni Naijiria yoo lekun si pẹlu miliọnu mẹtala laarin 2019 si 2025.

Afojusun banki agbaye ni pe ẹka ọrọ aje Naijiria yoo gbe pẹẹli si ni ida 2.9% lọdun kọọkan laarin 2023 ati 2025.

Wọn fi kun pe idagbasoke yi yoo wa lati ẹka iṣẹ iṣe oko owo ati karakata.

Ohun ti ijọba gbero lati ṣe

Dele Alake to gbẹnusọ fun aarẹ Tinubu sọ pe ijọba gbero lati fi owo subsidy ti wọn yọ kuro mu agbega ba ẹka ọgbin.

Awọn ilana ti ijọba kede pe awọn yoo gbe si ree:

  • Ipese ajilẹ ati owo iranwọ ti yoo mu inira yiyọ subsidy dinku fawọn agbẹ ati mọlẹbi wọn.
  • Ajọṣepọ to munadoko ni lati waye ni kiakia laarin ileeṣẹ ọgbin ati ileeṣẹ to n mojuto ọrọ omi ki iṣẹ ọgbin abomurin lasiko ẹrun.
  • Ṣiṣe idasilẹ ajọ ti yoo maa ṣakoso iye owo nkan ounjẹ lọja ati awọn igbesẹ miran ti yoo jẹ ki owo nkan oko duro deede.Ajọ yi naa ni ijọba yoo fi maa mojuto iye owo ounjẹ lọja
  • Ipese aabo to peye fawọn agbẹ ki wọn baa le ṣiṣẹ ọgbin lai ni ifoya kankan
  • Ajọṣepọ pẹlu awọn ileeṣẹ ti yoo pa oko fawọn agbe ti wọn baa le raye dako si.
  • Mimu atunto ba eto irina,kiko pamọ ati tita nkan ọgbin nilẹ okere.

Ki lo le jẹ ipenija fawọn ilana yi?

Eyi to pataki ninu awọn ipenija ti onwoye Aluyi ṣalaye fun BBC ni ti aabo to peye.

O ni oore nla lo jẹ pe Naijiria kii koju awọn ipenija layika tabi loju ọjọ bi awọn orileede miran.

''Bẹẹni a ni omiyale lọdun to kọja ṣugbn lorileede wa yi, ko si awọn ipenija to lagbara tabi ajalu to le ṣakoba fun ipese ounjẹ.

"Ohun to ṣe koko ni riri awọn ounjẹ yi gbe lati ibi kan si omiran lai si idiwọ.Idi ree ti a fi gbọdọ wa ojutu si ọrọ aabo.

Gẹgẹ bo ṣe wi lakotan, o ni bi aabo ba ti ni iyanju, ọrọ ounjẹ lọpọ yanturu yoo di afisẹyin ti eegun n fiṣọ.