You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oluyemi Adeyemi ‘Suara’ tó jẹ́ àgbà òṣèré tíàtà Yoruba, jáde láyé
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Oluyemi Lawrence Adeyemi, ti ọpọ eeyan mọ si Suara, ti jade laye.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, ọsu Kẹsan an, ọdun 2023 ni oloogbe naa jade laye gẹgẹ bii atẹjade kan ti ọmọ rẹ, Adetoun Adeyemi, fi lede.
Atẹjade naa ni “Pẹlu ibanujẹ ọkan ati ibọwọ fun Ọlọrun ni a fi kede iku baba, ọkọ, baba-baba, ẹgbọn ati ibatan wa, Oluyemi Layrence Adeyemi (suara)....”
“Inu wa dun nitori pe o ti lọ sinmi.”
“A rọ awọn araalu ki wọn fun wa laaye lati ṣọfọ rẹ, a o maa kede bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ laipe.”
Ọpọ awọn ololufẹ Suara ati ololufẹ tiata Yoruba lo ti bẹrẹ si n ṣedaro oloogbe naa bayii.
Nigba to n daro rẹ loju opo Instagram, ọmọ rẹ Aderoju Adeyemi ni oun ko le gbagbe awọn ẹkọ ile ti o kọ oun lailai.
Nnkan bii ọdun 2001 ni irawọ Suara bẹrẹ si n milẹ titi lagbo tiata Yoruba.
Ọpọ eeyan bẹrẹ si n mọ orukọ rẹ si ‘Suara’ lẹyin to kopa ninu ere ‘Oh Father, Oh Daughter’ ti ileeṣẹ Wale Adenuga gbe jade.
Lara awọn to ti ba ṣiṣẹ pọ ni Sola Sobowale, Bukky Wright, atawọn agba ọjẹ oṣere mii.