You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìsìnkú Baálẹ̀ Èṣù, Kayode Eṣuleke, bẹ̀rẹ̀ l'Osogbo
Ètò isinku gbajugbaja oniṣẹṣe to fi ilu Osogbo, nipinlẹ Osun ṣe ibugbe, Oloogbe Kayode Esuleke tawọn eeyan mọ si Baalẹ Eṣu ti bẹrẹ l'Osogbo.
Bi wọn ṣe gbe oku agba oniṣẹṣe to ka Kurani ati Bibeli de opin naa de si agboole wọn ti i ṣe ile Olugun, Isalẹ Ọja-Ọba, l'Osogbo, lọjọ Kẹrinla, oṣu Keji ọdun 2025 yii ni wọn ti bẹrẹ ẹyẹ ikẹyin fun un.
Gẹgẹ bi awọn eleto isinku ṣe ṣalaye fun BBC, ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji ọdun yii ni wọn yoo sin Baalẹ Eṣu nilana iṣẹṣe.
Ẹni ọdun marundinlaadọrun-un (85) ni.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni Baalẹ Eṣu jade laye.
Ta a ni Baalẹ Eṣu?
Oloogbe Kayode Esuleke, Baalẹ Eṣu, jẹ ọkan lara awọn ongbotarigi oniṣẹṣe ati onisegun niluu Osogbo ati kaakiri agbaye.
Eṣuleke jẹ oye Baalẹ Eṣu tilu Osogbo, oun naa si tun ni Baba Isalẹ fun awọn Oniṣẹṣe l'Osogbo ati ipinlẹ Osun pata nigba aye rẹ.
Baalẹ Eṣu tun kopa ninu oṣelu, ọmọ ẹgbẹ APC ni.
Oloogbe Esuleke ti figba kan ri jẹ Kansilọ adugbo, oun si ni ẹni akọkọ to bura wọle sipo Kansilọ pẹlu lilo ada ati ìbọn.
Ọdun 1955 lo ti ka Bibeli ati Kurani de opin.
Nigba to n ṣalaye iru eeyan ti Oloogbe Esuleke jẹ, Araba Awo Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon, sọ pe Esuleke jẹ ẹni to maa n fi otitọ ṣe ohun gbogbo ni gbogbo ọna.
O ni oniwa pẹlẹ eeyan, alaanu ati olufọkansin ninu nilana iṣẹ iṣegun ni.