Iléẹjọ́ ní kí wọ́n yẹgi fún ọmọ China tó ṣekúpa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ ọmọ Naijiria ní Kano

Ileẹjọ giga kan ni ipinlẹ Kano ti dajọ pẹ ki wn yẹgi fun ọmọ orileede China kan

Frank Geng Quarong lori ẹsun pe o ṣekupa ọrẹbinrin rẹ ọmọ Naijiria kan Ummulkhulsum Sani Buhari.

Adajọ Sanusi Ado-Ma’aji ninu idajọ to gbe kalẹ lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹta sọ pe arakunrin Quarong jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Idajọ naa si ni pe ki wn yẹgi fun titi ti ẹmi yoo fi bọ lọrun rẹ.

LọjọKejilelogun oṣu Kẹsan ọdun 2022 ni ọwọ awọn agbofinro tẹ Quanrong ti wn si fi si ahamọ lori ẹsun iṣekupani arabinrin ẹni ọdun mejilelogun naa ni ibugbe rẹ to wa ni Janbulo ni ijọba ibilẹ Kumbotso ni Kano.

Gẹgẹ bi awọn olupẹjọ ti ṣe wi, ẹsun yi tako alakaalẹ abala 221 ti iwe ofin orileede Naijiria.

Bi ẹjọ naa ti ṣe waye

Mọlẹbi ati awọn olugbe agbegbe Janbulo nibi ti arabinrin to padanu ẹmi rẹ yi ti wa sọ fun BBC pe Ummukulthum Sani ati Geng jijọ fẹ ara wọn fun igba kanna ko si daju ohun to fa ede aiyede laarin wọn.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe wọn ba ti wn ti fi ọbẹ rẹ Umumulkulthum lọrun nigba ti wọn yoo fi ri oku rẹ.

Bappa Sani jẹ olugbe adugbo ti Ummu n gbe .

O ṣalaye pe arabinrin naa ti kọkọ lọkọ kan tẹlẹ ṣugbọn igbeyawo naa ko pẹ ko to tuka.

Lẹyin igba naa lo bẹrẹ si ni fẹ ọmọ orileede China yii.

‘’A mọ daada ladugbo wa.O lọkọ tẹlẹ ko to di pe igbeyawo naa tuka.Ko pẹ sigba naa la gbọ pe o bẹrẹ si ni fẹ ọmọ China yii’’

‘’Lalẹ ana(nigba ti iṣẹlẹ naa waye nigba naa lọhun)mo n pada bọ wa si ile nimo gbọ tawọn eeyan ladugbo mii n sọ nipa nkan to ṣẹlẹ fun mi.Wọn ni arakunrin ọmọ China yi fo igana lati fi wọ inu ile Ummu to si fi ọbẹ pa.’’

Wọn ti n fẹ ara wọn tipẹ ki iṣẹlẹ yi to waye

Bakan naa, ni arakunrin kan Ahmad Abdullahi ti o jẹ ọrẹ mọlẹbi Ummukulthum Sani sọ pe awọn jade lọ jẹun ni ita lawọn gbọ pe iṣẹlẹ yi waye.

O ṣalaye pe ''ile Ummi ni mo maa n wa lọpọ igba nitori bi mọlẹbi lo jẹ si mi.Tori naa emi ati aburo rẹ jade ni nkan bi ago mẹsan an alẹ lati lọ ra ounjẹ''

''Baa ṣe n pada bọ la ri ti ero pe biba siwaju ile nigba naa la to gbọ nipa nkan to ṣẹlẹ''

O fi kun alaye rẹ pe ''Geng ti n fẹ Ummi tipẹ koda ọrẹkunrin lo jẹ si ki o to fẹ ẹlomiran. Gbogbo wa la mọ ninu ile. Koda wọn a maa joko sinu ile rojọ''

Ahmad ni oun mọ pe wọn ni ede aiyede kan diẹ laipẹ yi ati pe ''o sọ fun Geng pe oun ko ṣe mọ. Nkan to mu inu bi niyẹn''

Ahmad ṣalaye pe awọn ri Geng mu nigba to n gbiyanju lati sa lọ.