Ummukulthum kàgbákò ikú lọ́wọ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ ọmọ China,ọlópàá ní ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano ti mu arakunrin ọmọ orileede China kan, Geng Quanrong, lori ẹsun pe o ṣeku pa ọrẹbinrin rẹ ọmọ Naijiria.

Gẹgẹ bi awọn mọlẹbi obinrin naa ati awọn araadugbo ṣe sọ fun BBC, arabinrin Ummukulthum Sani ati Geng ti n fẹ ara wọn to ọjọ mẹta.

Wọn ko ribi fidi ọrọ mulẹ ohun to fa ede aiyede laarin wọn to fi mu ko ṣeku pa.

Arakunrin Bappa Sani n gbe adugbo kanna pẹlu Ummukulthum o si ni arabinrin naa ti lọkọ tẹlẹ ṣugbọn igbeyawo naa ko tọjọ ki o to bẹrẹ si ni fẹ Geng.

''A mọ Ummi daada ladugbo wa, o ti lọkọ tẹlẹ ṣugbọn wọn ti kọ ara wọn. Ko pe si igba naa la gbọ pe o n fẹ arakunrin ọmọ China naa''

''Lalẹ ana mi o si nile nigba tawọn eeyan bẹrẹ si ni pe mi lori ago pe arakunrin ọmọ China naa fo iganna wọle wọ iyara Ummukulthum to si fi ọbẹ pa''

Bakan naa, ni arakunrin kan Ahmad Abdullahi ti o jẹ ọrẹ mọlẹbi Ummukulthum Sani sọ pe awọn jade lọ jẹun ni ita lawọn gbọ pe iṣẹlẹ yi waye.

O ṣalaye pe''ile Ummi ni mo maa n wa lọpọ igba nitori bi mọlẹbi lo jẹ si mi.Tori naa emi ati aburo rẹ jade ni nkan bi ago mẹsan an alẹ lati lọ ra ounjẹ''

''Baa ṣe n pada bọ la ri ti ero pe biba siwaju ile nigba naa la to gbọ nipa nkan to ṣẹlẹ''

Wọn ti n fẹ ara wọn tipẹ ki iṣẹlẹ yi to waye

O fi kun alaye rẹ pe ''Geng ti n fẹ Ummi tipẹ koda ọrẹkunrin lo jẹ si ki o to fẹ ẹlomiran.Gbogbo wa la mọ ninu ile.Koda wọn a maa joko sinu ile rojọ''

Ahmad ni oun mọ pe wọn ni ede aiyede kan diẹ laipẹ yi ati pe ''o sọ fun Geng pe oun ko ṣe mọ. Nkan to mu inu bi niyẹn''

Ahmad ṣalaye pe awọn ri Geng mu nigba to n gbiyanju lati sa lọ.

O ni awọn sare gbe Ummi lọ si ile iwosan to wa ni itosi ile amọ dokita sọ pe o padanu ọpọ ẹjẹ tori naa ẹpa ko boro mọ.

Wọn tipada sin oku Ummi nilana musulumi ni nkan bi ago mẹsan owurọ ọjọ Abamẹta.

Ohun ti ọlọpaa wi nipa iṣẹlẹ yi

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano, SP Abdullahi Haruna sọ fun BBC pe awọn ti mu ọmọ China yi ati pe iwadii ti bẹrẹ.

''Lootọ la mu ọmọ ilẹ China kan,Geng Quanrong to fo iganna lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o ṣeku pa ọrẹbinrin rẹ''

''Iwadii ṣi n tẹsiwaju lakoko yi''

Ọlọpaa naa sọ pe awọn yoo tuṣu de isalẹ koko lati mọ pato nkan to ṣẹlẹ ki awọn to wọ Geng lọsi ile ẹjọ.

Ileeṣẹ iroyin BBC kan si Mike Zhang to jẹ olori awọn ọmọ ilẹ China ni Kano ṣugbọn amugbalẹgbẹ rẹ sọ pe o rinrinajo lọ si China.

O ni awọn naa yoo gbiyanju lati wadi nkan to ṣẹlẹ lori ọrọ yi.