Ààrẹ Amẹ́ríkà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu bí iléẹjọ́ ṣe gba láti sún ìdàjọ́ Trump ṣíwájú

Aarẹ Joe Biden orilẹede Amẹrika ti bu ẹnu ẹtẹ lu idajọ ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede naa lati sun idajọ aarẹ Amẹrika tẹlẹ ri, Donald Trump, lori ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an ṣiwaju.

Aarẹ Biden sọ pe ohun to lewu ni ile ẹjọ n fi lelẹ pẹlu idajọ naa.

Biden ni idajọ yii lodi si titẹle ofin, bẹẹ ni ko si dara fawọn ọmọ orilẹede Amẹrika.

Ṣaaju ni Trump ti kan saara si ile ẹjọ to ga julọ pe idajọ ti wọn gbe kalẹ tumọ si pe eto ijọba awarawa lo bori.

Awọn adajọ fidi rẹ mulẹ lọjọ Aje wi pe ofin ko faye gba aarẹ Amẹrika lati jẹjọ lori ohun to ni ṣe pẹlu ọrọ ijọba, amọ, ofin faye gba a lati jẹjọ lori ohun ti ko ni ṣe pẹlu ọrọ ijọba.

Lẹyin naa ni ile ẹjọ da ẹjọ naa pada sọdọ adajọ to n jokoo lori ẹjọ naa tẹlẹ.

Idajọ yii yoo tubọ da igbẹjọ Trump duro lori ẹsun ọdaran ti wọn fi kan pe o gbiyanju lati ṣe eeru pẹlu esi ibo aarẹ ọdun 2020 ninu eyi ti Biden ti jawe olubori.

Ni bayii, adajọ to n jokoo lori ẹsun ti wọn fi kan Trump ni yoo sọ awọn ẹsun ti wọn fi kan Trump nigba to wa ni ipo aarẹ.

O le to gba adajọ ni ọpọlọpọ oṣu lati le ṣe eleyii, koda, igbẹjọ le ma waye lati asiko yii titi di oṣu Kọkanla ti eto idibo aarẹ Amẹrika yoo waye.

Aarẹ Biden sọ lori tẹlifisan lọjọ Aje lẹyin idajọ ile ẹjọ to ga julọ pe ‘’ori ipilẹ ti orilẹede Amẹrika duro le lori ni pe ko si ọba ni Amẹrika, ori o jori ni gbogbo wa loju ofin.

Ko si ẹni to ju ofin lọ, koda, aarẹ orilẹede Amẹrika gan an ko ju ofin lọ.

Amọ, idajọ ile ẹjọ yii tumọ si pe aarẹ Amẹrika le ṣe ohun to ba wu u.''

Trump fẹ ki ile ẹjọ yi ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an danu

Awọn agbẹjọro Trump ti kepe ile ẹjọ lati yi ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an danu.

Bakan naa lawọn agbẹjọro yii tun beere lọwọ ile ẹjọ wi pe ko paṣẹ idaduro idajọ Trump loṣu yii.

Awọn agbẹjọro Trump sọ ninu iwe ti wọn kọ si adajọ pe idajọ ile ẹjọ to ga julọ ọjọ Aje ti fun Trump lanfani lati ma jẹjọ lori ẹsun to ni ṣe pẹlu ohun to ṣẹlẹ nigba ti o fi jẹ aarẹ Amẹrika.

Loṣu Karun un ọdun yii ni ile ẹjọ dajọ pe Trump jẹbi ẹsun onikoko mẹrinlelọgbọn pe o yi iwe lori okowo rẹ.

Ọjọ kọkanla oṣu keje yii ṣi ni wọn fi idajọ Trump si lori ẹsun ti wọn fi kan an naa.

Awọn agbẹjọro Trump n wi awijare w pe o buwọlu iwe okowo rẹ ti wọn n sọ nigba to fi jẹ aarẹ Amẹrika lọdun 2017.

Ṣugbọn adajọ ijọba apapọ kan ti kọ iwe si Trump wi pe o ti kuna lati fidi rẹ mulẹ pe o ṣe aṣemọṣe yii nigba ti nigba ti o jẹ aarẹ Amẹrika.

Ẹwẹ, idajọ ile ẹjọ to ga julọ ọjọ Aje gbe idajọ kalẹ lori ẹsun mii ti wọn fi kan Trump pe o gbiyanju lati doju esi ibo aarẹ ọdun 2020 bolẹ.