Iléeṣẹ́ Aṣọ́bodè gba ilé ẹrù tó kó ìbọn 800 àti ọta ìbọn 112,500 níbùdókọ̀ ojú omi

Ileesẹ asọbode nilẹ wa ti mu awọn afurasi mẹta lori ile ẹru kan ti wọn gba ni ibudokọ oju omi Onne to wa nipinlẹ Rivers.

Ile ẹru naa lo kun fun awọn ohun ija oloro lorisirisi atawọn oogun oloro pẹlu asọ bọsikọrọ ti wọn ko wọ Naijiria.

Ọga agba pata fun ileesẹ asbode nilẹ wa, Adewale Adeniyi lo se afihan awọn ohun ija oloro ati oogun oloro naa ni ibudokọ oju omi Onne lọjọ Aje.

Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye, Adeniyi ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kọkanlelogun osu Kẹfa ọdun 2024 yii ni ọwọ awọn osisẹ rẹ ba ile ẹru naa eyi ti olokoowo kan fẹ fi ọna ẹburu gbe wọle.

O ni olokoowo naa fẹ gbe ẹru naa wọle lai lọwọ awọn asọbode ninu, to si lọ ja ile ẹru ọhun si ibudokọ oju omi tawọn aladani.

Adeniyi fikun pe, awọn ọtẹlẹmuyẹ kan to n tọpinpin ile ẹru naa, to n bọ lati orilẹede Turkey, ni wọn n sọ bo se n gba awọn oniruuru orilẹede kọja pẹlu ajọsepọ awọn ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ni abẹle ati yika agbaye.

Adeniyi salaye pe “Nigba ti a se ayẹwo ile ẹru naa bo se yẹ, a ri oniruuru ibọn ti apapọ rẹ jẹ ojilelẹgbẹrin ati mẹrin (844) pẹlu ọta ibọn to to ẹgbẹrun lọna ojilelẹẹdẹgbẹfa ati ẹẹdẹgbẹta (112,500).

Awọn ohun ija oloro yii ni wọn ko pamọ sinu awọn eroja miran bii ilẹkun, awọn ọpa omi ati baagi alawọ.

Owo ori to yẹ ki wọn san lori ile ẹru naa si lo le ni biliọnu mẹrin Naira (N4.171bn).

Ni afikun eyi, afurasi mẹta lo ni ileeṣẹ aṣọbode tun ni lakata wọn bayii.

Eyi ṣee ṣe lẹyin ti wọn gba iwe aṣẹ lati mu awọn afurasi naa pamọ lati ile-ẹjọ.

Ṣaa, iwadii n tẹsiwaju lati ri i daju pe gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu iwa yii ni ọwọ ofin ba gẹgẹ bo ṣe sọ.

Òògùn òyìnbó rẹpẹtẹ ni wọ́n tún bá nínú kọ̀ǹténà mí-ìn

"Aṣọbode tun gba ile ẹru aṣọ aloku oyinbo ti owo rẹ to miliọnu lọna mẹrinlelogoje Naira (N144m)"

Iṣẹlẹ miran to tun fara pẹ ti akọkọ ni ti kọntena nla kan ti ọga aṣọbode sọ pe awọn tun ri gba lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2024 yii.

O ṣalaye pe awọn oogun oyinbo lo kun inu kọntena naa.

Awọn oogun ikọ bii Codeine onigiraamu ọgọrun-un kan to le ni miliọnu niye, Trodol benzhexol ti ko din ni miliọnu mẹta aabọ niye, onigiraamu marun-un si ni awọn eyi bo ṣe wi.

Bi wọn yoo ba sanwo lori awọn ẹru yii, Adeniyi sọ pe biliọnu mẹsan-an ati aabọ (9.6b) lo yẹ ki wọn san.

Ọga aṣọbọde fi kun un pe wọn fi idi kọntena ọhun ti sibi kan ni ile ikẹru si to wa lagbegbe Onne.

Lẹyin eyi ni awọn aṣobode tun gba kọntena aṣọ aloku oyinbo ti owo rẹ to miliọnu ọgọrun-un kan ati mẹrinlelogoji (144m).

Gẹgẹ bi ofin iṣẹ aṣọbode ti 2023 ṣe wi, o ni gbogbo ohun ti ileeṣẹ naa gba yii ni wọn yoo da pada fun adari to n ri si awọn nnkan ogun, eyi to wa labẹ ọfiisi Oludamọran fun ọrọ aabo. Lẹyin naa ni iwadii yoo tẹsiwaju pẹlu lilọ si kootu.

Ni ti awọn afurasi mẹta to wa ni ahamọ wọn, Adeniyi sọ pe wọn yoo ṣe iranwọ nipa titọka awọn yooku wọn ti wọn jọ n ṣe fayawọ.

Bakan naa lo ni awọn kọntena mẹjọ mi-in tun wa ti wọn parọ ohun to wa ninu wọn.

O ni awọn onifayawọ naa ṣe bẹẹ ki wọn ma baa sanwo to yẹ lori ọja ti wọn ko.

Wọn ti gba iwe aṣẹ awọn ile ẹru ti wọn gbe kọntena naa si bo ṣe wi, ileeṣẹ aṣọbode si ti fi ofin de awọn ibudo ti wọn gbe awọn kọntena yii si titi ti wọn yoo fi mọ boya wọn lọwọ nibẹ loootọ abi bẹẹ kọ

‘Aṣọ́bodè tó bá gbàbọ̀dè yóò jìyà lábẹ́ òfin’