You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìbúgbàmù àdó olóró ṣekúpa èèyàn àádọ́ta níbi ayẹyẹ àjọ̀dún ọjọ́ ìbí ànọ́bì
Ko din ni eeyan aadọta to ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ibugbamu ado oloro kan to waye ni orilẹede Pakistan.
Agbesunmọmi kan lo so ado oloro naa mọra lasiko to bu.
Awọn alaṣẹ sọ pe lẹba mọṣalaṣi kan ni agbegbe Balochistan l'ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ yi tiwaye lasiko tawọn eeyan peju lati ṣe ajọdun ibi Anọbi taa mọ si Maolud Nabbiy.
Bayi awọn alaṣẹ Balochistan ti kede ilu o fararọ.Ko yi ti si ẹnikankan to jade pe awọn lo wa nidi iṣẹlẹ ijamba yi.
Ẹwẹ lagbegbe itosi kan,ibugbamu mi ti waye ni mọṣalasi kan lẹba Peshawar lagbegbe Khyber Pakhtunkhwa
Fọnran taa ri lati ibi ti iṣẹlẹ ibugbamu Mastung ni Balochistan yi ṣafihan ọpọ to farapa tawọn oṣiṣẹ adoola ati araalu lagbegbe naa n sare lati doola wọn.
'Nṣe ni ẹsẹ mi bẹrẹ si ni gbọn ti ibugbamu naa si lami mọlẹ'
Alaye ti Ọgbẹni Hazoor Bakhsh, ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ ṣe fun ileeṣẹ iroyin AFP ni pe ṣe ni iṣẹlẹ naa da jinnijinni bolẹ.
''Nṣe ni ẹsẹ mi bẹrẹ si ni gbọn ti ibugbamu naa si lami mọlẹ''
Ẹni ọdun mọkandinlaadọta naa sọ pe bi eruku to bo ilẹ ṣe n parẹ diẹ loun ri tawọn eeyan fọnkan kaakiri ti wọn si n pariwo ẹ gbami.
Iṣẹlẹ yi kọja agbara awọn ileewosan ti wọn n gbe awọn to farapa lọ tawọn alaṣẹ si n polongo lori ẹrọ ayelujara pe kawọn eeyan wa fi ẹjẹ silẹ fun itọju awọn to farapa.
Ọga ọlọpaa agbegbe Balochistan, Abdul Khaliq Sheikh fidi iṣẹlẹ ibugbamu yi mulẹ.
O ni ọga ọlọpaa kan padanu ẹmi rẹ nigba to n gbiyanju lati kọdi ẹni to ṣe ibugbamu yi.
Minisita feto ọrọ abẹle Pakistan, Sarfraz Bugti juwe iṣẹlẹ yi gẹgẹ bi ''eleyi to buru gidi gaan '' to si bẹnu atẹ lu awọn iṣẹlẹ agbesunmọmi mejeeji to waye yi.
Ẹwẹ agbẹnusọ ọlọpaa agbegbe Khyber Pakhtunkhwa sọ pe awọn ribi dena ọkọ kan ti wọn ko ado oloro sinu rẹ ati awọn eeyan meji to so aṣọ ado oloro iku mọra.
O ni awọn gbẹmi ọkan ninu awọn ẹni yi lẹnu ọna mọṣalaṣi nigba to fẹ wọle nilu Hangu.
A ko le sọ pato iye eeyan to farapa ninu iṣẹlẹ ti Hangu amọ awọn ọlọpaa lo ṣeeṣe ki awọn eeyan kan ha sabẹ ile nigba ti orule mọṣalaṣi dawo.
Ki lawọn iṣẹlẹ to ti waye sẹyin?
Agbegbe Balochistan wa laarin Afghanistan ati Iran to si jẹ agbegbe Pakistan to tobi julọ to n koju ikọlu lọwọ awọn agbebọn ọmọ ogun Tehrik-e Taliban Pakistan (TTP) ati ikọ Islamic State.
Ni ibẹrẹ oṣu yi, o kere tan eeyan mọkanla to fi mọ gbajumọ olori awọn musulumi kan lo farapa ninu ibugbamu lagbegbe yio kanna.
Amọ ikọ TTP ti sọ pe awọn ko lọwọ ninu ikọlu ọjọ Ẹti yi ninu atẹjade kan ti wọn fi sita.
Bẹẹ ni ikọ naa bẹnu atẹ lu ikọlu to waye ni Khyber Pakhtunkhwa ti wọn si ni ''mọsalaṣi, ile ẹkọ, ati awọn ibi tawọn eeyan ba peju si ko si lara ibi taa n ṣe ikọlu si''
Adele Minisita feto iroyin Pakistan sọ loju opo X pe ''bi awọn ẹni ye ṣe lero pe ayajọ ọjọ ibi Anọbi lo tọ lati ṣe ikọlu ti fihan pe wọn ko ni nkankan ṣe pẹlu ẹsin kankan''
Ni Pakistan, ijọba ya ọjọ sọtọ fayẹyẹ ajọdun ọjọ ibi Anọbi Muhammad taa mọ si Maolud Nabbiy ti o maa n waye lọjọ Kejila oṣu Kẹta kalẹnda oju ọrun.
Isinmi lẹnu iṣẹ a maa wa lọjọ yi ti awọn oriṣi ayẹyẹ to fi mọ ikorajọ a si maa waye kaakiri.
Gbogbo awọn onimọ ẹsin Islammu lo fẹ ẹ panupọ tan lori ṣiṣe ajọdun ọjọ yi.
Amọ awọn kan wa to tako ayẹyẹ ti wọn fi sọ ori ọjọ ibi Anọbi.
Awọn yi a maa sọ pe ko si ẹri kankan to fihan pe ṣiṣe ayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi nigba to wa laye ati lawọn ọdun to tẹle iṣipopada rẹ.