Ṣé lọ́ọ̀tọ́ ní Musk tí dá Donald Trump padà sórí òpó Twitter?

Oludari tuntun fun opo Twitter, Elon Muck, ti kede pe awọn yoo gbe igbeṣẹ lati ṣi oju opo Twitter aarẹ ana lorilẹede Amẹrika, Donald Trump pada.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn eniyan ṣe dibo pe ki wọn fi aye gba a pada sori opo naa.

Musk ni awọn eeyan ti sọrọ lẹyin awọn eeyan toto milọnu mẹdogun dibo pe ki Trump pada lẹyin ti wọn fi ofin de lilo opo Twitter fun.

Sugbọn o ṣeeṣe ki aarẹ ana ọhun ma pada sori opo naa lẹyin to kede pe oun ko ri idi kan pato ti oun yoo fi pada si ori opo Twitter.

Wọn fi ofin de opo Twitter Trump lọdun 2021, lẹyin ti awọn alatilẹyin rẹ ṣe ikọlu si US Capitol ni Washington DC lọjọ kẹfa oṣu kinni ọdun 2021.

Keti ti awọn adari Twitter tẹlẹ fi ofin de Trump ni o gbe igbesẹ lati da opo ayelujara tiẹ silẹ, eeyi to pe ni “Truth Social”

Ni ọsẹ to kọja ni aarẹ ana ọhun kede pe oun yoo jade dupo aarẹ orilẹede Amẹrika lọdun 2024.

Musk, ẹni to lowo ju lagbaye gba akoso Twitter ninu oṣu kẹwaa, lẹyin to ra a pẹlu owo toto biliọnu marundinlogiji dọla.