Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí Afcon Round of 16 yóò ṣe lọ

Ipele ẹlẹgbẹjẹgbẹ fun idije AFCON 2023 ti wa sopin bayii lẹyin ti wọn pari gbogbo ifẹsẹwọnsẹ to wa ni isọri naa.

Ọpọlọpọ ohun iyalẹnu lo ti ipele yii jade, paapaa bi awọn orilẹede alagbara ṣe ṣubu niwaju awọn orilẹede kan ti wọn ko fi bẹ lorukọ ti a ba n sọrọ ere boolu.

Lẹyin gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ẹlẹgbẹjẹgbẹ naa, awọn orilẹede kan ni wọn ti fọwọ osi juwe fun, ti awọn mii si ni anfaani lati kopa ninu ipele ẹlẹni mẹrindinlogun nitori atunse tuntun ti ẹgbẹ CAF gbe kalẹ.

Eyi lo fa ti awọn orilẹede kan bi Cote di Ivoire to gba alejo idije naa, Guinea, Mauritania ati Namibia ti wọn gbe ipo kẹta ninu isọri wọn naa fi ni anfaani lati wọ ipele Round of 16.

Awọn orilẹede mẹrin yii ni wọn sapejuwe gẹgẹ bi awọn orilẹede to lulẹ sugbọn ti wọn si gbiyanju.

CAF lo iye ami ti ẹgbẹ agbaboolu gba ni isọri wọn ati bi wọn se fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn kopa.

Awọn orilẹede to de ipele ẹni mẹrindinlogun 'Round of 16' re e

  • Equatorial Guinea
  • Nigeria
  • Cape Verde
  • Egypt
  • Senegal
  • Cameroon
  • Guinea
  • Angola
  • Burkina Faso
  • Mauritania
  • Namibia
  • DR Congo
  • Ivory Coast
  • South Africa
  • Morocco
  • Mali

Awọn esi ati bi Afcon 2023 group stage ṣe lọ

Bi awọn ifẹsẹwọnsẹ Round of 16 yoo ṣe lọ

Ọjọ Abamẹta si ọjọ Iṣẹgun ọsẹ to n bọ ni ipele Afcon Round of 16 yoo bẹeẹ. Orilẹ-ede Naijiria ati Cameroon si ni yoo kọkọ pade.

Ẹ wo eto bii awọn ifẹsẹwọnsẹ yoo ṣe lọ:

Nigeria vs Cameroon - 27 January ni Felix Houphouet Boigny Stadium in Abidjan

Angola vs Namibia - 27 January ni Stade de la paix in Bouake

Equatorial Guinea vs Guinea - 28 January ni Alassane Ouattara Stadium

Egypt vs DR Congo - 28 January ni Laurent Pokou Stadium.

Cape Verde vs Mauritânia - 29 January ni Felix Houphouet Boigny Stadium.

Senegal vs Ivory Coast - 29 January ni Charles Konan Banny Stadium.

Mali vs Burkina Faso - 29 January ni Amadou Gon Coulibaly Stadium.

Morocco vs South Africa - 30 January 30 ni Laurent Pokou Stadium.