You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun tá a mọ̀ nípa akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ Unilorin rèé
Ori ko akẹkọọ kan ni ile ẹkọ giga Fasiti Unilorin yọ lọwọ awọn ajinigbe.
Akẹkọọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Moyosore Bright, jẹ akẹkọọ to wa ni ipele akọkọ ile ẹkọ naa to n kọ ẹkọ nipa awọn ẹranko (zoology).
Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Toun Adeyemi ṣalaye pe lọjọ Ẹti, ọjọ Kérindinlọgbọn ni iṣẹlẹ naa waye.
Adeyemi ni lasiko ti akẹkọọ naa wọ ọkọ korepe lati inu ọgba ile ẹkọ naa lati maa ile igbe rẹ to wa ni agbegbe Tanke.
O ni akẹkọọ ọhun kan deede ba ara rẹ ninu igbo kan to jina si ọgba ile ẹkọ naa nigba to ya.
Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye siwaju si pe ko si apa kankan tabi ohun to jọ pe wọn fiya jẹ ẹ nigba to ba ara rẹ ninu igbo naa.
Amọ ko ba owo to wa lọwọ rẹ iyẹn ẹgbẹrun mẹta naira ati kaadi ATM CARD rẹ nigba to maa fi mọ nnkan to n ṣe pada.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii to loorin lori iṣẹlẹ naa lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ si akẹkọọ naa, ki wọn si le fidi ootọ ohun to ṣee gan mulẹ.
O fi kun pe Kọmisanna ọlọpsa ipinlẹ Kwara, Victor Olaiya rọ awọn eeyan ipinlẹ Kwara lati fọkan balẹ tori ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe ohun gbogbo to yẹ lati pese aabo ẹmi ati dukia fun gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Kwara.
Nigba ti a kan si awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga Unilorin, Agbẹnusọ ile ẹkọ naa Kunle Akogun ni awọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa amọ iwadii ti n lọ lọwọ lori rẹ.
O ni kete ti awọn alaṣẹ ba ti le fidi ohun to ṣẹlẹ lede ni awọn maa fi lede fun gbogbo eniyan.
Unilorin lé akẹ́kọ̀ọ́ kan, Pluto, tó ń fi ìbálòpọ̀ bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wá ‘admission’
Ile ẹkọ fasiti ilu Ilorin, Unilorin, ti fi ikede sita pe awọn ti mu opin ba eto ẹkọ akẹkọọkunrin ile ẹkọ naa kan lori ẹsun fifi ipa ba akẹkọọbinrin kan lo pọ.
Alukoro fasiti naa, Kunle Akogun lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC Yoruba.
Ọgbẹni Akogun sọ pe akẹkọọ naa, Arakunrin Mathew Balogun, ti inagijẹ rẹ n jẹ Plato, ni igbimọ oludari fasiti gbẹjọ lori ẹsun ifipabanilopo ti wọn fi kan an, ti wọn si sọ pe o jẹbi ẹsun naa.
O ṣalaye pe atẹjade igbadegba fasiti naa to jade laipẹ yii ni awọn fi ikede igbesẹ ọhun.
Bi ọrọ ibalopọ ọna aitọ ṣe de'ti igbọ fasiti
Ọrọ ẹsun ifipabanilopọ yii ko ṣẹṣẹ waye, lati ọdun2023 ni wọn ti wa lẹnu rẹ.
Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, ni fasiti fiwe pe Arakunrin Mathew ti ọpọ mọ si Plato pe ko wa yọju si igbimọ iwadii fasiti lati wa wi tẹnu rẹ lori ẹsun ibanilopọ pẹlu awọn akẹkọbinrin kan.
Plato kọ ko yọju siwaju igbimọ naa nigba naa lọhun.
Nigba ti yoo fi pada yọju siwaju igbimọ ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, Plato jẹwọ pe lootọ l'oun jẹbi ẹsun keji ti wọn fi kan an.
Ẹsun naa ni pe o fi ọna ẹburu fi ọbẹ ẹyin jẹ awọn akẹkọbinrin kan niṣu nipa pe o parọ pe oun yoo ranwọn lọwọ lati wọle si fasiti naa.
Koda, o tun sọ pe oun ni agbara lati ba wọn yi esi idanwo lọna ti wọn yoo fi gbawọn wọle si fasiti ti eleyi si tako ilana ile ẹkọ naa.
Lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ni fasiti gbe iwe le lọwọ ti wọn si ni kii ṣe akẹkọọ awọn mọ.
Atẹjade igbadegba ti wọn fi gbe ikede yii sita ni akọkọ iru rẹ ti yoo jade lẹyin igba ti fasiti ti ni ki Plato kọri si ile awọn obi rẹ.
Fasiti ko sọ boya wọn fa akẹkọọ naa le awọn agbofinro lọwọ lati le fiya jẹ ẹ labẹ ofin iwa ọdaran orileede Naijiria.