You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìkọ́ aláàbò dóòlà ọ̀dọ́bìnrin méjìlá tí ajínigbé jí gbé ní Borno
Awọn ọmọ ologun lorilẹede Naijiria, Hadin Kai ti doola ẹmi awọn ọdọmọbinrin mejila ti ikọ Boko Haram/ISWAP ji gbe ni agbegbe Mussa, ni ijọba ibilẹ Askira/Uba nipinlẹ Borno.
Eyi waye ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun fi lede loju opo ayelujara wọn lọgbọn ọjọ oṣu kọkanla ọdun 2025.
"Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ṣe aseyọri lati doola ẹmi awọn ọdọmọbinrin mejila ti agbebọn Boko Haram/ISWAP jigbe ni agbegbe Mussa ni ijọba ibilẹ Askira/Uba nipinlẹ Borno," atẹjade naa ṣalaye.
"Awọn ọdọmọbinrin yii gba ominira ni ọjọ Ṣatide, ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla, lẹyin ti ikọ ologun HADIN KAI kọlu awọn agbebọn ni guusu ipinlẹ Borno".
Ileeṣẹ ologun ni awọn ọdọmọbinrin yii ni wọn tig be wọn lọ sibi ti wọn yoo ti ni anfani si ilera to peye ati ifọrọwanilẹnuwo.
Ọjọ ori awọn ọdọmọbinrin naa lo wa laarin ọmọ ọdun mẹdogun si ẹni ogun ọdun, ti wọn si ji wọn gbe ni ogunjọ oṣu kọkanla nigba ti wọn n ṣiṣẹ lori oko mọlẹbi wọn.
"Lẹyin ti a ba ṣe gbogbp eyi, wọn yoo darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn. Itusilẹ yii ti mu ọkan awọn ara agbegbe naa balẹ, eyi to ti ka soke lati igba ti awọn agbebọn ti ji awọn ọdọmọbinrin naa gbe."
Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe ṣalaye, orukọ awọn ọdọmọbinrin naa ni Fatima Shaibu (17), Fatima Umaru (15), Hauwa Abubakar (18), Saliha Muhammed (15), Sadiya Umaru (17), Amira Babel (15), Zara Adamu (17), Nana Shaibu (15), Zainab Musa (18), Zainab Muhammed (17), Jamila Saidu (15) ati Hauwa Hamidu (17)
Awọn olori ikọ ologun orilẹede Naijiria ti kan sara si ileeṣẹ ologun fun bi wọn ṣe mu iṣẹ lọkunkundun .