Èèyàn tó lé ní 70,000 ni Israel ti pa ní Gaza – Hamas

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ eto ilera Gaza ti Hamsa n ṣakoso rẹ ti sọ pe o le ni ẹgbẹrun lọna aadọrin eeyan ti wọn ti padanu ẹmi wọn lati igba ti Israel ti n kọlu agbegbe naa lọdun 2023.

Amọ iye eeyan eeyan to ku yii lo tunbọ n pọ si lẹyin adehun jogun-o-mi ti wọn tọbọ bọ lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 yii.

Lẹyin adehun naa ni Israel tun n ju ado oloro si Gaza lẹyin to fẹsun kan Hamas pe wọn yẹ adehun ọhun.

Lara awọn to padanu ẹmi wọn lẹyin ado oloro Israel tuntun yii ni awọn ọmọdekunrin meji ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa, Fadi ati Juma Abu Assi, ti awọn obi wọn ni ado oloro naa gbẹmi wọn nibi ti wọn ti n ṣa igi idana.

Ileeṣẹ eto abo Israle, Israel Defense Forces (IDF) sọ fun BBC pe awọn afurasi meji kan ti wọn kọja ala ti ko yẹ ki wọn kọja lawọn fi ado oloro naa ṣọwọ si.

Ala naa jẹ ibi ti Israel fẹnuko si pe awọn ko ni rekọja lasiko adehun naa pẹlu ijọba Amẹrika lọsẹ meje sẹyin.

Ẹgbọn awọn ọmọ to ku naa juwe wọn gẹgẹ bii ọmọ ọdun mẹwaa ati ọmọ ọdun mọkanla.

Awọn alabagbe wọn sọ pe igi idana ni wọn n wa lagbagbe Khan Younis ki wọn to padanu ẹmi wọn.

Wọn ti sin oku awọn ọmọ ọhun nile iwosan Nasser, to wa ni Gaza, lọjọ Abamẹta.

Gbogbo igba ni ileeṣẹ eto ilera Gaza maa n kede awọn to ku ninu ogun naa ti ajọ UN si maa n sọ pe ko si irọ ninu iye eeyan ti wọn kede.

Amọ ṣa, lọpọ igba ni ijọba Israel maa n sọ pe Hamas maa n fi kun iye awọn eeyan naa lati le jẹ ki awọn eeyan wa ni iha tiwọn.

Ẹwẹ, ijọba Israel ko gba awọn akọroyin bii ti BBC laaye lati wọ Gaza funra wọn, fun idi eyii, o ṣoro lati fidi iye eeyan to ku mulẹ.

Ileeṣẹ eto ilera Gaza ni 70,100 eeyan ni Israel ti ṣekupa ti 350 ninu iku naa si waye laarin ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa ti wọn tọwọ bọwe adehun jogun-o-mi.

Ogun aarin awọn mejeji bẹrẹ lẹyin ti Hamas gbẹmi awọn ọmọ Israle lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023.

Ọmọ Israel 1,200 ni Hamas pa lọjọ naa, ti wọn si ko eeyan 251 lẹru.