Àwọn ìgbésẹ̀ tí gómìnà Kwara, Oyo, Eko àti Ekiti gbé láti mú ìdẹ̀rùn bá aráàlú lẹ́yìn àlékún owó bẹntiróòlù

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Láti ìgbà tí àlékún ti tún gorí owó epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà ni àwọn èèyàn ti ń kọminú lórí ìpalára tí àlékún náà yóò tún kó bá ètò ọrọ̀ ajé.

Ṣaájú kí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tó gba ìjọba láti tukọ̀ Nàìjíríà fún ọdún mẹ́rin ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún, ọdún 2024, náírà méjìdínígba ni wọ́n ń ta epo káàkiri Nàìjíríà.

Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n búra wọlé fún-un tán lọ kéde pé kò ní sí ìrànwọ́ lórí epo bẹntiróòlù mọ́ tí owó epo sì gbẹ́nu sókè di N568 sí N617.

Láti ìgbà náà ni ọ̀wọ́n gógó ti ń bá Nàìjíríà fínra táwọn gómìnà ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, tó fi mọ́ ìjọba àpapọ̀ sì ti ń gbé ìgbésẹ̀ kan tàbí òmíràn láti fi mú ìdẹ̀kún bá àwọn ènìyàn.

Ìjọba àpapọ̀ kéde nígbà náà láti máa fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì gẹ́gẹ́ bá àlékún sí owó oṣù wọn kí wọ́n tó fẹnukò pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí iye tí owó oṣù tó kéré jùlọ yóò jẹ́.

Bákan náà ni àwon gómìnà ní ìpínlẹ̀ náà kọ̀ọ̀kan gbá àwọn ètò kalẹ̀ láti fi mú ìdẹ̀kùn bá àwọn èèyàn pàápàá àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba.

Lára irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Kwara àti Ogun kéde láti máa fún àwọn òṣìṣẹ́ ní àlékún ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà kún owó oṣù wọn.

Àmọ́ lọ́jọ́ Kẹta, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2024 ni àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà, NNPCL kéde àlékún tuntun lórí epo bẹntiro, tí owó epo sì lọ sókè di N855 sí N897.

Èyí ló ti ń mú kí àwọn èèyàn máa kọminú lórí ìnira tí àlékún yìí yóò tún mú bá ètò ọrọ̀ ajé, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti ń fi ẹ̀hónú wọn hàn.

Ní ìlú Ilorin, olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara, àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti ọlọ́kadà, lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹsàn-án daṣẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì kọ̀ láti máa gbé èrò nítorí ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiro.

Àwọn ọlọ́kadà àti oníkẹ̀kẹ́ náà sọ fún BBC News Yorùbá pé àwọn ilé epo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ta epo ní ẹgbẹ̀fà sí àádóje náírà ló jẹ́ kí àwọn daṣẹ́ sílẹ̀.

Wọ́n ní tí àwọn bá ti fowó ra epo tán kìí ku nǹkankan sílẹ̀ fún àwọn láti ṣàmúlò ló jẹ́ káwọn pinnu láti má ṣiṣẹ́ láìrò tẹ́lẹ̀ láti fi ẹ̀hónú àwọn han sí ìjọba pé nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ náà kò tẹ́ àwọn lọ́rùn.

Kí ni ìgbésẹ̀ táwọn gómìnà ìpínlẹ̀ ń gbé láti mú ìdẹ̀kùn bá aráàlú

Lẹ́yìn ìwọ́de àwọn ọlọ́kadà àti oníkẹ̀kẹ́ ni Ijọba ipinlẹ Kwara kéde pé awọn ti bẹrẹ si ni pese ọkọ ọfẹ fawọn araalu ni ilu Ilorin ti o jẹ olu ilu ipinlẹ naa.

Igbesẹ yii lo n waye nitori iyansẹlodi tawọn onikẹkẹ ati ọlọkada ṣe lọjọbọ ni ilu Ilọrin.

Iyansẹlodi naa si lo da lori bi epo bẹntiroolu ṣe gbowo lori, tawọn ileepo si n ta jala epo bẹntiro ni ẹgbẹfa naira si aadoje naira.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ gomina Abdulrahman Abdulrasaq, Rafiu Ajakaye ṣe sọ, ijọba gbe awọn ọkọ ọfẹ naa kalẹ lati mu idẹkun ba araalu lasiko ọwọn gogo epo bẹntiroolu ati iyanṣẹlodi tawọn onikẹkẹ ati ọlọkada gunle.

Ajakaye, nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, ni ilu Ilọrin, to jẹ olu ilu fun ipinlẹ Kwara nikan ni eto naa yoo ti maa waye, nitori Ilorin ni ibi ti awọn eniyan pọ si julọ ni ipinlẹ Kwara.

O ṣalaye pe kii ṣe pe awọn ilu to ku to wa ni ipinlẹ Kwara ko ṣe pataki, o ni idi ti awọn fi pese eto naa sinu Ilọrin lasiko yii ko ṣẹyin pe ibẹ ni awọn oriko ileeṣẹ ijọba pọ si julọ ati pe ibẹ ni awọn eeyan ti maa n lọ si ọna to jina julọ.

Rafiu Ajakaye tẹsiwaju pe “Ọpọ awọn ile ẹkọ, ile iṣẹ ijọba àti ti aladani lo pọ ni Ilorin ju awọn agbegbe yooku lọ.”

O sọ pe awọn ọkọ naa yoo wa ni gbagede, awọn ibi to jẹ orikusu tawọn awọn eniyan pọ si ati pe awọn eeyan mọ awọn ibi ti wọn ti maa n wọ awọn ọkọ naa nitori ijọba ko ṣẹṣẹ maa gbe awọn eto yii kalẹ nigba ti inilo ba wa fun.

Nigba to n dahun ibeere lori igba ti eto naa maa fi wa nilẹ da, Ajakaye ni "mi o le sọ pato igba ti ijọba yoo fi ṣe eyi.

Gẹgẹ bi mo ṣe sọ, eto idẹrun ni ijọba n ṣe e lati mu idẹrun ba awọn eniyan ni, paapaa julọ nitori pe o ṣe pataki lasiko ti awọn onikẹkẹ ati awọn ọlọkada daṣẹ silẹ.

Gómìnà Eko, Ekiti pàṣẹ káwọn òṣìṣẹ́ máa ṣiṣẹ́ láti ilé

Ní ìpínlẹ̀ Oyo ẹ̀wẹ̀, gómìnà Seyi Makinde ṣèlérí pé ìgbésẹ̀ tí ìjọba òun yóò bá gbé lórí àlékún tó bá owó epo yóò jẹ́ ìpinnu tí yóò mú ìdẹ̀kùn bá àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà.

Makinde ní bẹ́ẹ̀ náà ni yóò jẹ́ ìpinnu ṣàgbéyẹ̀wò ètò ọrọ̀ ajé dáradára.

Nínú àtẹ̀jáde olóṣooṣù rẹ̀ ni Makinde ti sọ ọ̀rọ̀ náà tó sì ní àwọn ìpinnu kan wà nílẹ̀ tí àwọn nílò ṣe pàápàá lórí ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiro.

Bákan náà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti pàṣẹ fáwọn òṣìṣẹ́ láti máa ṣiṣẹ́ láti ilé fún oṣù mẹ́ta.

Àtẹ̀jáde kan tí olórí òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Eko, Bode Agoro fi léde ní gómìnà pàṣẹ náà láti mú àdínkù bá ìṣòro táwọn òṣìṣẹ́ ń kojú látàrí bí owó epo ṣe tún ti gbówó lórí.

Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní ipele kìíní sí kẹrìnlá ní àǹfàní láti ṣiṣẹ́ nílé fún ọjọ́ méjì, tí wọ́n yóò sì máa lọ síbiṣẹ́ lọ́jọ́ mẹ́ta.

Ó ṣàlàyé pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wà ní ipele kẹẹ̀dógún sí ìkẹtàdínlógún ní àǹfàní láti ṣiṣẹ́ nílé lọ́jọ́ kan tí wọn yóò sì máa lọ ibiṣẹ́ lọ́jọ́ mẹ́rin dípò ọjọ́ márùn-ún.

Láti ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹsàn-án ni ìgbésẹ̀ náà sì ti bẹ̀rẹ̀.

Ní ìpínlẹ̀ Ekiti, gómìnà Biodun Oyebanji náà ti pàṣẹ pé káwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa ṣiṣẹ́ láti ilé fún ìgbà kan ná.

Gómìnà Oyebanji ní ìgbésẹ̀ náà wáyé láti ṣe ìdẹ̀kùn fáwọn aráàlú.

Àtẹ̀jáde tí olùbádámọ̀ràn gómìnà Oyebanji, Yinka Oyebode fi léde, ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní ìpele kìíní sí ìkeje ní ọjọ́ méjì láti fi lọ sí ibiṣẹ́, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ láti ilé fún ọjọ́ mẹ́ta.

Àwọn òṣìṣẹ́ láti ìpele kẹjọ sí ìkejìlá ni wọ́n máa ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ mẹ́ta ní ibi iṣẹ́, ọjọ́ méjì nílé.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìpele kẹtàlá sí ìkẹtádínlógún ni wọ́n máa máa ṣiṣẹ́ nílé fún ọjọ́ kan, tí wan sì gbọ́dọ̀ máa wà ní ibiṣẹ́ fún ọjọ́ mẹ́rin.

Àmọ́ ètò yìí tí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kẹsàn-án, gẹ́gẹ́ bí ìdarí gómìnà, kò kan àwọn olùkọ́, òṣìṣẹ́ ìlera àtàwọn òṣìṣẹ́ ètò ààbò.

Bákan náà ni wọ́n sọ pé oṣù méjì ni ètò yìí máa wà kí wọ́n tó tún ṣe àgbéyèwò rẹ̀.