Kílódé tí Oluwo ilẹ̀ Iwo ń ki Olorì rẹ̀ ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?

Yoruba bọ wọn ni ọrọ ifẹ bi adanwo ni.

Ohun lo difa fun Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Telu kinni to n ki Olori rẹ, Firdaus ni mẹsan an mẹwaa lori ayajọ igbeyawo wọn.

Oluwo ni '' mo ki Olori mi ku oriire ayajọ igbeyawo wa, Olori ti o n tọju Ọba ni.

Ko si igba kan ti o ja mi kulẹ ri, inu mi dun wi pe o wa ninu aye mi lasiko ti mo jẹ ọba yii.

Niṣe ni o maa n fun mi ni okun, o si tun maa n mu ọkan mi le.

Iru Olori bi tiẹ lo yẹ ki gbogbo ọba alaye maa gbadura lati ni, tori mi o mọ bo ya iru Olori bi tiẹ tun wa mọ.''