Emefiele gbé iṣẹ́ àgbàṣe tó lé ní N90m fún aya àti àna rẹ̀ – EFCC

Oṣojumikoro kan ninu ajọ EFCC, Agboro Omorewa, ti sọ niwaju ile ẹjọ giga to n gbọ ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan ọga agba CBN tẹlẹ, Godwin Emefiele, pe o lo ipo rẹ lati gba iṣẹ agbaṣe fun iyawo ati àna rẹ kan.

Omorewa sọ pe Emefiele funra rẹ atawọn mẹwaa mii ni CBN buwọlu iwe iṣẹ naa fun ile iṣẹ April 1616 ati Architekon Nigeria Limited.

O ni afurasi naa lo ipo rẹ gẹgẹ bii ọga agba CBN lati gba iṣẹ ọhun fun Architekon Nigeria Limited nibi ti iyawo ati àna rẹ ti jẹ adari lati gba iṣẹ ti iye owo rẹ jẹ N97.9m.

EFCC ni iṣẹ naa wa fun rira awọn aga ati ohun elo ọọfisi miran fun CBN.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, Emefiele ni ẹni to kẹyin to buwọlu iwe iṣẹ agbaṣẹ ọhun gẹgẹ bii gomina CBN lasiko naa.

O ni “Eeyan mẹwaa lo buwọlu iwe naa, nitori naa ẹnikan ni ẹbi ọrọ naa yoo wa lori rẹ, oun ni ọga agba CBN, ori tabili rẹ si ni aṣẹ to kẹyin wa.”

Nigba ti agbẹjọro Emefiele, Mathew Burkaa (SAN) bere lọwọ oṣiṣẹ EFCC naa boya Emefiele wu iwa naa lati mọọmọ lu owo ijọba ni ponpo, o ni “Rara, idi ti mo fi sọ bẹẹ ni pe awọn mọlẹbi ati ọrẹ rẹ ni a ṣewadii, kii ṣe oun funra rẹ.”

Ṣaaju ninu igbẹjọ na ni Omorewa ti kọkọ sọ pe Emefiele wu iwa ọhun lati kowo jẹ nipa bo ṣe lo ipo rẹ lati gbe iṣẹ agbaṣe naa fun Architekon Nigeria Limited ati April 1616.

O fi kun pe orukọ baba iyawo Emefiele lo fi silẹ lasiko to n ṣe iforukọsilẹ ileeṣẹ naa.

O sọ siwaju si pe orukọ oṣiṣẹ CBN kan, Sa`adatu Yaro, wa ni akọsilẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn adari ileeṣẹ ọhun.

Omorewa ṣalaye pe ileeṣẹ iyawo Emefiele ọhun gba oniruru iṣẹ agbaṣe ti lara rẹ jẹ pipese ọkọ Hilux marundinlaadọta ti iye owo rẹ jẹ laarin N854,700,000 si N99,900,000.

Ẹwẹ, adajọ Hamza Muazu to n gbọ ẹjọ ọhun ti wa sun un si ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ti a wa yii.