Àgbàrá òjò gbé èèyàn 150 lọ, 51,000 míì di aláìnílélórí

O kere tan, eeyan marundinlọgọjọ (150) lo ti jade laye ni Tanzania latari iṣẹlẹ omiyale ati ilẹ riri to waye nibẹ.

Ijọba orilẹede naa sọ pe iṣẹlẹ ọhun waye lẹyin ojo arọrọda El Niño kan.

Olootu ijọba, Kassim Majaliwa ti kilọ pe o ṣeeṣe ki ojo naa tẹsiwaju titi wọ inu oṣu Karun un, nitori naa, ki aawọn araalu ko ẹbi wọn kuro lagbagbe ti omiyale yoo ti waye.

“Ojo El Niño, to fi mọ iji lile, agbara ojo ati ilẹ riri ti da wahala nla silẹ kaakiri orilẹede yii."

Nnkan bii 200,000 eeyan ati ile gbigbe to le ni 51,000 ni iṣẹlẹ naa pa lara.

Yatọ si Tanzania, ojo arọrọda tun ti ṣọṣẹ ni Kenya ti Burundi.

Nigba to n jabọ fun ile aṣofin orilẹede naa,ọgbẹni Majaliwa sọ pe yatọ si awọn 155 eeyan to ku, 236 mii tun farapa.

O ni “Ojo El Niño, to fi mọ iji lile, agbara ojo ati ilẹ riri ti da wahala nla silẹ kaakiri orilẹede yii.

“Eyii ko yọ ọpọ ẹmi to sọnu, ere oko to bajẹ, ile ati duki araalu ti ojo gbe lọ, oju popo, awọn afara ati oju ọna irin ti agbara gbe lọ.

Olugbe agbegbe Siha ni ariwa ilẹ naa ṣo fun BBC pe ile oun ti dawo, oun si ti wa ni korofo bayii.

O ni “Mi o ni nnkankan mọ, gbogbo rẹ ni omi ti gbe lọ.

Ni Kenya, Aarẹ orilẹ-ede naa ti paṣẹ fun awọn ologun lati ṣeranwọ fun awọn adoola ẹmi.

O kere tan, eeyan mẹwaa ni omi gbe lọ, ti apapọ awọn to ti ku si jẹ awọn marindinlaadọta bayii.

Ni Burundi, o le ni 100,000 eeyan ti omiyale ti sọ alairilegbe.