You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀kọ́ èdè Yoruba àkọ́kọ́ lágbàyé Omotayo Olutoye jáde láyé, ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé
Ọjọgbọn Omotayo Olutoye, to jẹ iyawo Ọba Alaani ti ilu Idoani, ni ijọba ibilẹ Ose, nipinlẹ Ondo ,ti jade laye.
Ninu atẹjade kan ti alaga ijọba ibilẹ Ose, Dennis Adekunle fi lede lo ti kede iku oloogbe naa.
O ni adanu nla ni iku Ọjọgbọn naa jẹ fun oun ati gbogbo ọmọ bibi ilu Idoani, nipinlẹ Ondo.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Ọjọgbọn Omotayo Olutoye ree
Ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1935 ni wọn bi mama Omotayo Olutoye.
O kẹkọọ nile ẹkọ Queens College, niluu Eko ati St Agnes's College, to wa ni Maryland, Ikeja, niluu Eko.
Lẹyin naa o lọ si University College, Ibadan laarin ọdun 1960 si 1961, lati ibẹ lọ, o tẹkọ leti lọ si University of Lagos, ni 1967-70.
Lẹyin naa lo lọ si fasiti Leeds, nilẹ Gẹẹsi.
O ṣiṣẹ nileeṣẹ redio ati lawọn fasiti kaakiri.
Oun ni Ọjọgbọn nipa ẹkọ ede Yoruba akọkọ ni gbogbo agbaye.
Oloogbe naa ni iya to bi dokita to fi iṣẹ abẹ gbe ọmọ kuro ninu alaboyun lati ṣiṣẹ abẹ fun un, to si tun da ọmọ naa pada sinu iya rẹ lai si wahala kankan, iyẹn Olurotimi Olutoye.
Ṣaaju iku rẹ, oun ni Yeyeluwa ilu Idoani.
Yeyeluwa Idoani ọhun jẹ olufọkansin ninu ijọ Anglican ko to fi aye silẹ.
Awọn ọmo, ọmọ-ọmọ atawọn ọmọ-ọmọ-ọmọ lo gbẹyin oloogbe ọhun.