You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa ọdún Ifa ìlú Shao rí?
Ìlú Shao jẹ ìlú kan gbòógì ní ìjọba ìbílẹ̀ Moro ní Ìpínlẹ̀ Kwara, kódà ìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Shao jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí wọ́n kọkọ tẹ̀dó ní ìpínlẹ̀ ọhun.
Ní ilẹ̀ Yorùbá, a kò leè kò'yan Shao kéré tí a bá ń sọ nípa ẹ̀sìn ìbílè, bí ó tilè jẹ́ wí pé àwọn ọmọ lẹ́yìn Kristi àti Mùsùlùmí náà ò gbẹ̀yín ní ìlú náà.
Ẹ̀ka ẹ̀sìn ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà tí wọ́n maa n gbà fi ayẹyẹ sọrí ọdún tí èyí kò yàtọ̀ lọ́dọ̀ àwòn Babaláwo.
Ọdún Ifá ni ọ̀nà tí àwọn onífá fi ń ṣe ayẹyẹ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Aṣẹ̀dá, èyí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí Ọ̀rúnmìlà gbé kalẹ̀ láti ìgbà ìwáṣẹ̀.
Bí àwọn Babaláwo ṣe máa n ṣọdún ọdún Ifá káàkiri àgbáyé ni àwọn Onífá ní ìlu Shàó náà ń se ayẹyẹ ọdún láti fi ṣe ìdúpẹ́ àti láti fi bèrè fún àánú láti ọ̀dọ̀ Aṣẹ̀dá.
Ọdún Ifá ìlú Shàó yóò ti ọdun yii bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹéẹdógún títí di ọjọ́ kéjìlélógún.
Oríṣiríṣi eré ìbílẹ̀ àti àwọn ètò lọ́kan-ò-jọ̀kan ló má a wáyé níbi ọdún ọhun tí èyí kò sì ní gbẹ́yìn níbi ti ọdún yìí.
Lára àwọn ètò máa wáyé níbẹ̀ ni ìbọ Eṣù, ọdún Yemọja àti Ajé, ìbọ Osun, ayẹyẹ Sango àti Oya, àyàjọ́ Ifa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.