Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano ṣe ìgbéyàwó ńlá fún tọkọtaya 1,800

Ijọba ipinlẹ Kano ṣe kokari igbeyawo nla fun tọkọtaya to o dín diẹ ninu ẹgbẹrun meji kaakiri ijoba ibilẹ mẹrinlelogoji to wa nipinlẹ naa

Igbeyawo ọhun ni wọn pe orukọ rẹ 'Fatihah lo waye ni aafin Emir ti ilu Kano, Alhaji Aminu Bayero lọjọ Ẹti ati Satide.

Pupọ awọn tọkọtaya naa lo jẹ ọdọ, opo ati adelebọ.

Awọn eeyan jankanjakan to wa ni ayẹyẹ naa ni Gomina Ipinlẹ ipinlẹ Kano, Abba Yusuf, Olori ẹgbẹ Kwankwasiyya, Rabiu Kwankwaso, osisẹ ijọba ati awọn olori ẹṣin.

Madakin ti ilu Kano, Yusuf Nabahani lo soju Emir ti Ilu Kano.

Gomina Yusuf salaye pe sise igbeyawo yii lo wa ni ilana pẹlu asa ati ise, eyi ti yoo tun fun awọn tọkọtaya ni anfani lati se ayẹyẹ lia na owo to pọ, ti wọn yoo si bẹrẹ irinajo ifẹ pẹlu idunnu ọkan.

O tẹsiwaju pe igbeyawo naa ko ki ṣe lati so tọkọtaya pọ nikan sugbọn lati se iranlọwọ fun awọn araalu lati se ayẹyẹ nla fun igbeyawo wọn.

"Ayẹyẹ yii safihan asa,ise ati ifẹ to wa laarin awọn olugbe ipinlẹ Kano, ti ìjọba yoo si ri pe wọn da bobo lati pese ọjọ iwaju to da fun awọn olugbe ipinlẹ naa."