'Ọlọ́pàá yìnbọn pa àbúrò mi láti 2017, ọpẹ́lọpẹ́ ìwọ́de Endsars'

'Ọjọ ẹti Ọjọ kẹrindinlogbon Oṣu kẹfa ọdun 2017, nigbati ẹgbọn mi Emmanuel Ephraim de lati ile ijọsin'.

Ephraim to wọle ni dede aago meje irolẹ ni aburo rẹ ni o jade lati ra nkan ni iwaju ile wọn amọ ṣaadede lawọn gbọ ohun ibọn.

"Ago mẹwa ale ni awọn ara adugbo sọ fun wa pe ẹgbọn mi Ephraim ni awọn ọlọpaa yibon ba".

Nigbati o ba ikọ BBC sọrọ, Paul Ephraim ṣalaye pe Ephraim Emmanuel jẹ ẹni ọdun marundinlogoji nigbati iṣẹlẹ naa waye ti ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa ọdaran (SARS) nilu Calabar pa a ni tosii ile wọn.

Awọn ti iṣẹlẹ na ṣoju ṣalaye pe lẹyin ti wọn yibon fun Emmanuel, ile isẹ ọlọpaa Atakpa ni wọn gbe e lọ.

Paul ṣalaye pe ilakaka lati ri Emmanuel lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye lo jasi pabo, ko to di wi pe awọn ọlọpaa gbe oku rẹ fun wọn ni ọjọ keji, pẹlu ẹsun wipe adigunjale ni.

Ìwádìí mọ̀lẹ́bí Emmanuel

Akitiyan ẹbi lati mọ iku to pa Emmanuel ja si pabo, lẹyin igbati ileṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Cross River kọkọ fesi si iwe ipẹjọ ti idile kọ lati mọ okunfa iku to pa Emmanuel.

Kọmisọna Ọlọpaa ipinlẹ Cross River nigba naa ko fi oku Emmanuel silẹ titi ti idile fi kọ iwe ẹbi lati yọnda oku Emmanuel fun ẹbi rẹ.

Paul ṣalaye pe Emmanuel ni àkọbi ninu idile ti oun si tẹlẹ e, o ni lati igba ti iṣẹlẹ naa ti sẹlẹ ni iya awọn ti ni aisan ẹjẹ riru ti baba awọn kosi ni alafia taara lẹyin iku Emmanuel.

Kí wá ni àbájáde ìwádìí Ìgbìmò Ajàfẹtọọ Ọmọniyan?

Ijọba apapọ orilede nigeria ni ọjọ kẹrinla osu kẹsan-an odun yii, fun awọn idile mẹrinlelaadọrun ni owo gba mabinu latari isẹlẹ to ti ọwọ ikọ ọlọpaa orilẹ-ede yii wa.

Emmanuel ni abode iwadii ohun fihan pe awọn ọlọpaa yinbo mọ ẹgbọn oun lẹẹmẹta.

O ni bo tilẹ jẹ pe aṣoju ikọ ọlọpaa ko yọju sibi igbẹjo ti ikọ ajafeto Ọmọniyan gbe kalẹ, ohun ti idile Emmanuel beere fun ni idajọ otitọ .

'Ọ̀pẹ́lọpẹ́ ìwọ́de EndSars'

Iwode EndSars to waye lọdun 2020 lo fun idile Emmanuel ni anfani lati ṣalaye bi ikọ ọlọpaa se sekupa Ephraim, Paul ni ikọ iwadi ajafeto Ọmọniyan ti ijọba apapọ gbe kale san owo itaran fun idile Emmanuel.

Aburo oloogbe naa ni milionu marun naira ti ijọba apapọ fun idile Emmanuel ko le ra ẹmi ẹniti oti ku pada, o wa rọ ajọ to moju to eto ara ilu ati ijọba apapọ lati rii daju pe o lo esi abajade iwadi ajọ ajafẹtọ ọmọniyan nipa iṣẹlẹ ti o yọri si EndSars lọdun 2020.

Oni sisan ọwọ itaran ko to, ijọba apapọ gbọdọ fiyaje awọn ọlọpaa ati awọn oga ọlọpaa to jẹbi ẹsun ipaniyan lọna ti ko tọ.