You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ si nípa Adájọ 5 tí yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀hónú ìbò ààrẹ
Ileẹjọ to n gbọ awuyewuye lori esi ibo aarẹ yoo gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ kẹfa oṣu kẹsan an.
Ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peoples Democratic Party ati Allied Peoples Movement pẹlu awọn oludije wọn wọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ati Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu lọ si ileẹjọ, ti wọn si n sọ pe ki ileẹjọ wọgile ibo to gbe Aare Bola Tinubu wọle gẹgẹ bi Aarẹ.
Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP sọ fun ileẹjọ pe ọna eburu ni Tinubu fi bori eto idibo ati ko yẹ ni ẹni to yẹ ko jade dibo.
Ọjọ kinni, oṣu kẹta ni wọn kede Tinubu gẹgẹ ẹni to bori eto idibo Aarẹ to waye lọjọ kẹdọgbọn oṣu keji.
Nibi esi ti ajọ eleto idibo kede, Tinubu ni apapọ ibo 8,794,726, Atiku gbe ipo keji pẹlu apapọ ibo 6,984,520, ti Peter Obi to wa ni ipo kẹta ni 6, 101, 533, nigba ti Rabiu Kwankwaso ti ẹgbẹ oṣelu NNPC ni 1,496,697.
Igbimọ onidajọ marun un lo bẹrẹ ilewaju gbigbọ awuyewuye esi ibo aarẹ niluu Abuja lati oṣu karun un.
Sugbọn awọn wo ni awọn Adajọ marun un ti yoo gbe idajọ ti ọpọ awọn ọmọ orílẹ̀èdè Naijiria n reti yii kalẹ?
Mọ nipa awọn adajọ yii
Adajọ Haruna Simon Tsammani
Adajọ Haruna Simon Tsammani lo lewaju awọn igbimọ ẹlẹni marun un to n gbọ awuyewuye lori esi idibo aarẹ ni ileẹjọ.
Wọn bi adajọ Tsammani lọjọ kẹtalelọgbọn oṣu kọkanla ọdun 1959, o wa lati ijọba ibilẹ Tafawa Balewa nipinlẹ Bauchi.
Adajọ Tsammani lo gbe idajọ to fi idi idibo si sipo ẹlẹkeji Gomina Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi mọlẹ.
Ipo kọkanla ni Adajọ Tsammani wa ipele awọn adajọ ni ile kotẹmilọrun lorilẹede Naijiria.
Adajọ Stephen Jonah Adah
Wọn bi Adajọ Stephen Jonah Adah lọjọ kẹtala oṣu kẹfa ọdun 1957, to si wa lati ijọba ibilẹ Dekina nipinlẹ Kogi.
Oun ni adajọ keji ti ipo rẹ ga ninu awọn adajọ ti yo gbe idajọ kalẹ.
Ipo kọkanlelogun ni Adajọ Adah wa ipele awọn adajọ ni ile kotẹmilọrun lorilẹede Naijiria.
Lọdun 2012, oun Adajọ to wọgile ofin to ni ọlọpaa obinrin gbọdọ gba asẹ lọwọ kọmisọna ọlọpaa ko to le fẹ ẹni to ba wu u lati fẹ gẹgẹ bi ọkọ.
O kawe gba oye ni fasiti Ahmadu Bello, Zaria lọdun 1981, to ai tun morile Ile ẹkọ awọn Agbẹjọro lọdun 1982.
Idajọ rẹ lo tako igbesẹ Aarẹ Goodluck Jonathan lati yi orukọ fasiti ipinlẹ ẹkọ Moshood Abiola lọjọ kẹdọgbọn ọdun 2012.
Adajọ Mistura Bolaji-Yusuf
Adajọ Mistura Bolaji-Yusuf wa lati ijọba ibilẹ iwọ oorun Oyo nipinlẹ Oyo. Wọn bi I ni ọjọ keje, oṣu kẹjọ ọdun 1959.
Adajọ Bolaji-Yusuf jẹ obinrin kan ṣoṣo to wa lara igbimọ Adajọ ti yoo gbe idajọ kalẹ .
Fasiti Obafemi Awolowo lo ti kawe gba oye.
Ipo kejidinlọgbọn ni Adajọ Bolaji-Yusuf wa ni ipele awọn adajọ ni ile ẹjọ́ kotẹmilọrun lorilẹede Naijiria.
Adajọ Boloukuoromo Moses Ugo
Adajọ Boloukuoromo Moses Ugo ni adajọ agba fun ileẹjọ kotẹmilọrun ti ipinlẹ Kano.
Saaju ni iroyin ofege kan jade pe o kọwe fipo kuro lara awọn igbimọ onidajọ lori ọrọ eto idibo aarẹ.
Ẹni ọdun mẹtadinlọgọta yii lo wa lati ijọba ibilẹ Kolokum/Opokuma nipinlẹ Bayelsa.
Oun lo kere ju lọjọ ori ninu awọn igbimọ adajọ naa.
O pari ẹkọ rẹ ni fasiti Calabar, to si lọ si ilẹ ẹkọ awọn agbẹjọro lọdun 1990.
Ipo kọkanlelogoji lo wa ni ipele awọn adajọ ileẹjọ kotẹmilọrun lorilẹede Naijira.
Adajọ Abba Bello Mohammed
Adajọ Abba Bello Mohammed wa lati ipinlẹ Kano. Wọn bi i lọjọ kọkandinlogun lọdun 1961.
O lọ ile ẹkọ awọn agbẹjọro lọdun 1984, to si wa ni ipo kejidinlaadọrun awọn adajọ ileẹjọ kotẹmilọrun lorilẹede Naijira.
Wọn yan án gẹgẹ bi adajọ olu ilu Abuja lọdun 2010.
Oun ni alaga fun igbimọ to gbọ awuyewuye lori eto idibo gomina nipinlẹ Nasarawa lọdun 2019.