Ààrá pẹ̀lú mọ̀nà-mọ́ná pa ọmọdé mẹ́tàlá nílé ìjọsìn

Oríṣun àwòrán, BBC Weather Watcher Ian
Ko din ni ọmọde mẹtala, ati agbalagba kan, ti mọna-mọna pa nibudo ogunlende kan ni Uganda.
Ibudo naa ti wọn n pe ni Palabek, ni eeyan to le ni ẹgberun lọna ọgọrin, wa.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe lasiko ti awọn oloogbe naa wa nibi ijọsin ni sọọṣi ni irọlẹ ọjọ Abamẹta, ni mọna-mọna san loju ofurufu.
Eeyan mẹrinlelọgbọn mii lo tun farapa.
Lati asiko diẹ seyin ni ojo lile, àrá ati mọna-mọna, ti n waye ni agbegbe ọhun to wa ni Ariwa iwọ-oorun orile-ede Uganda.
Kituuma Rusoke, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, sọ fun BBC pe ẹni ọdun mọkanlelogun ni agbalagba to wa lara awọn to ku.
Amọ Ọgbẹni Rusoke ko sọ pato ọjọ ori àwọn ọmọde to ku.
Gẹgẹ bi àjọ United Nations ṣe sọ, awọn ti ko nile lori, ati awọn àtìpó, ni awọn to le ni 80,000 to n gbe ni ibudo ifiniwọ Palatek Refugee Settlement. Pupọ lara wọn si lo wa lati orile-ede South Sudan to jẹ alamuleti Uganda.
Lọdun mẹrin sẹyin, ọmọde mẹwaa ni mọna-mọna pa niluu Arua, ni ẹkun Ariwa-iwọ oorun Uganda.
Nibi ti awọn ọmọ naa ti n sinmi lẹyin ere bọọlu ni mọna-mọna kọlu wọn.












