You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ báyìí tí Iléeṣẹ́ ìfọpo Port Harcourt lórílẹ̀èdè Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́?
Ileeṣẹ ifọpo orilẹede NAijiria to wa ni ilu Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers ti bẹrẹ si ni fọ epọ epo rọbi pada.
Agbẹnusọ NNPCL, Femi Soneye lo kede igbesẹ yii, to ṣapejuwe rẹ gẹgẹ aṣeyọri nla.
“Oni jẹ ọjọ aṣeyọri fun orilẹede Naijiria bi ileeṣẹ ifọpo Port Harcourt se ti bẹrẹ iṣẹ ifọpo. Aṣeyọri ni yoo fi itan balẹ lorilẹede Naijiria, ti yoo si se anfani pupọ fun ilọsiwaju eto ọrọ Aje.”
“Mo ki Aarẹ Bola Tinubu ku orire,m alaga NNPC, Mele Kyari fun aṣeyọri nla yii. Ni apapọ, a n mu ayipada rere ba ọjọ orilẹede Naijiria ni ẹka epo rọbi.”
Soneye ni awọn ọkọ nla yoo ma wọle si ileeṣẹ na bẹrẹ lati ọjọ Isẹgun, to si jẹ ko di mimọ ileeṣẹ NNPC n sisẹ karakara lori ifilọlẹ ileeṣẹ ifọpo to wa niluu Warri.
Bakan naa ni NNPC kede loju opo X pe wọn ti bẹrẹ sini ma gbe epo jade bẹrẹ lati ago meji ku isẹju mẹdogun lojọ Isẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2024.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ileeṣẹ ifọpo yoo bẹrẹ si ni lati ma ta epo to to ẹgbẹrun lọna ọgọta barẹli lojojumọ.
Ileeṣẹ ifọpo portharcourt ni ileeṣẹ ifọpo keji to n pese epo lẹyin ileeṣẹ ifọpo Dangote.
O jẹ ọkan ninu ileeṣẹ ifọpo mẹta to jẹ ti orilẹede Naijiria ti NNPC n mujuto.