Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ẹni ọdun ba laye o yẹ ko ṣọpẹ, Barika de Sallah ẹ ku ọdun
Bẹẹ ni, lonii lawọn musulumi kaakiri agbaye n yayọ ọdun Ileya
Aarẹ Bola Tinubu rọ awọn musulumi ninu ọrọ ikini ku ọdun rẹ pe
Ki wọn ma sọ ireti nu, bo tilẹ jẹ pe oniruuru iṣoro lo n kọju Naijira lọwọ yii
'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''
Ijọba orilẹede Tanzania ti fofin de lilo oju opo ayelujara X, tawọn eeyan mọ si Twitter tẹlẹ
Ki nidi abajọ igbesẹ ijọba yii?
Wọn ni oju opo naa n faye silẹ fawọn to n lo o lati maa pin aworan ati fidio ibalopọ
Minisita fun eto iroyin lorilẹede naa Jerry Silaa sọ pe eleyii tako ofin, aṣa ati iṣe orilẹede Tanzania
Ẹkunrẹrẹ iroyin ọhun wa lori ikanni BBC Yoruba
''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''
Ireti awọn obinrin kan lati d'ọlọmọ laye ja ṣofo
Lẹyin tawọn ologun ba ọpọlọpọ ọlẹ ọmọ jẹ ni Gaza
Oludari ile iwosan Al-Basma ni Gaza sọ pe
o le ni ọgọrun un obinrin to ti padanu anfani lati di ọlọmọ laye latari ikọlu awọn ọmogu Israel


