Iran dènà àmúlò àwọn ojú òpò ayélujára torí ìwọ́de, ariwo sọ

Awọn ajijagbara ti n kọminu lori bi ijọba orilẹede Iran se dena lilo oju opo ayelujara lorilẹede naa.

Igbesẹ naa lo waye lasiko tawọn obinrin gun le iwọde alagbara lati tako lilo Hijab ni tipa tipa eyi to ti wọ ọjọ keje bayii.

Iwọde naa lo waye nitori bi obinrin kan se ku si ahamọ ọlọpaa lori ẹsun pe o tapa si ofin to nii se pẹlu lilo Hijab.

Ẹgbẹ NetBlocks, to wa fun sise agbeyẹwo amulo oju opo ayelujara, ni awọn oju opo Instagram ati WhatsApp – tii se oju opo ayelujara meji tawọn eeyan Iran ti maa n kan sira wọn, eyi tijọba Iran fọwọsi, ni wọn tun ti gbegi dina amulo rẹ bayii.

Amọ ileesẹ WhatsApp ni oun ti n sisẹ kara lati ri daju pe awọn eeyan orilẹede Iran n ri oju opo naa lo.

Aimọye miliọnu awọn eeyan lo n lo oju opo mejeeji ọhun to jẹ tilleesẹ Meta, tawọn eeyan si tẹwọ gba nigba tijọba fi ofin de amulo awọn oju opo ayelujara yoku lọdun diẹ sẹyin.

Wọn ti yọ awọn orilẹede Iran kuro lawọn oju opo ayelujara naa

Lara awọn oju opo ayelujara tijọba Iran fi ofin de ni Facebook ati Twitter, Telegram, YouTube ati TikTok.

Ẹgbẹ NetBlocks ni lootọ ni wọn da oju opo ayelujara pada silẹ Iran lọjọbọ amọ nigba ti yoo fi di ọjọ Ẹti, o tun ti nira lati so ayelujara pọ mọ orilẹede naa.

"Wọn ti yọ awọn orilẹede Iran kuro lawọn oju opo ayelujara naa”

Ọga agba to n dari oju opo Instagram,Oloye Adam Mosseri lo kede bẹẹ loju opo ayelujara.

O tun fikun pe "A lero pe wọn yoo tete da ẹtọ awọn eeyan ilẹ Iran lati lo awọn oju opo ayelujara pada ni kiakia”

Amọ awọn eeyan miran n fi ẹsun kan ileesẹ Meta pe o lọwọ ninu bi wọn se yọ awọn eeyan ilẹ Iran sẹyin lati lo oju opo ayelujara.

Ààrẹ Iran kọ láti yọjú sí Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú akọ̀ròyìn CNN nítorí ko lo ìbòrí

Gbajugbaja akọroyin CNN, Christiane Amanpour ti wọgile ifọrọwerọ pẹlu Aarẹ orilẹede Iran, Ebrahim Raisi.

Raisi lo sọ fun CNN nibi ipade ajọ isọkan agbaye to waye ni Amẹrika pe oun ko ni kopa ninu ifọrọwerọ naa nitori pe Amanpour ko bo ori rẹ.

Amanpour ni awọn aarẹ tẹlẹ lorilẹede Iran, ko beere fun nnkan ri nigba ti oun ba wọn sọrọ nipa orilẹede Iran.

O ni agbẹnusọ Raisi sọ fun oun pe, idi ti Aarẹ fi gbe igbesẹ naa ni nitori rogbodiayan to n lọ lọwọ lorilẹede naa.

Awọn obinrin Iran lo gunle iwọde naa lẹyin ti obinrin kan padanu ẹmi rẹ nitori pe o tapa si ofin lilo ’Hijab’.

Isẹlẹ naa si lo fa bi awọn obinrin se gunle ifẹhonuhan.

Mahsa Amini, ẹni ọdun mejidinlogun ni awọn ọlọpa fi ẹsun kan pe o tapa si ofin to de lilo ibori naa.

Iroyin ni awọn ọlọpaa lu obinrinn naa titi o fi bọ si ẹsẹkan aye ẹsẹkan ọrun, to si pada padanu ẹmi rẹ ni ile wosan lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.

Awọn ọlọpaa ni awọn ko fi iya jẹ obinrin naa ati pe o kan sadede ni ijakulẹ ọkan rẹ.

Mọlẹbi Amina ni ilera rẹ wa ni alaafia ki isẹlẹ naa to waye, ti ko si nkan to mu rara.

Nibayi eeyan mẹtadinlogun lo ti padanu ẹmi wọn ninu laasigbo iwọde nipa lilo ibori naa.

Ifọrọwerọ naa lo jẹ akọkọ fun Aarẹ Raisi to wa ni lorilẹede Amẹrika, lẹyin to pari ijokoo ajọ isọkan agbaye niluu New York.

Kí ní Christiane Amanpour sọ pé ó ṣẹlẹ̀

Nigba to n salaye ohun to waye laarin rẹ ati aarẹ Iran, gbajugbaja akọroyin CNN Christiane Amanpour ni oun setan lati bẹrẹ ifọrọwerọ naa, nigba ti ọkan lara awọn agbẹnusọ Aarẹ sọ fun oun pe ki oun lo bori oun.

“Ilu New York la wa, nibi to ti sọ ofin to dirọ mọ lilo bibo ori,” o sọ eleyi lori opo ayelujara Twitter.

O tẹsiwaju pe Aarẹ Raisi jẹ ko pe oun pe ifọrọwerọ naa ko ni waye ti oun ko ba fi nkan bori oun gẹgẹ bi oun apọnle.

Amọ o ni oun pẹlu awọn yooku oun ko da wọn lohun.

Ọdun to kọja ni wọn yan Aarẹ Raisi gẹgẹ bi aarẹ, to si buwọlu awọn ofin tuntun ninu oṣu kẹjọ.

Lara awọn ofin tuntun naa ni pe o pese ẹrọ ayaworan lati ma sọ awọn obinrin kaakiri, ti wọn yoo si mu ẹnikẹni ti ko ba fi nkan bori rẹ.

Ijiya wa fun ẹnikẹni ti wọn kba ẹfin pe o tapa si ofin lilo ibori naa.

Eyi lo fa idi tawọn obinrin lorilẹede naa fi bẹrẹ ifẹhonuhan lẹyin iku Mahsa Amini.