You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
''Ohun tí ojú mí rí rèé lẹ́nu ìrínàjò lọ sí Yúróòpù''
Ọmọ Naijiria kan, Ike Nnaebue ti sọ iriri rẹ nigba to gbiyanju lati rin irinajo lọ si ilẹ Yuroopu.
Ike Anaebue ni oun gbiyanju ni nkan bi ọdun mẹrindinlọgbọn ṣẹyin pẹlu awọn ọrẹ oun mẹta.
O ni awọn tẹ ọkọ leti lọ si ilu Benin lati rin irinajo lọ si oke okun.
''Erongba wa ni lati sọda lati ila oorun Ilẹ Afrika lọ si Togo, Burkina Faso, Mali ati Mauritania to fi mọ Morocco.''
''Nibẹ la gba de Yuroopu paapaa Spain, nibi ti wọn ti sọ fun wa pe ẹnikẹni to ba fẹ ṣe iṣẹ, yoo ri iṣẹ ṣe.''
''Ohun ti wọn sọ fun wa ni pe ẹnikẹni to ba wa iṣẹ yoo ri iṣẹ, emi si fẹ ṣiṣẹ''
''A ni lati mu orukọ miran yatọ si orukọ wa, Junior ni mo n jẹ''
Eze ni ọpọlọpọ awọn to n rin irinajo yii ni wọn ma n yi orukọ wọn pada, ki wọn ba le ri ọrọ sọ, ti awọn eniyan ba beere ni ọwọ wọn.
Eze ni Junior ni orukọ ti oun yan laayo nitori awọn ko le ṣẹẹṣẹ ma a ṣalaye ara awọn fun awọn eniyan.
Ọkan lara awọn to ba Eze sọrọ ninu fidio naa ni James ni orukọ oun ati wi pe oun fẹ igbe aye irọrun ni oun ṣe fẹ rin irinajọ lọ si ilẹ miran.
Ọpọlọpọ nkan lo ma n ṣẹlẹ si wọn ni oju ọna, igba miran wọn ma n na wọn, ti wọn ma n ja wọn lole tabi ki wọn tilẹ ta ẹya ara wọn.
''A rin irin ọjọ kan lati Mali de Morocco lọna ati de Yuroopu''
Bakan naa ni awọn obinrin sọ iriri wọn bi wọn ṣe ma n fi ipa ba wọn lọpọ ti wọn ba n rin irinajo wọn lọ si ilẹ Yuroopu.
Obinrin to sọ iriri rẹ ni awọn eniyan fẹ lati pada si ile amọ itiju ni kii jẹ ki wọn pada.
O ni ti awọn miran a si ma tọrọ lati jẹun, tabi fi ko owo jọ lati ra ọkọ oju omi ti yoo gbe wọn lọ si ilẹ Yuroopu.
''Ọjọ kan la fi rin irinajo de Morocco amọ aja awọn ọlọpaa bẹrẹ si ni le wa.''
''A kọkọ fẹ salọ, amọ a duro nitori ki aja naa ma ba bu wa jẹ titi awọn ọlọpaa fi de ibẹ.''
''Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa naa da wa pada lọ si ile.
Bi o tilẹ jẹ pe Eze pada si Ile lẹyin to kọ ẹkọ imọ nipa gbejade sinima ni Gambia, ọpọlọpọ awọn eniyan ni ko pada de ile mọ.