‘’Ọ̀rọ̀ Rauf Olaniyan ti wọ́n yọ ní ipò igbákejì gomina ìpínlẹ̀ Ọyọ dàbí ọ̀rọ̀ awakọ̀ méjì tó fẹ́ wa ọkọ̀ kan’’

Onimọ nipa eto oṣelu, Festus Adedayo ti ṣalaye pe ọrọ oṣelu lo fa yiyọ Rauf Olaniyan nipo gẹgẹ bi igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, ti wọn si fi ẹlomiran rọpọ rẹ.

Adebayo sọ eyi lasiko to n sọ ohun to mọ nipa iyọnipo igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ to waye laipẹ yii.

Ẹsun iwa ibajẹ ni wọn fi kan igbakeji gpomina ti wọn yọ nipo naa, ti wọn si ti bura wọle fun ẹlomiran gẹgẹ bi igbakeji gomina, Seyi Makinde.

Onimọ nipa eto oṣelu naa ni ohun to waye nipe gomina Seyi Makinde ati Rauf Olaniyan ni ifẹ si titukọ ijọba ipinlẹ Ọyọ, eleyii to ni o mu ki wọn kọlu ara wọn.

‘’Ẹgbẹ oṣelu ADC ati PDP ti wọn jọ ni adehun lo mu ki gomina Seyi Makinde mu Rauf gẹgẹ bi igbakeji rẹ, ẹni ti oun dije du ipo gomina naa labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC nigba naa.’’

‘’Bakan naa ni aridaju wa pe Rauf tun fẹ dije du ipo gomina ni ọdun 2023, eleyii to mu kuro ni ẹgbẹ oṣelu PDP lọ si APC lasiko to si wa ni ipo gẹgẹ bi igbakeji.

Njẹ Rauf Olaniyan le gba ileẹjọ lọ lori iyọnipo rẹ?

Onimọ nipa eto oṣelu naa ni o ṣeeṣe ki Olaniyan gba ileẹjọ naa lọ,amọ ko ni jẹ nitori wọn yọọ nipo.

O ni Ile Igbimọ Aṣofin ni aṣẹ ni abẹ ofin lati yọ igbakeji ni ipo ti wọn ba ti tẹle ofin to de yiyọ igbakeji nipo lai fi si ibi kankan.

Onimọ nipa eto oṣelu naa ni Olaniyan le e lọ si ileẹjọ to ba jẹ pe ọna ti wọn gba yọ ọ, ko tele ofin.

Amọ o ni ni iwoye ti oun, ile aṣofin ipinlẹ Oyo tẹle ilana yiyọ igbakeji nipo ki wọn to yọ ọ nipo nitori ẹsun ni wọn fi kan an, ki awọn ọmọ Ile Igbimo aṣofin to jẹ ida mẹta to buwọlu u pe ki wọn yọ ọ ni ipo.

Igbesẹ mẹjọ ti wọn gbọdọ gbe ni yii ki wọn to le yọ igbakeji gomina ni ipo

  •  Igbese akọkọ ni ki ọmọ Ile Aṣofin ni Naijiria fi ẹsun aṣemaṣe kan igbakeji gomina pẹlu ibuwọlu ida mẹta awọn aṣofin.
  • Lẹyin naa ni Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin laarin ọjọ meje yoo fi iwe ẹsun naa ranṣẹ si igbakeji gomina.
  • Igbesẹ kẹta ni ki igbakeji gomina naa da wọn lohun lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an.
  • Lẹyin ọṣẹ meji naa ni abẹnugan ile aṣofin yoo fi to ile leti boya iwadii awọn ẹsun naa yoo waye.
  • Ti ida mẹta awọn aṣofin ko ba buwọlu u, wọn yoo dẹkun itẹsiwaju rẹ amọ ti wọn ba buwọlu ni olootu eto idajọ nipinlẹ naa yoo gbe igbimọ dide lati ṣewadii ẹsun ti wọn fi kan an, ti awọn igbimọ naa ko si ni jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu ati aṣofin kankan.
  • Lẹyin oṣu mẹta ni igbimọ naa yoo wa fi iwadii ti wọn yoo si fi iwe ipẹjọ ranṣẹ si igbakeji gomina naa lati wa si ile aṣofin waro ti ẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an .
  • Lẹyin naa ni awọn aṣofin yoo buwọlu boya o jẹbi ẹsun naa tabi bẹẹkọ, eleyii ti wọn sọ boya ki wọn yọọ nipo abi ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.