Alága àpapọ̀ fẹ́gbẹ́ APC sọ̀rọ̀ sóke nípa èsì ìbò Osun

Alaga fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), Sẹnatọ Abdullahi Adamu ni bi ẹgbẹ oṣelu naa ṣe fidi rẹmi ninu eto idibo gomina ni ipinlẹ Osun, lo jẹ ẹkọ ati idanwo lati ọdọ Ọlọhun fun ẹgbẹ ọhun, ti awọn si ti gba fun Ọlọrun.

 Adamu ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, ni ojuṣe awọn ọmọ ẹgbẹ ni lati pa gbogbo asise wọn rẹ ninu eto iṣejọba orilẹede yii saaju igbaradi fun eto idibo Aarẹ lọdun 2023.

 “Eto idibo gomina ipinlẹ Osun ti fihan pe isẹ si pọ fun wa lati ṣe, ti a si ti bẹrẹ awọn igbesẹ lati yii awọn nkan wa pada.”

 “A ni lati wo finifini gbogbo nkan ti a n ṣe ti ko dara ati eyi ti o da lati mọ ohun ti a nilo lati ṣe atunṣe si ninu irinajo wa si eto idibo aarẹ lọdun 2023.”

 Adamu wa fi idi e mulẹ pe isubu APC ni ipinlẹ Osun ko tumọ si pe ẹgbẹ naa ko ni fakọyọ ninu eto idibo orilẹede wa lọdun 2023.”

 O ni awọn ni lati lọ ṣe iwadi lori ohun ti o sẹlẹ ninu eto idibo Osun, ti awọn fi lulẹ ati awọn atunṣe ti awọn gbọdọ ṣe.”

Ajọ eleto idibo nilẹ wa lo kede esi idibo gomina nipinlẹ Osun to waye lọjọ Satide, ọjọ Kẹrindinlogun osu Keje ọdun 2022 ti ẹni to bori eto idibo naa ni Sẹnatọ Ademola Adeleke tii se oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP.

Adeleke lo ni apapọ ibo 403,371 eyi to mu ko fi ẹyin gomina to wa lori aleefa janlẹ, eyiun Adegboyega Oyetola.

Ìjà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Adamu ni otitọ ni pe awọn ni igbọtaraẹniye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ti o si wa lara okunfa ti ẹgbẹ na fi fidirẹmi ninu eto idibo gomina to waye ni ipinlẹ Osun

 Alaga ni ija laara awọn agba ọjẹ ẹgbẹ naa gan ni idi ti awọn padanu eto idibo naa.

“O han si gbogbo wa pe ija wa laarin awọn eeyan pakati ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Osun.”

“Awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn ni gbọmisi omioto laarin ara wọn.”

 tí gbà fún Ọlọ́run

“Ọrọ oṣelu, ọlọrun nikan lo mọ ohun ti yoo sẹlẹ, ti a si ti gba fun ọlọrun.”

Bakana ni Adamu ni bi PDP ṣe bori eto idibo naa ki ṣe nitori pe awọn mọ ọrọ oṣelu ju awọn lọ sugbọn nitori aja to wa laara awọn ọmọ ẹgbẹ ni ipinlẹ Osun.

“A ti gba fun ọlọrun.”