You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
India fòfin de iléeṣẹ́ tó pèsè oògun ikọ́ tó pa ọmọdé 69
Iléeṣẹ́ ètò ìlera ní India ti pàṣẹ pé kí iléeṣẹ́ tó ń pèsè oògùn ikọ́ èyí tí wọ́n fẹ̀sùn kàn wí pé ó ṣekúpa ọmọdé mẹ́rìndínláàdọ́rin ní orílẹ̀ èdè Gambia ṣe ìdádúró pípésè oògùn náà.
Àjọ tó ń mójútó iléeṣẹ́ ètò ìlera India ní iléeṣẹ́ Maiden Pharmaceuticals tẹ gbogbo òfin tó rọ̀ mọ́ pípésè àti àyẹ̀wò ìpèsè oògùn ní orílẹ̀ èdè náà mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń pèsè oògùn náà.
Àjọ ètò ìlera àgbáyé, WHO ló kọ́kọ́ ké gbàjare sí àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé láti wà ní tojútìyẹ́ nígbà tí wọ́n ṣe àwárí rẹ̀ pé oògùn ikọ́ mẹ́rin kan wà lára àwọn ohun tó ṣokùnfa ikú àwọn ọmọdé kan ní Gambia.
Ní báyìí, ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè Gambia àti India láti mọ ohun tó fa ikú àwọn ọmọ náà.
Àwọn àjọ tó ń mójútó ètò ìlera ní India ní àwọn ti fòfin de pípésè oògun lílò ní ilé iṣẹ́ Maiden Pharmaceuticals nítorí tí ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin tó jẹ mọ́ ààbò lórí pípèsè oògùn ni iléeṣẹ́ náà ti tàpá sófin rẹ̀.
Wọ́n ní àwọn oògùn tí iléeṣẹ́ náà ń pèsè ni kò ká ojú òṣùwọ́n, tó sì léwu fún ìlera àwọn ènìyàn.
Nígbà tí ikọ̀ ìròyìn BBC kàn sí ileeṣẹ́ Maiden, iléeṣẹ́ náà kò tètè fèsì sí ìbéèrè BBC.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ní iléeṣẹ́ náà ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn láti rí ìròyìn nípa iléeṣẹ́ àwọn lórí ikú àwọn ọmọdé Gambia.
Iléeṣẹ́ Maiden ní ìròyìn ọ̀hún ba àwọn lọ́kàn jẹ́ gidi gan.
Ṣaájú ni àjọ ìlera àgbáyé ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé lórí oògùn ikọ́ mẹ́rin tí wọ́n ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ohun ló ṣàkóbá fún kídìnrín àwọn ọmọdé tó pàdánù ẹ̀m;i wọn nínú oṣù Keje, Kẹjọ àti oṣù Kẹsàn-án ní Gambia.
Orúkọ àwọn oògùn ikọ́ náà ni Promethazine Oral Solution, Kofexmalin Baby Cough Syrup, Makoff Baby Cough Syrup àti Magrip N Cold Syrup.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Gambia ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí àwọn òbí àwọn ọmọ tó pàdánù ẹ̀mí wọn ṣe ń bèrè fún ìdájọ́ òdodo.
Ààrẹ Gambia, Adama Barrow ní ìjọba kò ní kọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti fi ohun tó ṣẹlẹ̀ gan múlẹ̀ nínú ìwádìí wọn.
Nínú èsì ìwádìí tí àwọn ọlọ́pàá fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ní iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà kan ló kó àwọn oògùn ikọ́ náà wọ orílẹ̀ èdè Gambia.
Bákan náà ni wọ́n ní kò dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta oògun náà ni àwọn ti fi gbẹ́sẹ̀ lé ní orílẹ̀ èdè náà báyìí.
Ìdájọ́ la fẹ́, awọ́n òbí ti oògùn ikọ́ ṣe ikú pa ọmọ wọn 66 ké gbàjarè sí ìjọba
Ẹ o ranti pe a mu iroyin wa pe Kẹkẹ ọmọde wa lẹgbẹ kan ninu ile Mariam Kuyateh ti eruku si ti n bo mọlẹ.
O yẹ ko jẹ ti ọmọ rẹ, Musa ti ki ba ti pe ọdun meji ṣugbọn o dagbere faye loṣu Kẹsan.
O jẹ ọkan lara ọmọ mẹrindinlaadọrin ti ijọba Gambia gbagbọ pe wọn papoda lẹyin ti wọn fun wọn loogun ikọ kan ti ajọ isọkan agbaye sọ pe ''o lohun ṣe pẹlu ṣiṣe akoba fun kidinrin''
Ko si ẹnikankan ninu mọlẹbi Mariam to n fọwọ kan kẹkẹ Musa-iranti lo jẹ pe wọn padanu ọmọdekunrin yi lọjọ aipe.
Iya rẹ to jẹ ẹni ọgbọn ọdun to si ni ọmọ mẹrin mii a maa sunkun lọpọ igba to ba ti ranti iku Musa.
Bi Musa ṣe ku ree
Nibi to joko si ninu ile rẹ to wa lagbegbe Serrekunda, Mariam ṣalaye bi aarẹ ọmọ rẹ ṣe bẹrẹ pẹlu ọfinkin.
Lẹyin ti wọn gbe lọ ri dokita, ọkọ Mariam wa ra oogun ikọ kan lati fi ṣe itọju ọmọ naa ''ṣugbọn oogun yi lo da wahala mii silẹ lara ọmọ wa''gẹgẹ bi Mariam ṣe sọ.
''Ọmọ mi ko ribi tọ la ba gbe lọ si ileewosan ti wọn si tun ayẹwo ẹjẹ mii ṣe fun eyi to fi han pe kii ṣe iba lo n daamu rẹ''
O ni wọn fun ni itọju mii el;eyi ti ko ṣiṣẹ ti wọn siso ọpa mọ nidi ko baa le ribiu tọ ṣugbọn eleyi naa ko ṣiṣẹ''
''Lẹyin igba naa, wọn ṣe iṣẹ abẹ fun ṣugbọn ko si iyatọ''
''Ọmọ mi ko ribi ruu la. Bo ṣe gbabẹ faye silẹ ni yẹn''
Ni ibẹrẹ ọsẹ yi ni ajọ iṣọkan agbaye WHO ke gbajare ikilọ lagbaye lori awọn oogun ikọ mẹrin kan to niṣe pẹlu iku awọn eeyan ni Gambia
Awọn oogun ikọ yi - Promethazine Oral Solution, Kofexmalin Baby Cough Syrup, Makoff Baby Cough Syrup ati Magrip N Cold Syrup - la gbọ pe ileeṣẹ ipoogun kan ni India n pọn wọn.
Amọ ṣa WHO sọ pe awọn ko ri idanilojuaabo tabi ayẹwo topeye ti ileeṣẹ Maiden Pharmaceuticals ṣe lori awọn oogun yi.
Ijọba India lawọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yi.
Ileeṣẹ apoogun yi ko ti sọ nkankan lori ibeere ti BBC fi sọwọ si wọn.
Ni lawọn eeyan n faraya lori nkan to ṣẹlẹ ni Gambia yi tawọn kan si ni ki Minisita feto ilera ilẹ naa Dokita Ahmadou Lamin Samateh kọwe fipo silẹ ki awọn to gbe oogun naa wọ ilẹ naa si foju wina ofin.
''Eeyan mẹrindinlaadọrin ko kere. Tori naa, a fẹ idajọ ododo lori iṣẹlẹ yi tori awọn ọmọde lo farakasa iṣẹlẹ yi''
Ọrọ ti arabinrin Kuyateh sọ ree