You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lẹ́yìn ọdún márùn-ún àti oṣù mẹ́jọ́, Òṣèré fíìmù Seun Egbegbe gba ìtúsílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n
O ṣeeṣe ki awọn kan tilẹ ti gbagbe oju oṣere yii amọ awọn to ba maa n wo fiimu rẹ ni bii ọdun meje sẹyin, yoo ranti Seun Egbegbe daadaa ti wọn fi ofin gbe e fun ẹsun ole jija nigba naa.
Oṣere fiimu Yoruba yii, Olajide Kareem ti ọpọlọpọ n pe ni Seun Egbegbe ti wa gba itusilẹ bayii amọ o jiya ẹṣẹ rẹ fun odindi ọdun mẹfa ati oṣu mẹjọ ninu ẹwọn.
Ninu oṣu Keji ọdun 2017 lo wọ gbaga ofin lẹyin ti wọn fi ẹsun kan-an pe o fi ọna ẹburu gba owo lọwọ awọn eniyan ti ko din ni ogoji eeyan to n ṣẹ owo ilẹ okere ni ipinlẹ Eko.
Bakan naa ni iroyin gba igboro kan nigba pe o ji foonu iPhone.
Wọn ni laaarin ọdun 2015 si 2017 ni Egbegbe fi tan awọn eniyan naa lati fi gba owo lọwọ wọn.
Ẹsun wi pe Egbegbe lu awọn to n ṣẹ owo ilẹ okere ni jibiti nipa gbigba owo naira lọwọ lati bawọn ṣẹ si owo oke okun.
Apapọ awọn owo ti awọn ọlọpaa ka si Egbegbe lẹsẹ wi pe o lu jibiti rẹ ni miliọnu mọkandinlogoji naira (#39,000,000), ẹgbẹrun lọna aadọrun-un dọla ($90,000) ati ẹgbẹrun mejila pọun.
Seun Egbegbe ati ẹni kan Oyekan Ayomide ni awọn ọlọpaa kọkọ wọ lọ sile ẹjọ lori ẹsun jibiti lilu naa ki wọn to mu awọn mẹta miiran, Lawal Kareem, Olalekan Yusuf ati Muyideen Shoyombo lati kun wọn.
Ẹsun mẹrinlelogoji ni wọn ka si wọn lọrun lori jibiti lilu.
Egbegbe ri itusilẹ lẹyin ọdun marun-un lọgba ẹwọn
Ẹ̀wẹ̀, ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kọkanla oṣu Kẹwaa ọdun 2022 ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni Ikoyi, ipinlẹ Eko ni Egbegbe ko jẹbi ẹsun mẹtalelogoji ninu mẹrinlelogoji ti wọn fi kan-an.
Adajọ Oluremi Oguntoyinbo nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ ni Egbegbe jare awọn ẹsun ti wọn fi kan an yatọ si ẹyọkan nitori awọn to gbe ẹsun rẹ wa si ile ẹjọ ko ni ẹri lati fi ẹsun naa mulẹ.
Oguntoyinbo ni ko si awọn awọn ẹlẹrii lati fidi awọn naa mulẹ bi ẹsun kẹrin kọkandinlogun ati ikọkanlelogun.
Bakan naa lo ni awọn ọlọpaa ti ṣe eru lori owo ti wọn gba lọwọ Egbegbe lasiko igbẹjọ naa to si paṣẹ pe gbogbo owo ti wọn gba lasiko igbẹjọ naa ni ki wọn da pada fun-un.
O ni oun tu Egbegbe silẹ ko maa lọ sile rẹ layọ ati alafia lẹyin to lo ọdun marun-un lọgba ẹwọn.
Ki Seun Egbegbe to ko si gbaga ọlọpaa, oun ni alakoso ile iṣẹ Ebony Films Production, to n gbe fiimu Yoruba jade.
Bakan naa lo tun ti ṣakoso awọn olorin Fuji bii Pasuma, Wale Ayinde ati Tekoma ṣugbọn.