You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pásítọ̀ kó sí gbaga fún ṣíṣe aṣemáṣe pẹ̀lú ọmọdé tó jẹ́ àkàndá l'Ondo
Pásítọ̀ ìjọ Christ Apostolic Church Modebiayo, Oke-Gburowo, Igburowo ní ìjọba ìbílẹ̀ Odigbo, ìpínlẹ̀ Ondo, Peter James ti wà ní àhámọ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun, lẹ́yìn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé ó fún ọmọ ìjọ, ọmọ ọdún mẹ́tàlá lóyún.
Ìròyìn ní, níṣe ni wọ́n gbé pásítọ̀ náà lọ síwájú Ọba ìlú náà, Oloja Moses Ogunmoyewa fẹ́sùn fífún ọmọ náà lóyún.
Ọmọdébìnrin nàá tó jẹ́ àkàndá ẹ̀dá, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akọrin ilé ìjọsìn náà.
Iléeṣẹ́ ààbò Amotekun ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn náà látàrí bí pásítọ̀ ọ̀hún ṣe jiyàn wí pé òun kò fún ọmọ náà lóyún.
Ìròyìn ní pásítọ̀ ọ̀hún ti kọ́kọ́ gbà wí pé òun ni òun fún ọmọdébìnrin nàá lóyún nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wọ ọ lọ sílé ọba ìlú náà, tí ọba àtàwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ sì ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ ohun tó sọ.
Àmọ́ níṣe ni ọ̀rọ̀ tún bá ibòmíràn yọ nígbà tí pásítọ̀ náà tún jiyàn pé òun kò fún ọmọ náà lóyún.
Olú ìjọ ilé ìjọsìn náà ti dá sí ọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n pásítọ̀ Peter ṣi fi àáké kọ́rí pé, òun kọ́ ni òun fún ọmọ náà lóyún.
Ìyá ọmọdébìnrin nàá, Victoria Bernard sọ pé pásítọ̀ náà mọ̀ọ́mọ̀ ń jiyán oyún ọmọ òun ni nítorí pé ó jẹ́ àkàndá èèyàn.
Arábìnrin Bernard ni òun rọ ìjọba àtàwọn èèyàn láti ran òun lọ́wọ́ láti bá àwọn dá sí ọ̀rọ̀ náà kí wọ́n má ba à yan òun àt ọmọ náà jẹ.
Ọ̀kan lára àwọn pásítọ̀ ìjọ náà tí kò fẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn dárúkọ rẹ̀ sọ pé, olú ìjọ náà tó wà ní ìlú Odigbo ti ń dá sí ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìrètí pé yóò ní ìyanjú láìpẹ́.