Ṣé lóòtọ́ọ́ nilé aṣòfin àgbà fẹ́ yọ ààrẹ ilé, Godwill Akpabio nípò bí ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá ṣe dúró?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lojiji ni iroyin kan gbode laarin ọsẹ, eyi to n sọ pe igbesẹ ti bẹrẹ lati yọ olori ile igbimọ aṣofin agba Naijiria, Godswill Akpabio, kuro nipo olori ile igbimọ naa.

Awọn aṣofin kan ni a gbọ pe wọn wa nidii ete lati yọ Akpabio kuro nipo rẹ, iroyin naa si tan kalẹ laipẹ rara.

l’Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii, iroyin kan sọ pe awọn oṣiṣẹ DSS wa si ile igbimọ naa, bẹẹ ni awọn mọto wọn pọ ninu ọgba ọhun pẹlu, ati pe o ni i ṣe pẹlu Akpabio.

Àlàyé ìjọba lórí ìgbésè yìí

Senetọ Bashir Garba Lado to maa n gba Aarẹ Naijiria nimọran lori ọrọ awọn aṣofin, sọ pe ko si otitọ kan ninu iroyin naa, bo tilẹ jẹ pe awọn ileeṣẹ iroyin kan ti gbe e jade.

O ni ko si ẹni to fẹẹ yọ olori ile igbimọ naa nipo rẹ.

Gẹgẹ bi Bashir ṣe sọ, ’’mo fi n da yin loju pe ko si nnkan to jọ bẹẹ.

‘’Ki i ṣe tuntun pe ki awọn ọlọpaa abi awọn ẹṣọ alaabo DSS wa ninu ọgba ile igbimọ aṣofin, iṣẹ aabo naa ni wọn n ṣe nibẹ.

"Mo wa ninu ọfiisi mi nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, mo si dide lẹsẹkẹsẹ lati wo ohun to n ṣẹlẹ, mo ri i daju pe ko sohun to jọ ohun ti wọn n sọ kiri.

"Ajeji ti ko ba wọ ile igbmọ ri, ni riri awọn awọn DSS nibẹ le maa jọ loju."

Olugba aarẹ nimọran, Bashir Garba Lado lo ṣalaye bẹẹ.

Ohun ti awọn eeyan n sọ pe o fa awuyewuye iyọnipo yii ko ṣẹyin awọn ọrọ kan ti wọn ni Godswill Akpabio sọ, eyi ti wọn lo jọ fifi araalu ṣe yẹyẹ pẹlu bi nnkan ṣe le to ni Naijiria lasiko yii.

Bi eyi ti wọn lo ti sọ pe ibi ti wọn ba ti ri ounjẹ ọfẹ, ki wọn ma ṣafara lati jẹ ẹ, nitori pe ilu le.