You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn òbí fẹ́ kí àjọ JAMB fagilé gbogbo èsì ìdánwò UTME tó jáde torí àṣìṣe tó wà níbẹ̀
Awọn obi atawọn akẹkọọ kan to ṣe idanwo UTME lati wọle si ile ẹko giga fasiti atawọn ile ẹkọ giga mii ni Naijiria ti kepe ajọ JAMB to n ṣagbatẹru idanwo naa lati fagile gbogbo esi idanwo ti wọn gbe jade lẹyin ti ajọ naa sọ pe aṣiṣe wa ninu esi idanwo naa.
Awọn eeyan yii tun tako igbesẹ ajọ JAMB lati tun idanwo naa ṣe nipinlẹ Eko ati lawọn ipinlẹ ẹkun ila oorun guusu Naijiria nikan.
Awọn obi atawọn akẹkọọ naa ni ko dara fawọn akẹkọọ kan lawọn ipinlẹ perete ni Naijiria da idanwo naa tun ṣe papaa julọ pẹlu kudiẹ kudiẹ ti ajọ naa sọ pe o waye lati ọwọ wọn.
Lana Ọjọru ni Ọga agba ajọ JAMB, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, bu sẹkun nigba to n tọrọ aforijin fun aṣiṣe to wa ninu esi idanwo UTME to jade ti o si sọ pe ki wọn di ẹbi ọrọ naa ru oun.
Ọjọgbọn Oloyede ṣalaye pe bi ọpọ eeyan ṣe n kọminu ti wọn si n fi aidunnu wọn lori esi idanwo naa lo jẹ ki ajọ JAMB tete ṣe agbeyẹwo esi idanwo ọhun, bi bẹẹ kọọ, oṣu Kẹfa to n bọ lawọn o ba ṣe agbeyẹwo naa.
Ibudo idanwo 65 nipinlẹ Eko eyi to kan akẹkọọ 206,610 ati ibudo 92 lẹkun Owerri eyi to kan akẹkọọ 173,387 ni ọrọ yii kan gẹgẹ bi alaye ti ọga agba JAMB ṣe sọ.
Ọjọgbọn Oloyede ni ajọ JAMB yoo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sawọn akẹkọọ yii ṣaaju ọla ọjọ Ẹti ati ọjọ Abamẹta ti wọn yoo tun idanwo naa ṣe.
Amọ, awọn obi kan ti wọn bawọn akọroyin sọrọ ti sọ pe ohun to tọ fun ajọ JAMB lati ṣe ni pe ki fagile gbogbo esi idanwo ti wọn jade ki wọn si ṣe idanwo mii fun awọn akẹkọọ.
Ọgbẹni Bosun Arowogbade, ọkan lara awọn obi to bawọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe oriṣiiriṣii aṣiṣe lo jẹyọ ninu idanwo naa.
O ni awọn ibeere ti wọn bi awọn akẹkọọ ko pe fun awọn iṣẹ kan, bakan naa lo sọ pe siṣe idanwo laago mẹfa aarọ ko dara to.
Obi miran, Alhaji Gbade Ojomu, sọ pe Ọjọgbọn Oloyede gbọdọ fagile gbogbo esi idanwo ti ajọ JAMB gbe jade ki wọn si ṣe idanwo mii fun gbogbo akẹkọọ.
O ni nnkan ti awọn ọmọ Naijiria fi le fori jin Ọjọgbọn Oloyede niyẹn gẹgẹ bi o ti tọrọ aforijin.
Aham Ijendu Chimereze to kopa ninu idanwo yii niluu Owerri sọ pe oun ṣetan lati tun idanwo naa ṣe ti ko ba tun ni si aṣiṣe mii.
Akẹkọọ mii, Uchenna Eme ni ago mẹrin loun pada sẹ idanwo naa bo tilẹ jẹ pe ago mẹfa ni JAMB sọ pe kawọn bẹrẹ.
O ni oun ṣetan lati tun idanwo naa ṣe bo tilẹ jẹ pe oun ko tii mọ ohun toun ninu idanwo to lọ.
Kókó márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa àtúnṣe ìdánwò UTME tí JAMB tún kéde rẹ̀
Ajọ JAMB to n ṣakoso idanwo ati ati gbaniwọle si ile ẹkọ giga fasiti at'awọn ile ẹkọ giga mii ni Naijiria ti ni atunṣe idanwo Jamb yoo waye ni Ọjọ kẹrindinlogun oṣu Karun un, ti wọn yoo si fun awọn akẹkọọ kan ni anfani lati tun idanwo ṣe
Eyi wa lẹyin ti iwadii fihan pe ọwọ Jamb ni aṣiṣe to fa ti ọpọ akẹkọọ fi fi idi rẹmi ti waye.
Ninu atẹjade kan ti Jamb fi lede, wọn ni otitọ ni pe awọn aṣiṣe kan wa lati ọwọ wọn lasiko ti wọn ṣe idanwo Jamb ti ọdun 2025.
Bo ti lẹ jẹ pe Ọga fun ajọ Jamb, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede ti tọrọ aforijin lọwọ awọn akẹkọọ ti ọrọ kan lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ fun aṣiṣe naa, to si tun ṣe ileri pe gbogbo ọna ni oun yoo fi ṣe atunṣe.
"Ohun to yẹ ko jẹ ohun idunu ti yipada nitori aṣiṣe kan tabi ikeji,"Oloyede sọrọ.
Akọwe ajọ kede pe o le akẹkọọ 379,997 ti yoo tun idanwo naa ṣe pada.
Eyi lo waye lẹyin ti ọpọ bu ẹnu atẹlu esi idanwo ti ajọ naa gbe jade lẹyin idanwo.
Awọn ipinlẹ wo ni eyi ṣe akoba fun?
JAMB ni awọn ti ṣawari ohun to sẹlẹ to ṣe akoba fun ile idanwo 157 ni ipinlẹ Eko ati Owerri.
Ni ipinlẹ Eko ati Oyo, ile idanwo marundinlaadọrin ni kudiẹkudiẹ yii ṣe akoba fun. Ni ipinlẹ Aba, Imo, Abia Anambra ati Ebonyi, ile idanwo mejidinlaadọrun ni wọn ko ri ayelujara ṣiṣẹ.
Ọjọ wo ni idanwo yii ati pe ki ni awọn akẹkọọ nilo?
Ọjọgbọn Oloyede ni bẹrẹ lati ọjọ kẹrindinlogun oṣu Karun un, awọn akẹkọọ ti ọrọ yii kan yoo bẹrẹ si ni ma tun awọn idanwo yii kọ. O ni ọpọ idanwo ni yoo waye lọjọ Ṣatide, ti awọn akẹkọọ yoo si nilo lati mu iwe idanwo wọn dani.
Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, awọn akẹkọọ ti ọrọ yii kan yoo gba atẹjisẹ lori foonu wọn, eyi ti yoo kọka ọjọ ati ibi ti wọn yoo ti ṣe idanwo.
"Awọn miiran le gbe ipe. Wọn ni lati lọ tun iwe idanwo pọ jade lati ori ayelujara ti wọn yoo fi ṣe idanwo."
O fikun pe o ṣeeṣe pe atunṣe idanwo yii waye lọjọ kana pẹlu idanwo WAEC to n lọ lọwọ ṣugbọn JAMB ti n ba awọn WAEC sọrọ lori ọna lati ma jẹ ki iṣẹlẹ naa waye.
Ọ̀gá Àgbà àjọ JAMB bú sẹ́kún, ó ní lóòótọ́ ni àwọn ṣe àṣìṣe nínú èsì ìdánwò UTME ọdún 2025 tó jáde
Ajọ JAMB to n ṣakoso idanwo ati ati gbaniwọle si ile ẹkọ giga fasiti at'awọn ile ẹkọ giga mii ni Naijiria ti sọ pe aṣiṣe wa ninu esi idanwo UTME tọdun 2025 yii to ṣẹṣẹ jade.
Ọgagba ajọ JAMB, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, bu sẹkun gbaragada nigba to fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin lonii Ọjọru niluu Abuja.
Ọjọgbọn Oloyede ni "nnkan to yẹ ko jẹ ayọ ti di ibanujẹ nitori aṣiṣe tó wáyé."
Akọwe agba JAMB naa kede pe bii 379,997 awọn akẹkọọ to ṣe idanwo naa ni yoo tun idanwo ọhun ṣe bayii.
Eyi ko ṣẹyin awọn kudiẹ kudiẹ to waye to ṣokunfa bi ọpọ akẹkọọ ṣe fidirẹmi ninu idanwo naa.
Ajọ JAMB fidi rẹ mulẹ loju opo X rẹ pe mẹtadinlọgọjọ (157) ninu aadọrun-un le lẹẹgbẹrin din mẹta (887) ibi ti idanwọ ọhun ti waye ni aṣiṣe ti waye.
Ajọ naa sọ pe eyi gan lo ṣokunfa bi maaki ọpọ akẹkọọ ti ṣe idanwo lawọn ibikan ṣe lọọlẹ gan an.
NI bayii, gbogbo awọn akẹkọọ tọrọ kan ni ajọ JAMB yoo kan si lati tun idanwo naa ṣe laipẹ.
Lọjọ Aje to kọja ọjọ kejila oṣu Karun un yii ni ajọ JAMB kede pe awọn yoo ṣe agbeyẹwo esi idanwo UTME ọdún 2025 t'awọn gbe sita.
Agbẹnusọ ajọ JAMB, Fabian Benjamin, ṣalaye pe igbimọ alaṣẹ ajọ naa yoo ṣe agbeyẹwo ọhun ni kiakia.
O ni gbogbo ohun to ni ṣe pẹlu idanwo naa ni wọn yoo ṣe agbeyẹwo rẹ fínífíni.
Eyi ṣẹlẹ tori bi ọpọ eeyan ṣe sọrọ nipa esi idanwo UTME ọdún yìí eyi ti ọpọ akẹ́kọ̀ọ́ fìdírẹmi ninu rẹ.
Ọgbẹni Benjamin sọ saaju wipe ajọ JAMB yoo ṣe ohun to tọ tó bá jẹ pe loootọ ni kudiẹ kudiẹ wa ninu eto idanwo naa.
Ọpọ eeyan ṣe ifẹhonuhan lori ayelujara tori esi idanwo JAMB ti ọpọ akẹkọọ ti fidirẹmi
Ṣaaju ni ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa julọ awọn ti esi idanwo naa kan gbọngbọn, ti bọ sori ayelujara lati fi ẹdun ọkan wọn han.
Ọpọ akẹkọọ lo ni esi idanwo tawọn gba kọja gan-an ko buru to ti 2025 yii.
Akọle kan ti i ṣe #thisisnotmyresult, ni awọn eeyan naa n lo lati fi aidunnu wọn han, ti wọn si n pe fun atunyẹwo esi idanwo yii.
Esi ti JAMB fi sita kede pe bii miliọnu kan aabọ akẹkọọ (1.5 million candidates), ni ko gba to maaki igba (200) ninu idanwo naa.
Itumọ eyi ni pe ida ọgọrin (80%) akẹkọọ ni ko gba maaki igba ninu irinwo (400).
Iṣẹ mẹrin ti maaki ọkọọkan jẹ ọgọrun-un (100) ni awọn akẹkọọ naa jokoo ṣe ninu UTME, apapọ rẹ lo jẹ irinwo (400).
JAMB ṣalaye pe akẹkọọ yoo kọkọ fi orukọ silẹ, yoo jokoo ṣedanwo, esi yoo si jade. Igbesẹ mẹta naa ko ju bẹẹ lọ.