You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé rèé lórí bí òkùnrin kan ṣe pàdánù $2.1m sórí ‘cryptocurency’
Ni bayii ti ọkunrin ti wọn n pe ni ‘King of Crypto’ yoo maa jẹjọ lori oniruru ẹsun jibiti, ọkunrin ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan ti ṣalaye bi oun ati ọpọ eeyan kaakiri agbye ṣe padanu obititi owo si ileeṣe Sam Bankman-Fried.
Titi di igba ti ileeṣẹ naa fi lulẹ, Sunil Kavuri ṣi gbagbọ pe Sam Bankman-Fried ṣi le wa ọna abayọ si iṣoro ti wọn dojukọ.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣe King of Cryotp ti n dawo, Sunil gbagbọ pe ko si ewu loko.
Eyii ko si ṣẹyin awọn irirri rẹ nipa idowopọ pẹlu awọn ileeṣẹ nla nla bii ile ifowopamọ ati bo ṣe maa n ṣowo crypto ṣaaju.
Igbagbọ rẹ pọ ninu Sam Bankman-Fried to bẹẹ to fi sọ pe ko si ewu loko.
Ẹnu rẹ lo wa titi to fi ri atẹjisẹ pe ko si anfani lati gba owo jade mọ.
Eyii ko ṣẹyin bi ileeṣẹ FTX, to jẹ ileeṣẹ to tobi julọ lagbaye nipa paṣipaarọ cryptocurency ṣe lulẹ.
Gbogbo oogun oju Sunil fun ọjọ pipẹ lo ba ileeṣe naa lọ lẹyin to padanu owo ti iye rẹ jẹ $2.1 nibẹ.
"Pupọ ninu awọn to dokowo ninu Bitcoin yii lo ti di ẹdun arinlẹ, nigba ti awọn mii padanu owo to le ni ọpọ miliọnu"
Iroyin ni ọgbẹni Sunil ni ọmọ ilẹ Gẹẹsi to padanu owo to pọ julọ ninu iṣẹlẹ naa.
Amọ yatọ si Sunil ọpọ awọn eeyan bii tirẹ lo padanu owo nla sileeṣẹ naa kaakiri agbaye, o si ti darapọ mọ awọn eeyan naa lati pe FTX lejọ bayii.
Sunil ni “ẹnikan tilẹ wa lorilẹ-ede Turkey to jẹ pe $600 nikan lo ku lọwọ rẹ lẹyin to padanu gbogbo owo rẹ sọwọ FTX, nigba ti ẹlomiran ni South Korea ti dero ile iwosan.”
Sunil ti bẹrẹ iranlọwọ fun awọn eeyan lati ilẹ Amẹrika, Canada, Argentina, Dubai, Turkey, Hong Kong, China ati Singapore lẹyin iṣẹlẹọhun.
Pupọ ninu wọn lo ti di ẹdun arinlẹ, nigba ti awọn mii padanu owo to le ni ọpọ miliọnu.
Gbogbo wọn lo n duro de igbẹjọ rẹ lọsẹ to n bọ.
Miliọnu meṣan an eeyan lati orilẹ-ede bii ọgọrun un lo dokowo ninu Bitcoin
Ẹsun meje ọtọtọ to ni ṣe pẹlu iwa jibiti ni awọn aṣofin ilẹ Amẹrika fi kan Sam Bankman Fried.
Ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn naa, to da ileeṣẹ FTX ti sọ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, amọ yoo pe ẹjọ tako awọn ẹsun naa.
Yatọ si oun, awọn lọgalọga nileeṣe rẹ naa ti gba pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn kan wọn, wọn si ṣetan lati sọrọ lori bi ileeṣẹ naa ṣe da wo.
FTX jẹ ileeṣẹ ti ọpọ gbagbọ pe wọn le ko owo wọn le lori fun owo crypto ṣiṣe.
Lara awọn katakara ti awọn eeyan le ṣe nileeṣẹ naa ni Bitcoin, atawọn owó ayelujara mii.
Miliọnu meṣan an eeyan lo ba ileeṣẹ naa dowopọ lati awon orilẹ-ede bii ọgọrun un.
Nigba ti ileeṣẹ ọhun dawo, nnkan bii miliọnu kan eeyan ni owo wọn bọ ha nitori wọn ko tete gba awọn owo naa jade.
Koko ẹsun ti wọn fi kan Sam Bankman Fried ni pe o lo owo awọn to ba ileeṣe rẹ dowopọ fun awọn owo mii fun anfani ara rẹ, ati lati ra awọn ile olowo nla, wọn ni o tun bun ọpọ oloṣelu lowo fun ipolongo ibo.
"Lẹyin ti awọn eeyan bẹrẹ si n gba owo wọn ni ileeṣẹ Bitcoin da wo"
Wahala bẹrẹ fun ileeṣẹ naa lẹyin iroyin kan ti ileeṣẹ Coindesk gbe jade nipa rẹ lẹyin iwadii kan, eyii to mu ki ọpọ awọn oniṣowo rẹ lọ maa gba owo wọn jade nibẹ.
Lẹyin ti awọn eeyan bẹrẹ si n gba owo naa ni ileeṣẹ ọhun da wo.
Amọ Sam Bankman Fried ti sọ pe oun ko lu owo olowo ni ponpo, oun ko si na owo ti awọn eeyan ko si ikawọ oun ni inakuna.
Wayi o, Sunil Kavur ti sọ pe Sam Bankman Fried ti ba aye ọpọlọpọ eeyan jẹ.
Sunil lo pe meji ninu oniruru ẹjọ ti FTX yoo jẹ, ti ọkan ninu rẹ jẹ lodi si awọn gbajumọ to maa n ṣe ipolowo crypto.
Lọṣẹ to kọja ni wọn pe iya to bi Bankman-Fried naa lẹjọ lori awọn owo ati dukia to ti gba lọwọ ọmọ to jẹ olujẹjọ.
Lara awọn dukia naa ni awọn ile to ni lorilẹ-ede Bahamas.
Kavuri sọ pe igbagbọ oun tunbọ gbilẹ si ninu FTX lẹyin ti ileeṣẹ Sequoia Capital dowopọ pẹlu rẹ pẹlu owo ti iye rẹ to $213m.
O ni “Mo ri ọpọ eeyan ti wọn n ko owo wọn lọ sibẹ ti wọn si n fontẹ lu ileeṣẹ naa, eyii to mu ki n gbabọ pe ko ni sewu.
Ọjọbọ to kọja ni Sunil ati iyawo rẹ bi ọmọ wọn keji, eyii to fun ni iwuri lati tiraka lati gba owo rẹ to padanu pada.
Amọ ni bayii, ko si ohun miran to le ṣe ju ko duro pẹlu ireti pe yoo ri owo naa gba pada.
Awọn agbẹjọro Sam Bankman-Fried ti ni awọn ko ni ohunkohun lati sọ lori ọrọ yii.