Mi ò kàn dédé fún Mide Martins lóyún, bí ìrìnàjò ìfẹ́ wa ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí - Afeez Owo

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Afeez Abiodun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Afeez Owo ti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó rọ̀ mọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Mide Martins láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.

Afeez Owo tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ pé òun kò kàn ki Mide Martins mọ́lẹ̀ láti fun lóyún gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ń gbe kiri nígbà kan.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò kọ ẹnu ìfẹ́ sí Mide Martins, ó ṣàlàyé pé látara bí òun àti Mide Martins ṣe ń jáde kiri láti gbé polongo àwọn eré tí ìyá rẹ̀, Funmi Martins ṣe kalẹ̀ kó tó jáde láyé ni eré ìfẹ́ àwọn ti bẹ̀rẹ̀.

Ó ní láti ara Funmi Martins ni òun àti Mide Martins ti di ọ̀rẹ́, tó fi jẹ́ pé ìgbà tí Mide máa kọ́kọ́ ní ọkọ àfẹ́sọ́nà àkọ́kọ́, ó ṣàlàyé fún òun tí òun náà sì mọ àfẹ́sọ́nà ti òun náà.

“Gbogbo bí èmi Mide ṣe ń lọ sí àwọn ìlú káàkiri láti lọ polongo àwọn sinimá tí ìyá rẹ̀ ṣe kalẹ̀, ni nǹkan tó so àwa méjéèjì pọ̀.”

"Mo mọ afẹsọna Mide Martins, O si mọ afẹsọna temi naa"

“Nígbà tí òun àti ẹni tó ń fẹ́ nígbà náà kò sí papọ̀ mọ́, tí ẹni tí èmi náà sì ń fẹ́ ti já mi kulẹ̀ ni a bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ìfẹ́ wa.”

Ó ṣàlàyé pé bí àwọn ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ìfẹ́ àwọn nìyẹn àti pé òun àti Mide kò tilẹ̀ mọ̀ pé àwọn le bá ara àwọn nínú eré ìfẹ́.

Gbajúmọ̀ òṣèré náà ní òun kò mọ̀ pé Mide Martins ma padà ṣe fíìmù láyé nítorí ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ láti kópa nínú sinimá rẹ̀ ṣùgbọ́n tó máa ń fárígá.

Ó ní òun bá Mide sọ̀rọ̀ pé tó bá fẹ́ tọ́jú àwọn àbúrò rẹ̀, ó ní láti tẹsẹ̀ bọ bàtá tí ìyá rẹ̀ bọ́ kalẹ̀, kó lè ba à tẹ̀síwájú láyé.

Ó fi kun pé kò sí ìbáṣepọ̀ tàbí ìbágbépọ̀ ènìyàn méjì tí kìí ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ nínú àmọ́ òun dúpẹ́ pé Ọlọ́run bá òun to ìdílé òun àti pé ìyàwó òun kìí ni òun lára rárá.

Bákan náà ló rọ àwọn tọkọtaya láti máa fi Ọlọ́run síwájú nínú gbogbo ìgbésí ayé wọn nítorí kò sí ìdílé tí kò ní àwọn ìpèníjà tirẹ̀.

Báwo ni Afeez Owo àti Funmi Martins ṣe pàdé?

Afeez Owo ṣàlàyé pé níbi iṣẹ́ sinimá Yinka Quadri kan tí òun ṣe alákòso rẹ̀ ni òun àti Funmi Martins ti pàdé àti pé kùkárí òun lórí sinimá náà ni àwọn fi di ọ̀rẹ́.

Ó ní gbogbo ìgbà tí àwọn fi ń ṣe iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Funmi Martins yìí Mide kò sí ní Nàìjíríà, orílẹ̀ èdè United Kingdom ni ó wà.

Ó ní nígbà tí Mide Martins padà sí Nàìjíríà ni òun àti ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ àti pé gbogbo nǹkan tó bá fẹ́ ṣe kìí ṣe ẹ̀yìn òun.

Ó ṣàlàyé pé Funmi Martins ni ó kọ́ka fún òun ní owó tí òun fi ṣe fíìmù òun àkọ́kọ́ jáde àti pé òun ló kó ipa tó lóòrìn nínú sinimá náà láì gba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ òun.

“Oríire mi kò ṣé kò yẹ̀ ní ìlànà ẹbí Funmi Martins, kò sí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ láàárín èmi àti Mide, mi ò le gbàgbé àwọn oore tí ìyá rẹ̀ ṣe fún mi.”

"Dókítà, agbẹjọ́rò tàbí olùkọ́ ló wù mí kí n dà láyé"

Afeez Owo ní láti ọdún 1984 ni òun ti bẹ̀rẹ̀ eré sinimá gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.

Afeez Owo ṣàlàyé pé iṣẹ́ dókítà tàbí agbẹjọ́rò tàbí olùkọ́ ló òun kí òun ṣe láyé àmọ́ àárẹ̀ ńlá kan tó dé bá òun nígbà tí òun wà ní ipele tó kẹ́yìn ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún ètò ẹ̀kọ́ òun.

Ó ní ọ̀pọ̀ oṣù ní òun fi ṣe àárẹ̀ yìí, tó jẹ́ wí pé orí àárẹ̀ náà ni òun wà tí wọ́n fi gbé òun lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti lọ ṣe ìdánwò àṣekágbá ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé àárẹ̀ náà ṣokùnfà tí ẹsẹ̀ òun méjéèjì rọ, tí òun kò lè dìde rìn lórí ibùsùn tí òun wà tó jẹ́ pé wọ́n máa ń gbé òun ṣe gbogbo nǹkan ni.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun yege ìdánwò náà, ìpèníjà ńlá ni owó tún jẹ́ fún òun láti fi tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ òun.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ni òun ṣe láti fi rán ara òun ní ilé ẹ̀kọ́ nítorí àwọn òbí òun kò sí papọ̀ mọ́ tí òun sì gbọdọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ náà tí òun bá fẹ́ tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ òun.

Afeez Owo ní òun máa ń kiri ọtíkà láti fi kún àwọn iṣẹ́ tí òun ṣe tí òun fi parí ilé ẹ̀kọ́ girama àmọ́ kò sí agbára fún òun láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga.

"Big Abbas ló kọ́ mi ní eré tíátà ọfọ̀ pípa"

Ó fi kun pé nígbà tí òun kúrò ní Iseyin lọ sí ìpínlẹ̀ Eko láti wá bí yóò ṣe da fún òun si ni òun pàdé ìyàwó olóògbé Muritala Muhammed.

Afeez Owo ní ọmọ ìyá náà ló mú òun lọ sí National Theatre níbi tí òun ti pàsé Big Abbas tí òun sì fi bẹ̀rẹ̀ eré kí á máa pa ọfọ̀.

Ó ní nígbà tó yá ni òun pàdé Yemi my lover tí ìrìnàjò eré sinimá òun fi bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.

Ó fi kun láti ìgbà ni òun ti ń ṣeré sinimá tí òun sì ti lò tó ọgbọ́n ọdún nídìí eré tíátà ní ṣíṣe.

Ta ni Afeez Owo?

Gbajúmọ̀ elére tíátà àti sinimá ni Afeez Abiodun tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Afeez Owo.

Ó gbajúmọ̀ fún ṣíṣe àgbàlagbà nínú àwọn sinimá tó sì máa ń sọ èdè ìlú Iseyìn lẹ́nu.

Yàtọ̀ sí ṣíṣe eré, Afeez Owo tún máa ń darí àwọn eré sinimá.

Ọmọ bíbí ìlú Iseyin ní ìpínlẹ̀ Oyo ni afeez Owo.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré ni Afeez Owo ti kópa nínú rẹ̀, tó sì ti gba àmì ẹ̀yẹ lé wọ́n lórí.

Bákan náà ló jẹ́ ọkọ gbajúmọ̀ onítíátà mìíràn, Mide Martins tí wọ́n sì ti bí ọmọ méjì.