Ọmọ ogun ṣekúpa obìnrin kan, gbé òkú rẹ̀ pamọ́ ní bárékè- Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Àwọn ọmọ ogun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iléeṣẹ́ ológun ní Nàìjíríà ti sọ pé ológun tó pa obìnrin kan ní ìpínlẹ̀ Enugu kìí ṣe ọ̀kan lára àwọn ọmọ ikọ̀ Boko Haram tẹ́lẹ̀ rí.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun, Onyema Nwachukwu ló ṣíṣọ lójú eégún ọ̀rọ̀ náà lọ́jọ́ Àìkú.

Ní ọjọ́bọ̀ tó kọjá ni òṣìṣẹ́ ológun kan, Adamu Muhammad ṣekúpa obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hauwakulu Tabra ní bárékè Enugu.

Ní ọjọ́ kejì ni wọ́n tó rí òkú Hauwakulu.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun náà, Nwachukwu bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà banilọ́kàn jẹ́ nítorí ẹ̀mí èèyàn bá a lọ, ó ní ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àwọn kan ń gbe kiri pé ọmọ ikọ̀ Boko Haram tó ti sọwọ́lẹ̀ fún ìjọba ló ṣe ìkọlù náà.

Ó ṣàlàyé pé Hauwakulu àti Adamu ni wọ́n ní àjọṣepọ̀ láàárín ara wọn tí ẹ̀mí rẹ̀ sì ti ọwọ́n ẹni náà bọ́ àti pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

“Ní ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni Hauwakulu Tabra pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ Adamu Muhammad, tí a sì rí òkú rẹ̀ ní ọjọ́ kejì ní ọgbà bárékè Enugu.

“Ìwádìí tí à ń ṣe lọ́wọ́ fi hàn pé Adamu ló ṣekúpa Hauwakulu, tó sì ti wà ní àhámọ́ wa. A tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tó lóòrìn láti fìdí ohun tó fa ìgbésẹ̀ Adamu múlẹ̀.

Nwachukwu tẹ̀síwájú pé Adamu kìí ṣe ọmọ ikọ̀ Boko Haram tẹ́lẹ̀ kó tó di pé ó darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun .

Ó ní kò sí ìgbà tí iléeṣẹ́ ológun gba àwọn ọmọ ikọ̀ Boko Haram síṣẹ́.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fún àwọn ènìyàn tó jágun tako àwọn àwọn agbéṣùmọ̀mí láàyè láti darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ ológun àwọn kò fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ikọ̀ Boko Haram tí wọ́n ti jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ fún ìjọba.

Ó ní àwọn èèyàn tó ní ìfarajìn, tí wọ́n sì ṣe é fi ọkàn tán ni àwón gbà sẹ́nu iṣẹ́ ológun.

Bákan náà ló ní iléeṣẹ́ ológun bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Hauwakulu Tarba kẹ́dùn lórí ikú ọmọbìnrin náà àti pé àwọn máa ri dájú pé ikú rẹ̀ kò lọ lásán.

Nwachukwu ní àwọn fi ń dá gbogbo èèyàn lójú pé ìdájọ́ òdodo yóò wáyé lórí ikú Hauwakulu àti pé àwọn kò ní fi ààyè gba àwọn ìwà kò tọ́ nínú iṣẹ́ ológun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post