You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohinoyi ti ilẹ̀ Ebìrà, Ado Ibrahim tẹ́rí gbaṣọ
Ohinoyi ti ilẹ Ebira to wa niluu Okene, nipinlẹ Kogi, Abdul Rahman Ado Ibrahim ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelaadọrun-un.
Ado Ibrahim to tun jẹ olori ọba alaye kaakiri ilẹ Ebira la gbọ pe o jade laye loni ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo kọlu.
Iroyin ni ile iwosan kan to wa niluu Abuja, iyẹn nibi ti kabiesi naa ti n gba itọju ni lo dakẹ si ni nnkan bi aago meji oru.
Ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Abubakar Ado Ibrahim lo fidi iroyin naa mulẹ, to si ni eto isinku yoo waye nilana ẹsin Musulumi loni.
Gomina Abubakar Audu ti ipinlẹ Kogi nigba kan ri naa lo gbe ade fun Ado Ibrahim gẹgẹ bi Ohinoyi ti ilẹ Ebira lọdun 1997, lẹyin ipapoda Alaaji Sanni Omolorin to jẹ laarin ọdun 1995 si 1997.
Ọjọ keje, oṣu keji, ọdun 1929 ni wọn bi Ado Ibrahim, to si lọ sile ẹkọ ede larubawa.
Ile-ẹkọ Native Authority to wa niluu Okene ni Ado Ibrahim ti kẹkọọ alakọbẹrẹ jade lọdun 1940.
Oloogbe naa tẹsiwaju nile ẹkọ girama ti Ondo Boys High School, ko to tẹsiwaju nile ẹkọ Oduduwa College, nibi to ti ṣetan lọdun 1949.
Lọdun 1954 ni Ado Ibrahim kẹkọọgboye Bachelor’s Degree ninu imọ ẹkọ Economics ni London School of Economics, to pada gboye Master’s ni Harvard Business School lọdun 1959.
Ado Ibrahim ni igbakeji alaga igbimọ ẹgbẹ awọn ọba alaye nipinlẹ Kogi ki ọlọjọ too de.